Mi o so pe mi o ni i da soro oselu lodun to n bo __Ọbasanjọ

Spread the love

Nigba ti aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Oloye Olusẹgun Ọbsanjọ, n ba awọn ọmọ Owu bii tiẹ sọrọ niluu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, lopin ọsẹ to kọja, awọn akọroyin gbe e jade pe baba naa ni oun ko ni i da si ọrọ ipolongo ibo fun ẹnikẹni sipo aarẹ lọdun to n bọ. Ṣugbọn nigba ti yoo fi di irọlẹ Sannde, ọjọ Aiku, ti i ṣe ọjọ keji iroyin yii, Ọbasanjọ loun ko sọ bẹẹ rara.

Awọn ọmọ Owu nile-loko ni wọn n ṣe ajọdun ọlọdọọdun wọn, ẹlẹẹkẹtadinlọgbọn iru ẹ to waye niluu Iwo. Nibẹ ni Oloye Ọbasanjọ ti ba wọn sọrọ lori ibo ọdun to n bọ, to ni ki wọn ri i daju pe ẹni to ṣee fọkan tan ni wọn dibo fun.

Ọna ti Ẹbọra Owu gba ba awọn eeyan Owu sọrọ, ti wọn ni ko fẹẹ sọipade ọhun di ti oloṣelu, lo jẹ kawọn akọroyin kan gbe e jade lọjọ Satide naa pe Ọbasanjọ ti pada lẹyin Atiku to loun fọwọ si tẹlẹ, nitori ko darukọ oloṣelu to n dupo aarẹ naa titi to fi pari ọrọ ẹ.

Ohun ti wọn ni Ọbasanjọ sọ yii lo tun mu awuyewuye waye, tawọn eeyan fi n sọ pe o da bii pe o ti pada lẹyin Atiku loootọ. Ṣugbọn nigba ti yoo nirọlẹ ọjọ Aiku ti i ṣe Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, atẹjade kan ti ọdọ Ọbasanjọ wa.

Bo tilẹ jẹ pe baba naa ti lọ sorilẹ-ede Cairo lọjọ Aiku naa, nibi to ti lọọ ba wọn ṣeto kan ti wọn pe ni Intra-African Trade Fair, sibẹ, akọwe iroyin ẹ, Ọgbẹni Kẹhinde Akinyẹmi, buwọ luwe naa lorukọ aarẹ tẹlẹ, wọn si ṣalaye sinu ẹ pe Ọbasanjọ ko sọ pe oun ko ni i da si ipolongo ibo lọdun to n bọ o.

Atẹjade naa sọ pe ni gbogbo igba to ba yẹ ki Ẹbọra Owu sọ si bi Naijiria ṣe n lọ ni yoo maa sọrọ, nitori oponu eeyan ni wọn yoo maa ba ilu baba rẹ jẹ loju ẹ ti yoo si maa wo, ti ko ni i wi nnkan kan.

Abala kan ninu atẹjade naa ka pe,’’ ipurọ mọ ni, ati ibanilorukọ jẹ ni fun ẹnikẹni lati sọ pe Oloye Ọbasanjọ ko ni i da si ọrọ oṣelu, tabi ṣatilẹyin fun ondije to ba daa. Baba ko fẹẹ sọ ayẹyẹ awọn Owu di ti oloṣelu lo ṣe sọ ọ ni ti mọlẹbi. Ohun to sọ ni pe oun ko ni i gbe ẹnikẹni le wọn lori pe ki wọn dibo fun un dandan, ki wọn ṣaa ri i daju pe eeyan gidi ni wọn dibo wọn fun. ‘’Ọbasanjọ ki i ṣe oponu, bẹẹ ni ko gọ. Omugọ eeyan ni yoo sọ pe ko kan oun nigba ti wọn ba n ba ilu ẹ jẹ. Fun idi eyi,  Ọbasanjọ ko ni i dakẹ lori bi wọn ṣe n ṣe Naijiria lasiko yii, to jẹ kedere lo foju han pe nnkan ko lọ bo ṣe yẹ’’

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.