“Mi o ni mi o ki i ṣe ọba ilẹ Yoruba mọ o, mo kan ni ẹ le maa pe ni Ẹmia naa ni o” Oluwoo ilu iwo.

Spread the love

Oluwoo ilu Iwo, Ọba Adul-Rasheed Akanbi, sọ lanaa ọjọ sannde pe oun ko figba kan yan oye Emir dipo ọba ilẹ Yoruba, oun kan sọ pe wọn le pe oun ni Emir ni, pe ko si oun to buru nibẹ.

Oluwoo loun sọrọ yii lati yanju ọrọ ti awọn eeyan n gbe kiri pe oun loun ko jẹ ọba Yoruba mọ, oun kan sọ eleyii lati fi jẹ ki o ye awọn ọmọ ilẹ Yoruba pe ede lo yatọ, nnkan kan naa ni Hausa ati Yoruba jọ n sọ bi wọn ba n pe Emir ti awa si n pe Ọba.

Ọba Abdul-Rasheed loun ti rin irinajo lọ si awọn ilẹ Hausa to jẹ wọn ki i le pe “Ọba” nitori ede wọn, dipo bẹẹ wọn yoo pe oun ni Emir, oun yoo si da wọn loun nigba toun mọ pe nnkan kan naa ni awọn jọ n sọ.

Nipari, Oluwoo ni baba gbogbo Naijiria loun, oun ko le da awọn Hausa ti wọn n pe oun ni Emir lẹkun.

 

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.