Mikel bẹrẹ iṣẹ tuntun ni Trabzonspor

Spread the love

Balogun Super Eagles ilẹ wa tẹlẹ, Mikel Obi, ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu lẹgbẹ agbabọọlu Trabzonspor, ilẹ Turkey, pẹlu bi awọn alaṣẹ kilọọbu naa ṣe n reti nnkan ara ọtọ.

Lọsẹ to kọja ni Ahmet Agaoglu to jẹ aarẹ ẹgbẹ naa sọ pe oun nireti pe Mikel yoo jẹ awokọṣe fawọn agbabọọlu ẹgbẹ naa ti wọn jẹ ọmọde, nitori iriri to ti ni nipa bọọlu.

Mikel to ti darapọ mọ Ogenyi Onazi ati Anthony Nwakaeme ni Turkey ni yoo kopa nigba akọkọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba ti wọn ba koju Sparta Prague, nibi kuọlifaya idije Europa League.

Agaoglu ṣalaye pe agbabọọlu to ni ẹbun gidi ni ẹni ọdun mejilelọgbọn naa, eyi ni ko ṣe rọrun lati ra a, oun naa si mọ idi tawọn fi gbe e wa si Turkey. Adehun ọdun meji lo tọwọ bọ pẹlu kilọọbu yii, anfaani si wa fun un lati fi ọdun kan kun un.

Plateau United ni Mikel ti bẹrẹ bọọlu gbigba ko too kọja si Lyn, ilẹ Norway, lọdun 2004. Lẹyin eyi lo lọ si England ati China, bẹẹ lo pada si England, ko too lọ si Turkey bayii.

O gba bọọlu fun ikọ ojẹ-wẹwẹ Naijiria ko too bọ si Flying Eagles ati Super Eagles, nibi to ti lo apapọ ọdun mẹrindinlogun. Oṣu to kọja lo fẹyinti lẹyin idije ilẹ Afrika, nibi ti Naijiria ti ṣe ipo kẹta.

Fun ara rẹ, kilọọbu ati orilẹ-ede, ife-ẹyẹ ati ami-ẹye ti Mikel gba ko din ni mẹwaa.

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.