Mo fẹẹ kopa rere bii ti Awolọwọ taọn araalu ba dibo fun mi– Bayọ Lawal

Spread the love

Oludije fun ipo Senetọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress,

(ADC ), fun ẹkun Ariwa ipinle Ọyọ, Amofin Abdulraheem Bayọ Lawal, ti ṣeleri lati gun le eto Oloogbe Ọbafemi Awolọwọ ti wọn ba dibo ya an gẹgẹ bii sẹnetọ ti yoo maa ṣoju ẹkun naa

ninu idibo ọdun to n bọ. Nigba to n ṣe ifilọlẹ eto ipolongo ẹ lo sọrọ naa niluu Kiṣi, nijọba Ibilẹ Irẹpọ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja.

 

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, lasiko iṣejọba Awolọwọ lo fi eto iṣejọba ọna mẹrin lọlẹ, ninu eyi ta a ti ri eto ẹkọ ọfẹ, eto ilera ọfẹ, ipese iṣẹ fawọn ọdọ, awọn agbẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Lawal ṣalaye pe iwọnyi lawọn iṣẹ rere Awolọwọ ti awọn eeyan ṣi n tọka si doni. O fi kun un pe bo tilẹ jẹ pe awọn ẹgbẹ oun ti wọn ti dipo naa mu tẹlẹ ni awọn ipenija to n dojukọ awọn ara agbegbe naa nipa ọna gidi, airiṣẹ awọn ọdọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, o ni pẹlu iriri oun gẹgẹ bii ọmọlẹyin Oloogbe Awolọwọ ati alakooso fun eto idajọ ni ipinlẹ Ọyọ, oun mọ ibi ti bata ti n ta araalu lẹsẹ, ati pe oun ti ṣetan lati pese awọn nnkan ti yoo mu idagbasoke ba ẹkun idibo naa.

 

 

O waa gba awọn oludibo gbogbo niyanju lati ṣe agbeyẹwo awọn oludije

lati mọ awọn to kunju oṣuwọn, ki wọn le mọ ẹni ti yoo le ṣoju araalu daadaa ninu gbogbo wọn.

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.