Mo fẹran lati maa jo lode ariya, sugbon ipo oba ti gba a lowo mi___Ọba Okunoye

Spread the love

Ọkan pataki laarin awọn ori ade niha Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ọṣun ni Ẹburu ti Iba, Ọba Adekunle Adeogun Okunoye, Adedeji Keji. Kabiyesi gba akọroyin ALAROYE, FLORENCE BABAṢỌLA, lalejo lọsẹ to kọja, eyi si ni bi ifọrọwerọ naa ṣe lọ:

*******Alaroye: Ipo ọba jẹ ipo to lọwọ pupọ nigba atijọ ati lasiko yii, bawo la ṣe ba ara wa nibi ti a wa yii?

 

Ọba Okunoye: Ma a tu ibeere yẹn. Ṣe pe ori-ade n polongo ibo nita gbangba lo ti tumọ si pe o fi ori-ade wọlẹ ni abi bawo?

 

Alaroye: Pe o bọ sita gbangba

 

Ọba Okunoye: O ṣe. Aye ti yipada, a o si gbọdọ tan ara wa jẹ, a gbọdọ sọ ododo ọrọ. Idi ti wọn fi maa n sọ pe ki ori-ade ma da si ọrọ oṣelu ni pe atọtun-atosi, ọmọ ori-ade ni wọn, ṣugbọn mo fẹ ki o feti si ọrọ yii, ki o si ro o daadaa. O ni ọmọ meji, o mọ eyi to jẹ pe bi o ba lọọ ji i, ko ni i dide lori ibusun funra rẹ, ko si nnkan to buru nibẹ, ọmọ rẹ ni. O si mọ eyi to jẹ pe yoo ti ji ki iwọ gan-an too ji, yoo ti gbale-gbana, dakun, ti o ba fẹẹ lọ sode, ti ẹ si nilo kẹ ẹ tete ji, ewo lo maa mu lọwọ ninu awọn ọmọ mejeeji? Ṣebi iwọ lo lọmọ mejeeji.

Nnkan ti a n sọ niyẹn, awa la bi gbogbo ọmọ nitootọ, to ba ṣe pe ko si eyi ti mo mu lọ ninu awọn mejeeji, o ti tan, ṣugbọn ṣe bẹẹ ni ninu awọn to n jade fun eto oṣelu?

Ti a ba ti yẹ ẹlomi-in wo, a ti mọ gbogbo nnkan to ti ṣe, ṣe ẹni ti a mọ pe eleyii ti sin wa ri ti ko ṣe daadaa, eleyii de, a ko ti i mọ nnkan to le ṣe, ṣugbọn iwoye rẹ da bii ẹni ti yoo jẹ oloootọ, a waa sọ pe ka ma da si i, ka waa laju silẹ ko debẹ ka too wa maa ṣaroye, ko ṣee ṣe.

Awa lolori ilu, ọwọ awọn oloṣelu ni gbogbo ọrọ aje wa n bọ si lati ijọba ibilẹ titi de ipinlẹ, ti a ba ṣi eeyan mu, awọn araalu a maa kun, ọdọ wa si ni wọn a maa wa, rara o. Ma ṣi mi gbọ o, laaarin awọn ọmọ mejeeji, ti mo ba mu Ojo lọ sode loni-in, iyẹn o sọ pe mo korira Aina o, ti Aina ba ri i pe Ojo ni mo mu lọ, o ṣee ṣe koun naa yipada lọla, to ba tun di ọla, ma a mu Aina lọ.

Nnkan ti ori-ade o gbọdọ ṣe ni ka ba a nibi to ti n ba eeyan ja nita gbangba, ko tọna,  ko si ọba kankan ti ko ni oloṣelu kan to yan laayo, ṣugbọn ẹyin ti ẹ n bu ọba pe ko da duro, ti ẹ si mọ pe ko ṣee ṣe, lẹ maa n jẹ ki wọn gba lọtun-un, gba losi, iyẹn gan-an ni wọn fi n wọ ori-ade nilẹ.

Ti o ba de ọdọ mi, ti mo si sọ fun ọ pe ko sọna nibẹ, ti mo si ṣalaye idi rẹ fun ọ, ko si nnkan to buru nibẹ, o dara ki ọba duro lori ipinnu rẹ. Fun apẹẹrẹ, ko ṣee ṣe fun ọba ilu ti ọmọ rẹ fẹẹ ṣe gomina lati sọ pe oun ko ni i da si i, o gbọdọ da si i, ko si duro ti wọn.

 

Alaroye: Kabiyesi, awọn nnkan wo lẹ fẹran lati maa ṣe tẹlẹ ṣugbọn ti ẹ ko le ṣe mọ bayii?

 

Ọba Okunoye: Ṣe ẹ mọ pe ipo ta a wa ti di ipo ojutaye, tori pe gbogbo eeyan lo n wo wa, a si gbọdọ maa fi apẹẹrẹ to dara lelẹ. Ni temi, mo fẹran lati maa jo lode ariya, ha!, ti mo ba n jo bayii, okoto ni mi, o si maa n ṣe mi lẹẹkọọkan o, ṣugbọn…

 

Alaroye: Bawo ni irin ajo yin sori itẹ ṣe ri?

 

Ọba Okunoye: Lakọọkọ, gbogbo ọmọ ọba ni wọn ni anfaani lati jọba, ṣugbọn o waa ku ẹni ti Ọlọrun ti fi ori rẹ sọ pe yoo dade. Bi ẹni ti yoo jọba ba si ti n dagba, ami ati apẹẹrẹ kọọkan yoo maa wa. Ko ṣoro fun mi nigba ti asiko to, tori mo sun mọ awọn eeyan mi, mo si nifẹẹ lati maa ran awọn eeyan lọwọ.

Lati kekere ni wọn ti maa n pe mi ni dansaki, ṣugbọn mi o ka a si nitori ọmọ-ọba ni mi. Nitori naa, ko ba mi nija-fuu nigba ti wọn mu mi gẹgẹ bii ọba, bo tilẹ jẹ pe ko si ninu nnkan ti mo n ro lasiko yii rara.

 

Alaroye: Kin ni itumọ Iba?

 

Ọba Okunoye: Abẹ-Iba (Place of Refuge). Ilu o fararọ nibi ti awọn baba-baba wa de si nigba ti wọn n ti Ileefẹ bọ, Apala la n pe orukọ ilu naa, wọn d’Ifa, Ifa si sọ fun wọn pe ki wọn tẹ siwaju, pe wọn yoo ri ibi kan ti oke yi ka, ibẹ ni ki wọn tẹdo si. Bayii la de ibi ti a wa yii, wọn waa pe ibẹ ni Abẹ-Iba, bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ lo n ṣi orukọ yẹn pe, Iba (do re) ni, ki i ṣe Iba (re do).

 

Alaroye: Awọn itẹsiwaju wo lẹ waa le ri tọka si niluu yii latigba ti ẹ ti gori itẹ awọn baba-nla yin?

 

Ọba Okunoye: Mo dupẹ. Ki n ṣalaye daadaa, gbogbo ilọsiwaju ti wọn ba ni ọba n ṣe niluu loni-in, ijọba ni o, afi ọba ti Ọlọrun kẹ daadaa lati fi ṣe iṣẹ ilu. Ọba maa n lo anfaani awọn ọrẹ rẹ ti wọn jẹ olowo fun ilọsiwaju ilu rẹ. A dupẹ pe a ni ijọba eletiigbaroye.

Igba ti a de ori-oye ni wọn fun wa ni eeria-kansu tiwa, o tun jẹ ki ijọba sun mọ wa. Ekeji, ijọba ba wa tun ileewe girama wa ṣe, o si dun un wo bayii, wọn ba wa ṣe ọna wa, bo tilẹ jẹ pe o tun ti bajẹ.

Bakan naa la n ran awọn ọmọ wa lọwọ fun idanwo JAMB, bẹẹ lawọn ọmọ wa n dagba soke, laipẹ yii ni ọkan ninu awọn ọmọ wa di Jẹnẹra nileeṣẹ ologun orileede yii, ara oriire ni.

 

Alaroye: Eewọ wo lo wa niluu Iba?

Ọba Okunoye: Ko si eewọ kankan ti emi mọ o.

 

Alaroye: Ibudo nnkan imbaye wo lẹ waa ni?

 

Ọba Okunoye: Oke Ayẹẹ. O jẹ okuta ti awọn baba-nla wa maa n ba sọrọ, a si n ṣe bẹẹ titi dasiko yii, wọn aa gbe ẹtọ rẹ lọ fun un. Oke to rẹwa pupọ ni, adura la maa n lọọ ṣe nibẹ, o ni igba (calabash), kan ti wọn maa n gbe lọ sibẹ, emi o tu u wo ri o, wọn aa gbe igba yẹn waa ba mi, ma a sọ gbogbo nnkan ti mo ba fẹ sinu ẹ, wọn aa waa gbe e lọọ ba Ayẹẹ, wọn aa da obi nibẹ.

 

Alaroye: Ṣe igba yẹn maa poora ni, abi wọn aa gbe e pada?

 

Ọba Okunoye: Mi o ni i sọ fun ọ.

 

Alaroye: Idibo 2019 ti sun mọ, kin ni imọran yin fawọn ọmọ orileede Naijiria?

 

Ọba Okunoye: Akọkọ ni pe ki kaluku ro ọkan rẹ lati mọ nnkan to n fẹ lorileede yii, lẹyin naa, ko ṣakiyesi ileri awọn oludije kọọkan lẹka-jẹ-ka, eleyii ni yoo jẹ ọpakutẹlẹ ipinnu wọn. Ki wọn ma wo owo ti wọn aa na tan loojọ ki wọn fi fi ara wọn sinu ide ọdun mẹrin.

Ki a yan ẹni to dara si ipo, ka yago fun jagidi-jagan, oṣelu o mu ija wa rara, lẹyin idibo, ka para-pọ lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹnikẹni to ba wọle, ko pọn dandan pe ẹni ti mo fẹ lo gbọdọ debẹ, ijọba awa-ara-wa ni.

 

Alaroye: Kin ni erongba yin fun ọjọ iwaju ilu Iba?

 

Ọba Okunoye: Emi o fẹẹ sọ ilu Iba di Ikẹja Industrial Estate, nibi ti ko ni i si atẹgun alaafia, mo fẹ ki ilu Iba jẹ ilu iṣẹ ọgbin to kun fun idagbasoke, mo fẹ ki gbogbo nnkan to wa niluu nla-nla wa niluu Iba, mo fẹ ẹni to lowo bii Dangote nipasẹ iṣẹ agbẹ niluu Iba, ki alaafia wa si maa tẹsiwaju.

 

 

(53)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.