Mo kabaamọ pe mo darapọ mọ ẹgbẹ APC-Ọkẹ

Spread the love

Oloye Oluṣọla Oke, to jẹ oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AD, nibi eto idibo gomina to waye lọdun 2016, nipinlẹ Ondo, ti sọ pe oun kabaamọ bi oun ṣe darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Oke sọ eleyii lasiko to ṣe ipade nla kan pelu awọn alatilẹyin rẹ ninu ile rẹ to wa ni Ẹsiteeti Ijapọ, niluu Akurẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.

Ọgọọrọ awọn alatilẹyin gbajugbaja oloṣelu to ṣẹṣẹ gboye amofin agba yii, ni wọn fi aidunnu ọkan wọn han si bi ẹni ti wọn n wo gẹgẹ bii aṣiwaju ṣe le darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Awọn alatilẹyin naa ti wọn wa lati awọn ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo, fẹsun kan awọn aṣaaju ẹgbẹ APC ipinlẹ naa pe niṣe ni wọn pa awọn ti latigba ti awọn ti darapọ mọ ẹgbẹ yii.
Awọn ololufẹ Oke ti waa fimọ-ṣọkan ninu ipade naa pe awọn ti ṣetan lati fi ọkunrin naa silẹ ninu ẹgbẹ APC, awọn aa si lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi-in, iyẹn ti Oke ba kọ lati kuro ninu ẹgbẹ naa. Nigba to n fesi lori ohun ti awọn alatilẹyin rẹ sọ, Oke bẹ gbogbo wọn pe ki wọn ma binu pe oun ko wọn wọ inu ẹgbẹ APC.
O ni oun ti gbe igbesẹ ọhun tan ki oun too mọ pe aṣiṣe loun ṣe lati pada sinu ẹgbẹ APC. O ni ṣe ni awọn aṣaaju ẹgbẹ naa fẹẹ sọ oun deeyan lasan ninu oṣelu.
Oke to jẹ oludije gomina labẹ asia ẹgbẹ AD ninu eto ibo ọdun 2016, ni Gomina Rotimi Akeredolu ki kaabọ sinu ẹgbẹ APC niberẹ ọdun yii, lẹyin to ṣe ipo kẹta ninu eto ibo gomina to waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2016.
Ṣa, ko ti i si ẹni to mọ ẹgbẹ oṣelu ti ọkunrin naa fẹẹ darapọ mọ bayii.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.