Lọwọ yii, afi ki Saraki fi odidi aja, agbo ati obukọ rubọ

Spread the love

Adajọ kan wa ti ko gba igbakugba, oun ni gbogbo aye n pokiki ẹ bayii o. Orukọ adajọ naa ni, Olubukọla Banjoko. Laarin ọsẹ meji pere, adajọ naa ti sọ awọn gomina atijọ meji sẹwọn, ko si faaye owo itanran silẹ fun wọn, o ni ọrọ wọn ti kọja ẹni ti wọn n gba owo itanra lọwọ rẹ, ki wọn maa lọ sẹwọn wọn soose ni. Adajọ yii lo sọ Jolly Nyame, baba kan to ni oun Rẹfurẹndi, to ṣe gomina ipinlẹ Taraba laarin ọdun 1999 si 2007 sẹwọn, oun na lo si ju Joshua Dariye to sa mọ awọn oyinbo lọwọ nigba toun naa n ṣe gomina laarin ọdun 1999 si 2007, ẹwọn ọdun mẹrinla ṣagidi. Inu awọn EFCC naa dun, nitori ẹjọ bii mejila ni wọn ni awọn gbe siwaju awọn adajọ oriṣiiriṣii, ẹjọ naa jẹ ti awọn gomina to ti kowo jẹ, wọn si ti n ṣe awọn mi-in lati bii ọdun mẹẹwaa sẹyin ti wọn ko ri i yanju. Adajọ Banjoko yii ni adajọ akọọkọ to yanju ẹjọ tirẹ. Meji pere naa ni wọn fun un ninu gbogbo ẹjọ EFCC, mejeeji naa lo si ti pari bayii, ẹwọn lọrọ naa si ja si fawọn ti wọn mu de ọdọ rẹ. Iyẹn laya awọn ti wọn fẹran Saraki ṣe n ja gan-an. Wọn ni yoo mura si iṣẹ aafaa, bo ba le de ọdọ awọn wolii naa, yoo lọ sibẹ, yoo si fi ewurẹ mọkanlelogun, aja mọkanlelogun, obukọ mọkanlelogun rubọ. Bo ba ti fi awọn nnkan wọnyi rubọ, bẹẹ ni yoo maa ju awọn ohun rẹ si i pe, ‘a ki i tori gbigbo ka pa aja; a ki i tori kikan ka pa agbo; a ki i tori werewere pa obukọ; ọrọ owo ti wọn ni mo ko jẹ yii di aṣegbe, emi Saraki paapaa di aṣegbe, aṣegbe ọmọ Edumare.’ Wọn ni o da bii pe ohun to le gba a silẹ ninu ọrọ to wa nilẹ yii niyẹn o. Idi ni pe wọn ni wọn fẹẹ gbe Adajọ Banjoko kuro nibi to wa, ọdọ igbimọ to n gbọ ẹjọ Saraki, CCT, ibẹ gan-an ni wọn ni wọn fẹẹ gbe e lọ. Loootọ ijọba ti ni ki i ṣe bẹẹ, iyẹn ni Saraki ṣe tete gbọdọ rubọ, ki wọn ma gbe obinrin naa lọ sibẹ o. Nitori bi obinrin naa ba fi le di alaga igbimọ yii, to si jẹ iwaju rẹ ni ẹjọ Saraki wa, ti wọn n ṣe ẹjọ naa yọbọyobọ lati ọjọ yii wa, afaimọ ko ma jẹ paapaapaa ni yoo ṣe ẹjọ naa o. Ko si si Abuja lọrun ọpẹ, ẹwọn sireeti ni, iyẹn lo ṣe jẹ bi nnkan ti ri yii, bẹ ẹ ba ti ri Saraki, ẹ so fun un pe yoo rubọ o, afi ko tete rubọ o, bi bẹẹ kọ, haa, bi bẹẹ kọ, ko ma di ohun ti wọn yoo maa fi agbada ranṣẹ si i lọgba ẹwọn Kuje. Ko rubọ aṣegbe, ko rubọ ayalu, Ọrunmila lo sọ bẹẹ. Ẹ sọ fun un ko fi owo aniyan silẹ, ọfẹ la fi fun ni!

(153)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.