Mo lalaa pe mo lu iyawo mi pa, mi o si fẹẹ lokuu eeyan lọrun, ẹ tu wa ka- Franklin

Spread the love

Afi bii ere ori itage lọrọ ọkunrin kan, Franklin Temitayọ, ẹni aadọta ọdun ri, nigba to n rojọ ni kootu Agege l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja. Baale ile yii ni nitori ala toun la loun ṣe fẹẹ kọ iyawo oun, Temitayọ Titilayọ silẹ.

Franklin to n gbe ni adugbo Agege, sọ pe ọdun 2003 loun pade Titi, ọmọ mẹta lawọn si bi. Ṣugbọn nnkan to gbe oun de kootu ni pe oun ko fẹẹ lokuu eeyan lọrun, nitori oun ti lalaa pe oun lu iyawo oun pa, bẹẹ awọn ala oun maa n ṣẹ.

Ọkunrin naa ni oun ti fi ile silẹ fun obinrin yii nitori ala yii. Lara ẹsun to fi kan iyawo rẹ ni pe o maa n na inakunaa, to si jẹ pe niṣe lo maa n bu oun laṣọ so toun ba ti fẹẹ kuro nile. Yatọ si eyi, o ni epe lobinrin yii maa fi n sin oun jade nile laraaarọ, gbogbo eleyii si ti su oun.

Nnkan to tilẹ waa jẹ ki o tun tete wa si kootu gẹgẹ bo ṣe wi ni pe ọjọ kẹta lẹyin toun la ala pe oun lu u pa lobinrin naa ṣi fila ori oun sọnu, to si ni dandan ni ki oun lu oun.

Titilayọ naa wa ni kootu, obinrin to dudu, to ga daadaa, naa ṣalaye pe onirọ lọkọ oun i ṣe. O ni ọdun 2003 loun fẹ Franklin, ṣugbọn ko si ọjọ kan tọkọ oun sọ pe oun gba owo-oṣu ri, yoo ni wọn jẹ awọn lowo nibi iṣẹ ni.  Titi ni idi niyẹn toun fi gba ọdọ ọga rẹ nibi iṣẹ lọ, toun si lọọ fi ẹjọ rẹ sun, niyẹn ba ṣeleri lati maa pin owo-oṣu rẹ si meji, leyii ti yoo maa gba idaji, toun naa yoo maa gba idaji rẹ. Gbogbo eyi lo ni ko dun mọ ọkọ oun ninu to fi gba kootu wa.

Adajọ Patricia Adeyanju sọ pe ki Franklin ṣi maa san ẹgbẹrun marun-un Naira loṣooṣu gẹgẹ bii owo itọju ọmọ rẹ titi ti igbẹjọ yoo fi pari. O kilọ fun wọn pe wọn ko gbọdọ ba ara wọn ja ti ẹjọ naa yoo fi pari.

Igbẹjọ mi-in di ọjọ kọkanlelogun, oṣu to n bọ.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.