Michael Okpara, olori ẹgbẹ NCNC, ko wahala gidi ba Awọn Akintọla ni West

Spread the love

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu karun-un, 1964 ni ijọba Ladoke Akintọla kede ni Western Region pe awọn ti fi ofin de ipade ita-gbangba tabi akojọpọ awọn oloṣelu, tabi ipade oṣelu tabi ipolongo kankan ni gbogbo agbegbe naa pata. Wọn ni ko si awọn kan ti wọn gbọdọ ko ara wọn jọ sibi kan pe awọn n jo tabi awọn n ṣe ipade, tabi pe awọn n ko rẹirẹi lọ sibi kan, ki kaluku maa rin irin ẹsẹ rẹ loun nikan kaakiri ibi to ba n lọ ni, ko si aaye ero rẹpẹtẹ loju kan naa. Ọjọ Tusidee ni ijọba Akintọla kede eyi, ọjọ Wẹsidee, iyẹn ọjọ keji, ni wọn si sọ pe kinni naa yoo bẹrẹ, konikaluku maa lọ wọọrọ lai gbọdọ si ero rẹpẹtẹ kan loju kan naa rara. Ko sẹni ti ọrọ naa ba lojiji, awọn eeyan mọ pe ki i ṣe nitori ohun mi-in lofin pajawiri yii ṣe jade bi ko ju nitori olori ẹgbẹ NCNC, Michael Okpara, to fẹẹ bẹ agbegbe naa wo lọ.Wọn ko fẹ ẹ nibẹ rara.
Ṣe ọrọ naa ti dija tẹlẹ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji, ijọba ko si jẹ ki ọrọ naa tutu rara ti wọn fi kede pe ẹnikẹni ko gbọdọ pero jọ sibi kan. Ṣe bi Okpara ba wa bẹẹ, awọn oloṣelu yoo lọọ pade rẹ, wọn yoo ko ara wọn jọ si ita gbangba tabi ninu gbọngan nla kan, nibi ti ero rẹpẹtẹ yoo ti waa pade rẹ, ti yoo si ti ba wọn sọrọ, ti wọn yoo si sọ ohun ti wọn ba fẹ ki awọn ọmọ NCNC naa ṣe fun wọn. Iru ipade yii gan-an ni ibẹru awọn Akintọla, wọn ni awọn ko fẹ rara, bi ko ba si ti si iru ipade bẹẹ, ohun ti wọn n dọgbọn sọ ni pe ki Okpara jokoo jẹẹ siluu rẹ, awọn ko fẹ ẹ ni Western Region rara. Ọrọ naa bi ẹgbẹ NCNC ninu gan-an ni. Iyẹn awọn NCNC nilẹ Yoruba ni o, wọn ni ki lo n ṣe awọn ẹgbẹ Dẹmọ yii ti ko ṣe ẹnikan ri paapaa, wọn ni kin ni wahala to ba wọn ti wọn n fapa janu, ṣe ori wọn ni Okpara fẹẹ duro si ni abi ewo ni wahala tiwọn.
Bi awọn Akintọla ti ṣe ofin wọn jade lawọn NCNC yii naa ti bẹ jade lọjọ keji, wọn si gbe iwe jan-an-ran kan jade, wọn ni awọn lodi si gbogbo ohun ti ijọba West yii n sọ. Wọn ni ohun ti awọn fẹẹ mọ ni idi ti Akintọla ati awọn eeyan rẹ fi sare gbe ofin pakaleke bayii jade lẹyin ti awọn aṣofin ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ NCNC ti sọ nile-igbimọ ati laarin awọn eeyan wọn pe Okpara ti i ṣe olori ẹgbẹ awọn n bọ ni West. Wọn ni ki i ṣe ile ijọba lo n bọ, bẹẹ ni ko de ile Akintọla, ki waa ni tiẹ ti yoo sọ pe kawọn ma rin irin-ẹsẹ awọn. Awọn NCNC yii ni ẹru lo n ba Akintọla, awọn si mọ ohun to n ba a lẹru, o mọ pe awọn Yoruba ko si lẹyin oun ni, nitori bo ba jẹ aṣaaju tootọ ni, ko ni i di awọn eeyan rẹ lọwọ lati maa tẹle ẹgbẹ oṣelu to ba wu wọn. Wọn ni ki Akintọla maa bọ nilẹ Ibo, tabi ni Mid-West, ko waa wo ohun ti wọn n pe ni dẹmokiresi gidi.
Ṣugbọn awọn Akintọla ko da wọn lohun bẹẹ o, nitori kaka ki wọn dahun, niṣe ni wọn tun sare ṣe ofin mi-in, wọn ni iru ofin ti awọn ṣe ni Ibadan ati agbegbe rẹ yii, awọn o tun gbọdọ gbọ pe ẹni kan n rin gberegbere ni agbegbe Ondo, titi wọ ilu Ọwọ de ilu Akurẹ ati gbogbo Ekiti patapata. Eleyii fihan pe lati Ibadan titi wọ ilu Ibini, ijọba Akintọla lawọn ko fẹ ipade kankan, tabi akojọpọ awọn eeyan, awọn ọlọpaa ti ni bi awọn ba ri iru rẹ, ẹni ti ọwọ ba tẹ, yoo fimu danrin. Ko si si ẹni ti ọwọ tẹ bẹẹ ti ki i ṣe itimọle gidi ni wọn yoo sọ ọ si, nibẹ ni yoo si gba dewaju adajọ, bẹẹ ni aanu ko si nigba naa, ẹni ti wọn ba mu pe o tẹ ofin ijọba West mọlẹ, agaga bi tọhun ba jẹ ọmọ ẹgbẹ AG tabi NCNC, tabi to ba ni ohunkohun i ṣe pẹlu eyikeyii ninu awọn mejeeji yii, yoo lọ sẹwọn ṣaa ni, ko si bo ṣe le mọ ẹjọ i ro to.
Amọ o, pẹlu gbogbo ofin tuntun ti awọn Akintọla ṣe yii, ohun to n tẹnu Okpara ati awọn eeyan rẹ jade ni pe ko si Jupita kan ti yoo da oun duro, oun yoo lọ si Western Region, koda ki awọn ti wọn n ṣejọba ibẹ fẹẹ ko si kanga. Eyi gan-an lo ṣẹṣẹ waa bi ẹgbẹ NNDP ninu, iyẹn Ẹgbẹ Dẹmọ, n lakọwe ẹgbẹ naa ba jade. Richard Akinjide ni o. Bẹẹ ni, Akinjide yii kan naa ni, oun lakọwe awọn Dẹmọ lọjọ naa lọhun-un, n lo ba fibinu jade. Ọkunrin lọọya naa ni oun ko ri ibi ti ainiṣẹ ati ainikan-an-ṣe ti n daamu eeyan bii ti ọgbẹni ti wọn n pe ni Okpara yii ri. O ni iṣẹ ko ka ọkunrin naa lara rara, bi iṣẹ ba ka a lara ni, bawo ni yoo ṣe fi ile rẹ silẹ ti yoo maa rin kaakiri. O ni awọn Yoruba ti ni awọn ko fẹ Okpara nilẹ awọn, ki lo tun waa n wa kiri, ki lo de ti ko jokoo si ilu rẹ nibi ti wọn ti dibo yan an, ko maa ṣejọba lawọn to yan an sipo lori.
Akinjide ni gbọn-in gbọn-in ni ẹgbẹ Dẹmọ wa lẹyin Akintọla ati ijọba Western Region lori ofin ti wọn ṣe pe ki ẹnikẹni ma ṣe ipade kankan ni agbegbe naa, pe awọn si mọ idi ti ofin naa fi waye. O ni ofin yii ko deede waye bi ko jẹ pe awọn mọ iwa ọkunrin ti wọn n pe ni Okpara pe bo ba di ọrọ oṣelu, onijagidijagan kan ni, ko si kọ ki ilẹ ṣu ni aila bo ba di lati ja ija oṣelu, nigba ti awọn si mọ pe awọn eeyan awọn nilẹ Yoruba ko fẹ ohunkohun to ba jẹ ti jagidijagan nijọba ṣe ṣe ofin naa pe ko saaye apejọ tabi ipade awọn oloṣelu nibi kan. Akinjide ni ibi ti awọn eeyan yoo ti mọ pe onijangbọn ọkunrin kan ni Okpara ni ọrọ to n sọ jade lẹnu pe oun n bọ nilẹ Yoruba dandan, bo tilẹ jẹ pe ijọba ti ṣofin pe awọn ko fẹ alejo ati ipade. O ni ko si olori ijọba kan to fẹran alaafia, ti ki i ṣe arufin, ti yoo ṣe ohun tijọba fofin de.
Akinjide tun halẹ mọ Okpara atawọn ọmọ NCNC to ku, o ni ki wọn gbọ daadaa o, nitori were ita la ṣe n ni were ile o, bi Okpara tabi awọn NCNC ba ro pe awọn le waa maa fọwọ lalẹ nilẹ Yoruba tawọn, awọn ẹgbẹ Dẹmọ naa ti ṣetan lati ki wọn nilọ ti wọn ko ni i gbagbe lae. O ni ẹgbẹ Dẹmọ ko fẹ wahala, ṣugbọn ẹni to ba tẹ ọka niru mọlẹ ni, tọhun yoo ri ija ọka dandan. Ọrọ ti Akinjide sọ yii ba ohun ti awọn ọdọ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ n fẹ lara mu, ṣe awọn naa ti n sọ pe bi Okpara ba le wa to wa ṣe mẹẹsi kan pẹlu awọn, awọn yoo sọ fun un pe ikọja-aaye ni, oorun ori kẹkẹ, awọn yoo jẹ ko mọ pe ilẹ awọn ki i ṣe ibi to ti le waa maa halẹ. Ohun to kan n ya awọn eeyan lẹnu ju naa ni pe nigba ti ẹgbẹ NCNC yoo ran awọn ẹgbẹ UPP ti Akintọla lọwọ lọjọ kin-in-ni ana, Akinjide yii wa lara awọn ti wọn n mu Okpara kiri ilẹ Yoruba.
O jọ pe ohun to bi awọn ẹgbẹ NCNC ninu niyẹn, wọn ni ọrọ n gbe awọn ninu, awọn tun fẹẹ sọrọ. Ṣugbọn ki wọn too le wi kinni kan, ẹgbẹ AG, iyẹn Action Group, ẹgbẹ Ọlọpẹ ti ta pẹẹrẹ jade, wọn ni awọn fọwọ si i, awọn si fẹsẹ si i pe ki olori ẹgbẹ Alakukọ, NCNC, maa bọ nilẹ Yoruba, ko si rin ko yan bo ba de, ko si ẹnikan ti yoo mu un si i, nitori ko si meji obi nigbo, ko si ẹni ti i pa aṣẹ ilẹ Yoruba bi ko jẹ ẹgbẹ Ọlọpẹ. Ẹgbẹ Ọlọpẹ ni ihalẹ ati ariwo lasan lo n ti ẹnu awọn ẹgbẹ Dẹmọ jade, ti wọn n sọ pe awọn n sọrọ lorukọ Yoruba tabi fun ilẹ Yoruba, o ni ọrọ ti wọn n sọ naa ko yatọ si gbigbo aja lasan. Wọn ni ni West ti awọn wa yii o, bi ẹgbẹ oṣelu kan yoo ba sọrọ lorukọ awọn Yoruba nibẹ, aa jẹ pe ẹgbẹ ti wọn ti dibo fun to ti wọle, to si ti ṣejọba le wọn lori ni. Ẹgbẹ AG waa beere pe ta lo dibo fun Ẹgbẹ Dẹmọ nilẹ Yoruba o.
Wọn ni ijọba ti Akintọla ni oun n ṣe yii, ṣebi ijọba AG ati NCNC ni, ṣebi awọn ọmọ ẹgbẹ AG lo ji ko lọ sọdọ ara rẹ, to si beere fun iranlọwọ lati ọdọ awọn NCNC, ko too di pe o pada waa dalẹ ẹgbẹ NCNC, to si ji awọn ọmọ ẹgbẹ naa ko si ọdọ ara rẹ. Wọn ni bo ba jẹ oun to ọkunrin, to si mọ pe oun to aṣẹ ilẹ Yoruba i pa, tabi pe oun loloṣelu ti Yoruba fẹran ju, ko tu ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ka bayii, ko si ṣeto idibo, ki wọn waa wo ẹni ti yoo wọle boya Ẹgbẹ Dẹmọ ni o, tabi ẹgbẹ AG. Wọn ni ko si ẹnikẹni ti yoo fa ijangbọn nilẹ Yoruba nitori pe Okpara n bọ, awọn Yoruba fẹran alejo, ẹru lo n ba ẹgbẹ Dẹmọ. Wọn ni bi wahala kan ba fi le ṣẹlẹ pẹnrẹn, ki awọn eeyan ipinlẹ naa ti yaa mọ pe ki i ṣe ẹnikẹni lo fa a o, awọn aṣaju Dẹmọ ti wọn ti n pariwo pe kugu maa bẹ, ijangbọn yoo ṣẹlẹ, ni ki wọn tete mu si i.
Igba ti ọrọ tilẹ ti da bayii ni ọkunrin kan to pe ara rẹ ni Alimi Adeṣọkan ti jade, o ni oun ni alaga ẹgbẹ Herbert Macaulay Dẹmo Youth Group, awọn ọdọ ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ yii kan naa ni. O ni ẹru kan ki i ba odo, ẹru kan ki i ba ọlọ, ẹru kan ki i ba ṣọja bi ogun ba de, ko si ẹru ti yoo ba NNDP, ẹgbẹ Dẹmọ. O ni irọ lawọn eeyan n pa pe ẹru pe Okpara n bọ n ba ẹgbẹ Dẹmọ, o ni gbogbo Yoruba pata, bi a ba ko ọgọrun-un wọn kalẹ, marundinlọgọrun-un ninu wọn lo jẹ Dẹmọ ni wọn n ṣe, ki waa ni ẹru yoo maa ba wọn si pe alejo kan n bọ, nigba ti ki i ṣe pe o fẹẹ duro sori awọn. Adeṣọkan ni bo ba jẹ tawọn ni, awọn ti gbaradi, bi Okpara ba n bọ o kaabọ, ohun to da awọn loju ni pe ko ni i ri ẹni kan pade ẹ, yoo kan maa rin kiri ninu oorun fọ-nọtin ni. O ni Dẹmọ lo ni West, kinni naa ti bọ lọwọ AG ati NCNC, wọn kan n japoro lasan ni.
Gbogbo eleyii ko jẹ kinni kan fun wọn ninu ẹgbẹ NCNC ṣa o, nitori nigba to di alẹ ọjọ Sannde, lọjọ ti oṣu karun-un, ọdun 1964 pari gan-an, iroyin jade pe Michael Okpara, olori ẹgbẹ NCNC, yoo gunlẹ si ilu Eko lọjọ keji, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa ọdun. Wọn ni Eko ni yoo ti bẹrẹ irinajo rẹ lọ si Western Region, nigba to jẹ Western Region ti bẹrẹ lati Idi-Oro ati agbegbe Jibowu bayii, nibẹ ni yoo si gba de ọna Agege, Sango, Ifọ titi wọ ilu Abẹokuta. Wọn ni Okpara ti sọ pe gunnugun kan n gba gẹrugẹru lasan bansa ni, kinni kan o ni i ṣe, bi awọn ijọba Western Region atawọn ọlọpaa ijọba Naijiria ba ni agbara kan lati sa foun, ki wọn tete mura lati sa agbara naa loju gbogbo agbaye, ṣugbọn pe ki oun ma ṣe abẹwo toun si Western Region yẹn, ala ti ko ni i le ṣẹ ni, bi babalawo kan ba da iru ẹ nifa, idakudaa lo da.
Ẹgbẹ NCNC funra wọn naa tilẹ gbe iwe jade, wọn ni awọn ti wo ọtun, awọn wo osi, awọn ti wadii ohun gbogbo wo, awọn si ti ri i pe ko si ohun kan ti yoo fa wahala ninu abẹwo ti Okpara fẹẹ ṣe silẹ Yoruba, ati pe bi awọn onijagidijangan ba da wahala silẹ, awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ ni. Nitori ẹ ni wọn ṣe kọwe si Olori ijọba Apapọ, Tafawa Balewa pe ojuṣe rẹ ni lati ri i pe nnkan kan ko ṣe Okpara nilẹ Yoruba to fẹẹ lọ. Wọn ni olori ẹgbẹ oṣelu ni, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ si pọ nilẹ Yoruba, ki waa ni ijọba kan yoo ṣe ofin pe ko gbọdọ wa sibẹ si, ti wọn yoo ni awọn n bẹru wahala. Awọn wo lo fẹẹ fa wahala, ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ to waa ki ni yoo bẹrẹ ija ni abi awọn wo! Wọn ni bi ija kan ba fi le de, ki kaluku ti mọ pe awọn aṣaaju ẹgbẹ Dẹmọ ni wọn wa nidii ẹ, pe nitori ẹ lawọn ṣe kọwe, ki wọn ba awọn kilọ fun Akintọla atawọn eeyan rẹ daadaa. Ọrọ naa maa le o, nitori ẹni ti ko yẹ ko da si ọrọ naa aa da si i. Nigba ti ijọba West ri i pe ko si ohun ti awọn ṣe to jọ pe o fẹẹ da ọkunrin Okpara yii duro, Akintọla sare pe awọn ọba ti wọn fẹ tirẹ ni West jọ, o ni ki awọn ọba naa kọwe si Gomina Western Region, iyẹn Oloye Ọdẹlẹyẹ Fadahunsi, ki wọn sọ fun un pe awọn ko fẹ Okpara nilẹ Yoruba rara, ko ṣe ofin pe ki ọkunrin naa ma wa o. Fadahunsi mọ pe oun ko le ṣe ofin kankan niru asiko naa ki ofin naa mulẹ, nigba ti ẹni to fẹẹ wa ti sọ pe oun n bọ, ti ọjọ wiwa rẹ si ti ku ọla. Ṣugbọn o da ọgbọn kan, o sare gbe iwe pajawiri ti wọn maa n kọ laye igba naa ti wọn n pe ni tẹligiraamu dide, o kọ ọ si Aarẹ Naijiria funra rẹ, Oloye Nnamdi Azikiwe, o ni ko sare ba oun da si ọrọ to wa nilẹ yii, nitori oun ko fẹ ohun ti yoo da wahala kan silẹ lagbegbe oun.
O kọwe bayii pe, “Dokita Nnamdi Azikiwe. Nitori ti awọn ọba ilẹ Yoruba waa ba mi pe awọn ko fẹ ki Michael Okpara ko waa ṣe abẹwo si adugbo awọn lasiko yii, mo fẹ ki ẹ ba mi lo agbara yin lati sọ fun ẹni wa yii ko sun abẹwo rẹ siwaju o. Emi ni Ọdẹlẹyẹ Fadahunsi.” Nigba to ti jẹ iwe pajawiri ni bẹẹ, ẹsẹkẹsẹ naa ni Azikiwe ti dahun, oun naa ni, “Ọdẹlẹyẹ Fadahunsi, Gomina ni West. O ṣeun iwe ti o kọ si mi lori ọrọ Okpara. Ṣugbọn ki lo de ti awọn ọba Yoruba yoo fi sọ pe ki olori ijọba ipinlẹ mi-in ma wa si ipinlẹ tiwọn? Kin ni wọn sọ pe o ṣẹlẹ? N ko le da si ọrọ yii nitori ọrọ oṣelu lo jọ loju mi, sibẹ, bo ba jẹ pe irin-ajo ati abẹwo ọkunrin naa mu wahala kan dani, n oo da si i kiakia” Nibi yii lo jọ pe apa Gomina West naa ati ti Akintọla pẹlu ijọba rẹ ti jabọ, ko jọ pe nnkan kan wa ti wọn tun le ṣe mọ.
Ṣugbọn Ladoke Akintọla to n ṣejọba Western Region yii gbọn ju bẹẹ lọ, bi ọrọ ba da bayii, o mọ ibi ti oun yoo doju ọrọ ọhun kọ. Ko ni i ba Tafawa Balewa sọrọ, nitori o mọ pe Balewa yoo fẹẹ maa tẹle ofin, tabi ko maa ni kinni kan ko le ṣee ṣe, pe bi oun ba ṣe bẹẹ, aye yoo bu oun, nitori bẹẹ, Akintọla ki i fẹẹ lọọ ba a. Bi ọrọ ba da bayii, ọdọ Ahmadu Bello ni yoo lọ, bo ba si ti ba Sardauna sọrọ, ti iyẹn ba ri i pe loootọ lawọn kan fẹẹ maa halẹ mọ ọn nidii oṣelu West, kia ni yoo ṣe ohun ti Akintọla ba fẹ ko ṣe. Ohun to si ṣẹlẹ naa niyi, nitori ko si ẹni to mọ bi ọrọ naa ti jẹ tabi bo ti ṣẹlẹ, lẹsẹkẹsẹ lawọn ṣọja ya wọ ilu Ibadan, wọn si bẹrẹ si i rin kaakiri opopo gbogbo, wọn ni awọn waa ṣeto aabo fun agbegbe naa. Ewo lo waa kan ṣọja pẹlu eto aabo, nigba ti ki i ṣe pe ogun de! Ati pe iru eto aabo wo lawọn eeyan naa n ṣe pẹlu ibọn lọwọ wọn.
Iṣẹ ọwọ Sardauna niyi. Nigba mi-in, iru ọrọ bẹẹ ko ni i de eti Balewa, nitori ẹni to n ṣe minisita eto aabo to jẹ abẹ rẹ ni awọn ṣọja wa, Ribadu ni, Ribadu yii si sun mọ Sardauna ju Balewa lọ. Ribadu yii ni Sardauna fẹ ko wa nipo Balewa tẹlẹ, ṣugbọn nitori iwe ti Balewa ka, ati bo ti gboyinbo, to si ni laakaye ju awọn to ku lọ ni wọn ṣe mu un. Ko ṣa sẹnikan to mọ bi ọrọ naa ti ri, wọn kan deede ri ṣọja nigboro ilu Ibadan ni. Awọn Akintọla ti ro pe iyẹn yoo ba Okpara ati awọn NCNC rẹ lẹru, wọn yoo si jokoo jẹẹ soju kan. Ṣugbọn niṣe lọkunrin Ibo naa ko agidi bori, o ni bawọn ṣọja ba fẹẹ pa oun ki wọn tete mura silẹ, oun n bọ ni Western Region, ko si sohun tẹnikan yoo ṣe.
Bẹẹ lawọn ṣọja mura silẹ, awọn ọlọpaa mura, Akintọla mura, awọn ẹgbẹ Dẹmọ mura, ẹgbẹ Ọlọpẹ mura, Ẹgbẹ Alakukọ naa si mura, wọn n reti Michael Okpara nilẹ Yoruba, gọngọ n fẹẹ sọ!

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.