Mathew to ji ọkada Risi ni Mọdakẹkẹ ti dero ẹwọn

Spread the love

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ Adetunji Mathew, ẹni ọdun mejilelogun lori ẹsun ole jija.

 

Inspẹkitọ Ọna Glory to jẹ agbefọba lori ọrọ naa sọ funle-ẹjọ pe lagbegbe Itamẹrin, niluu Mọdakẹkẹ, ni Matthew ti ji ọkada naa lọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ọdun to kọja.

 

Aago mejila ọsan ni olujẹjọ ji ọkada BAJAJ Boxer alawọ pupa, to ni nọmba FKJ 531 QJ, Chassis No: MD2A18AY3JWB89078 ati Engine No: DUZWJB89184 gẹgẹ bi Ona ṣe wi.

 

Owo ọkada naa, eleyii to jẹ ti Arabinrin Adegoke Risikat ni wọn pe ni ẹgbẹrun lọna ọrinlelugba o le mẹfa Naira (#286,000).

 

Inspẹkitọ Glory ni ijiya wa fun nnkan ti Mathew ṣe yii ninu abala irinwo o din mẹwaa iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ọṣun ti ọdun 2003.

 

Olujẹjọ, ẹni ti ko ni agbẹjọro kankan to n ṣoju ẹ, sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ole jija ti wọn fi kan oun rara.

 

Adajọ Muhibah Olatunji sọ pe oun ko ni i faaye beeli silẹ fun olujẹjọ lati le jẹ ẹkọ fun awọn ọdọ bii tiẹ ti wọn le maa gbero iwa iru eleyii.

 

O waa paṣẹ pe ki wọn lọọ fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileefẹ titi di ọjọ keje, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ti igbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.

 

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.