Mo fẹẹ mu Biọla pada wa sile lati Amẹrika

Spread the love

Wọn lu Anti Sikira lọsẹ to kọja, lọjọ Keresi, wọn lu u ti oju ẹ wu ku-n-gbu-ku-n-gbu. Ohun to ṣẹlẹ ni pe n ko mọ ibi ti wọn ti na an, oun naa ko sọ, ọkọ ẹ naako si sọ. Ọrọ ọlọrọ, bi ẹ si ti ri i yẹn, ki i ya mi lara. Ohun teeyan ba fi lọ mi ni mo maa n da si, ọrọ ti mo ba si mọ ni mo maa n sọ. Ṣugbọn wọn na an,Ọlọrun lo mọ awọn to ṣe e bẹẹ yẹn, ati ohun toun naa ṣe fun wọn. Amọ nigba ti wọn o ti sọ fẹnikan, ko sẹni to beere lọwọ ẹ. Ko kuku tiẹ fẹ kẹni kan mọ,Ọlọrun lo kan tu aṣiri ẹ, wọn fẹẹ bo gbogbo ẹ mọlẹ ni.

Igba ti emi ri i lọjọ keji ọdun yẹn to wọ aṣọ to tun lo iborun, to da iborun yẹnboju gan-an, niṣe ni inu mi dun. Adura ti mo n gba fun un naa ni ko bẹrẹ si ikirun daadaa, ko maa lọ si asalaatu, boya awọn iwa to sọ pe oun n hu yẹn yoo maa kuro lara ẹ diẹdiẹ. Koda, nigba ti mo ri i, mo rẹrin-in si i ni, bo tilẹ jẹ momọ pe ọjọ yẹn ki i ṣe ọjọ asalaatu, sibẹ, mo ro pe o fẹẹ lọọ ba wọn ṣe e nibi kan ni. A kuku maa n ṣe iyẹn naa daadaa. Ṣugbọn mo ṣọ ọ daadaa, ko lọ sibi kan, mo tiẹ si waa ro pe boya ọkọ ẹ lo ni ko maa bori kiri ile, ṣe ko si ara ti ko si lọwọ awọn mejeeji.

Iya Dele lo jẹ ki n mọ, oun lo sọ fun mi pe, “Kin niyawo ẹ ṣe ti wọn fi waa lu u bẹẹ?” Mo ni iyawo mi wo, lo ba ni Sikira. Mo ni ta lo lu u, o ni ṣ’emi o ri oju ẹ ni, mo ni mi o ri i, lo ba ni ṣe mo ro pe o kan deede da aṣọ boju ni. O ni lati irọlẹọjọ ọdun lo ti n daṣọ boju, ṣugbọn oun ri i nigba to bọ silẹ ninu takisi, o ni tipatipa loju ẹ fi riran, pe niṣe ni gbogbo ẹ wu to daranjẹ, eeyan o si le ṣẹṣẹmaa beere ohun to ṣe e ko too mọ pe lilu ni wọn fi ba tiẹ jẹ bẹẹ. Niṣe ni mo lanu. Ki lo waa ṣe. Mo mọ daadaa pe Sẹki aa wadii ọrọ yẹn, a gbọdọ mọ ohun to ṣẹlẹ ṣaa ni.

Bo ba jẹ o ṣi oju silẹ ni, a ba bi i, nigba to si jẹ o n fi oju ẹ pamọ yii nkọ, ti ọkọ ẹnaa ko si sọrọ, wọn jọ n mu un mọra ni. Ko ṣa ma jẹ nnkan ti o daa kan lo ṣe. Mo mọ pe bo jẹ ohun ti o daa naa lo ṣe, ko jẹ sọ fọkọ ẹ, irọ nla kan ni yoo gbe kalẹ fun un, tiyẹn naa yoo maa sa kiri. Ẹni to jẹ titi di bi mo ṣe n wi yii, ko jẹwọfun un pe akisa loun di sinu toun pe loyun fun un, pe irọ loun pa. Mo mọ pe owo ọsibitu mi to da pada yẹn, ọkọ ẹ lo fori ko o. O kuku ti daa bẹẹ, ẹni to ba bimọ ọran ni yoo pọn ọn, oun lo riyawo ọlẹlẹ to fẹ ẹ, ki wọn jọ maa ran an.

Aanu ọkọ ẹ lo n ṣe mi, ninu ọdun tuntun, niṣe lo tun ru to n gbẹ. Mo ti sọ fun Iya Dele pe ti ọrọ ọmọbinrin yii ba fẹẹ di wahala fun ọkọ mi, mo maa da a si rọọfu fun un o, mi o le laju mi silẹ ki obinrin kan waa sọ mi di opo ọsan gangan o. Ohun ti ko jẹ ki n ti i ja bayii ni pe wọn le ni ara oluwa-ẹ n gbona ni, ohun ti mo dẹ n sa fun niyẹn. Ṣugbọn to ba ti waa fẹẹ la tẹmi lọ, ti ko ni i fi ọkan ọkọmi balẹ, ija maa de laarin temi ẹ. Bo ba jẹ bi a ṣe n lo Alaaji lati ọjọ yii ree, ṣe oun le ri i nita ko ni oun fẹẹ fẹ ẹ. Baba to jẹ niṣe lo n dan, o ti waa sọ ọ diṣioṣio.

Emi o ni i gba o, o si digba ti mo ba wadii ohun to ṣẹlẹ yẹn ki n too mọ ọwọ ti mo maa ba mu un. Bo jẹ ki n pe Alaaji funra ẹ ki n sọ fun un, mo maa pe e, oun naa kuku jẹrii mi, o mọ pe n o jẹ wa aburu oun, tabi ohun ti yoo ko wahalaba oun, o si mọ pe bi ọrọ ba ti ri naa ni n o ṣe sọ ọ. Abi kin ni gan-an! Ṣe ọmu rẹpẹtẹ to n fi kiriimu pa ti iyẹn da bii ti ọmọde lo fẹẹ tori ẹ pa ọkọ fun mi, ti mo ba si le e, ibẹ yẹn ko ni i gba a, oun naa kuku tiẹ mọ ẹni to ni. O mọ midaadaa, o tun fẹẹ pada sitimọle ẹ lẹẹkan si i ni. Ọlọrun lo si mu baba naa funraẹ, ẹni toju ẹ o ba ti gbebi kan, bi wọn ṣe maa n gbegbekugbee naa niyẹn. Inu awọn mejeeji tiẹ n bi mi.

Mo ti ba Akinfẹnwa sọrọ yẹn. Ọrọ Iya Tọmiwa ti mo ni ko jẹ ki a lo nnkan ibilẹsi arun to n ṣe e. Ọrọ to sọ ya mi lẹnu. Niṣe lo dupẹ titi, o loun ti ba ọrẹ mi sọ ọtiti pe ko jẹ ki awọn lo oogun ibilẹ, pe oogun si aisan to ba n ṣeeyan ki i ṣe ẹbọṣiṣe, nigba to jẹ ohun tawọn oyinbo naa n ṣe ti a n lo ti wọn n pe ni piisi tabi abẹrẹ, ewe ati egbo naa ni wọn fi n ṣe e. O ni ṣugbọn niṣe lọrẹ mi maa n taku, ti yoo ni ko si ohun ti ewe ati egbo le ṣe ti oogun oyinbo ti oun n lo ko le ṣe e. O ni ki n ṣa ba oun bẹ ẹ ko gba, nitori onitiju mi ni, o si fẹran mi daadaa.

Nigba ti mo ti gbọ bẹẹ, ti ọkọ ẹ ti ni ko si wahala, to jẹ oun lo tun n bẹ mi pe ki n ba a sọrọ, mo ti mọ pe o ti ṣee ṣe niyẹn. Mo mọ pe n o le da iṣẹ yẹn ṣe, emi ati Sẹki la jọ maa ko ti i. Mo sọ fun Sẹki pe ti mo ba ti ba a sọ ọ lọsan-an, to badi alẹ ki oun naa tun ba a sọ, nigba ti a ba fi maa ṣe bẹẹ foṣu kan gbako, o maa gba ohun ti a n wi. Ko tiẹ si waa le to bẹẹ yẹn o, nigba ti mo ti sọ fun un ti mo si ti ṣalaye pe ọkọ ẹ to fẹẹ purọ mọ ti sọ fun mi pe oun fun mi laṣẹ, niṣe lo n rẹrin-in, to ni, “Iya Biọla, ẹyin ki i gba ṣaa, afi kẹ ẹ ṣeun tẹ ẹ ba fẹẹ ṣe yẹn!”

Nigba to ti gba bẹẹ, mo ti ṣe gbogbo alaye fọkọ mi, oun naa si ki mi, o ni oun jẹrii mi, oun mọ pe mo ti tun bẹrẹ iṣẹ aanu kan niyẹn, Ọlọrun aa fun mi ṣe. Moti ranṣẹ sawọn baba yẹn naa ki wọn wa, ki wọn tiẹ waa ba mi lo oogun akọkọfun un. Ohun to jẹ ki n sọ fọkọ mi niyẹn nitori ile mi ni wọn maa wa, mo si le gba otẹẹli fun wọn ti o ba saaye nile, ṣugbọn gbogbo eelo oogun wọn ti wọn ba fẹẹ ṣe, ọdọ wa ni wọn ti maa ṣe e. Wọn o kuku tiẹ ṣe nnkan kan naa nibẹ, agbo lasan ni, agbo atawọn oogun ẹrọ, ko soogun kan to le dẹru baayan ninu ohun ti wọn fẹẹ ṣe.

Kinni kan wa ti mo fẹẹ ṣe, n o ti i mọ bi yoo ti ṣee ṣe si ni. Mo fẹẹ mu Biọla pada wa sile. Ko kuro l’Amẹrika, ko pada si Naijiria. Mo ti ṣeto naa fun un bayii, ohun ti yoo ṣe ti wa nilẹ, ko kan gba si mi lẹnu lo ku. Iya n jẹ ẹ nibi to wa yẹn, iya gidi ni paapaa. Abi bawo leeyan yoo ṣe maa gbe ilu kan ti yoo maa sare kiri bẹẹ lai nisinmi, oun atọkọ ẹ, ki wọn maa ji laago marun-un, ki wọn maa wọle laago mẹsan-an alẹ, tabi mẹwaa nigba mi-in. Wọn si ṣe gbogbo ẹnaa, a o ri nnkan kan. Wọn o le binu na ẹgbẹrun kan dọla, iyẹn wan taosan dọla. Emi ti mo si wa ni Naijiria le na iru ẹ mẹwaa ti nnkan kan o ni i ṣe. Mo fẹẹmu un pada wa sile, k’Ọlọrun jẹ o gba si mi lẹnu.

 

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.