Mi o julẹ tori 2023, ọwọ Amosun ni mo ti fẹẹ gbajọba— Dimeji Bankọle

Spread the love

Olori ile igbimọ aṣoju nigba kan, Ọnarebu Dimeji Bankọle, toun naa n dije dupo gomina nipinlẹ Ogun, ti sọ pe kawọn eeyan yee sọ pe nitori ọdun 2023 loun ṣe n julẹ lasiko yii, toun n polongo ibo kiri. O ni ko sohun to jọ bẹẹ, ọwọ Amosun loun ti fẹẹ gbajọba, 2019 yii si ni.

Ṣe ohun tawọn eeyan n sọ ni pe awọn kan wa ninu awọn ondije dupo gomina nipinlẹ Ogun tawọn naa mọ pe ko si kinni kan fawọn, ṣugbọn ti wọn kan fẹẹ maa julẹ de ọdun 2023, bẹẹ lawọn mi-in wulẹ n fowo ati akoko wọn ṣofo lasan. Ọkan ninu awọn ondije bẹẹ ni wọn pe Dimeji Bankọle.

Lati fi otitọ to wa nidii ọrọ yii han lọkunrin to n dije labẹ asia ẹgbẹ Action Democratic Party (ADC), naa ṣe pepade awọn akọroyin sile ẹ to wa l’Abẹokuta, to si sọ pe oun ko tori 2023 polongo o, 2019 yii loun fẹẹ di gomina Ogun, ọdun karun-un si ree toun ti ni ipinnu naa lọkan oun.

O ni ohun to jẹ koun maa fi erongba oun, paapaa lori koko ipolongo kan ṣoṣo toun yan laayo, eyi ti i ṣe ipese iṣẹ fun gbogbo eeyan han niyẹn.

Dimeji ni lẹyin ọdun kẹjọ toun ti kuro lọfiisi aṣofin, iṣẹ toun ṣe sibẹ ṣi n fọhun labala ilera, biriiji Ọta toun ṣe atawọn mi-in to pọ. Bẹẹ naa ni idagbasoke yoo tun ba awọn ẹka yooku boun ba wọle ibo gomina ti yoo waye loṣu to n bọ.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.