Mi o wa lati gbẹsan rara—Fayẹmi Ma ti i dunnu, awa la maa bori lẹẹkeji—Fayoṣe

Spread the love

Oludije tẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ṣẹṣẹ dibo yan, Ọmọwe Kayọde Fayemi, ti sọ pe ki i ṣe ẹsan loun waa gba bi oun ṣe pada waa dupo gomina yii gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n sọ. O ni ko sẹni to ṣẹ oun toun yoo maa le kiri, iṣẹ ilu loun fẹẹ ṣe.

Lasiko to n sọrọ lori aṣeyori rẹ ninu ibo abẹle lo mẹnuba ọrọ naa, nibi to ti sọ pe ẹgbẹ Peoples Democratic Party (PDP) ti ba Ekiti jẹ, atunṣe loun si n gbe bọ fawọn eeyan ipinlẹ naa.

O waa bẹbẹ fun iforiji lọwọ gbogbo awọn to ṣẹ nipa awọn nnkan to ṣe lasiko to ṣe gomina laarin ọdun 2010 si 2014, bẹẹ lo ke sawọn ọmọ ẹgbẹ lati darapọ mọ eto irapada.

Ṣugbọn Gomina Ayọdele Fayoṣe ti sọ pe ki Fayẹmi ma ti i dunnu rara nitori PDP yoo tun bori ju eyi to waye lọdun mẹrin sẹyin lọ. O ni aṣeyọri ẹlẹmii-kukuru ni gomina tẹlẹ naa ni, ẹgbẹ awọn yoo le e lọ lasiko idibo oṣu keje, ọdun yii.

O waa ni PDP dupẹ lọwọ APC pẹlu bi wọn ṣe gbe oludije tawọn eeyan ko ni i dibo fun kalẹ nitori yoo rọrun fawọn lati maa ba ijọba lọ.

COVER

Mo ti change headline Ota yii o, e wo eyi to wa ninu story te e plan ti mo correct

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.