Mi o ni i ja eyin araalu kule__Buhari

Spread the love

Aare Muhammadu Buhari seleri pe oun ko ni i ja awon araalu kule ninu igbagbo ti won ni ninu oun bi won ba dibo yan oun sipo aare pada lodun to n bo.Aare soro yii nigba to n ka oro apileko re to fi gba lati dije loruko egbe oselu APC ninu ibo aare odun to n bo.

Nigba to n salaye idi pataki ti o fi ye lati tun dupo aare, o so pe ise akanse lorisiirisii nijoba oun ti gbe se lagbon eto aabo, oro aje, ina oba gbigbogun ati iwa ibaje. Ko sai menuba eto ounje ofe to ni ijoba oun se kaakiri awon ileewe alakoobere nile Naijiria. Bee lo ni ijoba oun ti se ona lorisiirisii kaakiri awon ipinle lorileede wa.

O gbosuba fun Oluye Bola Tinubu to je asiwaju egbe naa, Oloye Bisi Akande toun naa ti figba kan je alaga egbe won ati Oloye John Oyegun to je alaga egbe naa titi to fi fipo naa sile lodun yii ati awon gomina egbe oselu APC gbogbo fun ise takuntakun ti won se lati di opo egbe naa mu.

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.