Lọwọ ti Buruji Kaṣamu wa yii, APC lo dun

Spread the love

Wọn ni Buruji n palẹmọ o, wọn lo n mura bayii, baba n fẹẹ fo gọta. Bii ti bawo, o fẹẹ fo gọta sodikeji ni, ko si si odikeji kan ti yoo lọ, bo ba fo gọta bayii, inu APC ni yoo balẹ si, lau! O yẹ ki gbogbo awọn ti wọn ba mọ awọn eeyan wa daadaa, ti wọn si mọ nipa oṣelu ti mọ pe ko si ibi ti Buruji Kaṣamu yoo lọ, tabi ohun ti yoo ṣe, yoo wọ inu APC gbẹyin ni. Oun naa kuku ri gbogbo awọn ole ati jẹgudujẹra oloṣelu ti wọn wọ inu ẹgbẹ naa, o ri i pe bi wọn ti n wọ inu rẹ ni wọn di angẹli tuntun, angẹli ti ko dẹṣẹ nibi kan ri. Musiliu lo n yan kiri igboro nni, oun lo ti di iyawo ọlẹlẹ ti wọn n gbe kaakiri yii. Bi EFCC ba fẹẹ sọrọ, wọn yoo ni ole ni Fayoṣe, wọn ko si ni i darukọ Ọbanikoro to jẹ oun ni baba rẹ. Tabi ti Orji Uzor Kalu to da ẹgbẹ “Buhari-la-fẹ” silẹ leeyan ko ni i ranti, ole ti wọn n le kiri lọjọ yii, ti EFCC lawọn yoo gbe e. Ewe APC lo ja, loun naa ba fi ṣe oogun aṣegbe, lati ọjọ naa lo ti n jaye ori rẹ lọ. Wọn ni Buruji ṣe aṣemaṣe l’Amẹrika, wọn si n wa a lọhun-un, wọn ti fa a titi ko lọ, lo ba n pe ẹjọ loriṣiiriṣii. Ṣugbọn nigbẹyin, awọn adajọ ti ni ko si wahala nibẹ nao, bi ọwọ rẹ ba mọ ko lọọ ba wọn nile-ẹjọ lọhun-un, ko lọ si Amẹrika, ko lọọ sọ ohun to mọ ninu ẹsun ti wọn fi n kan an kaakiri. Ọrọ naa ko tẹ Buruji lọrun, oun ko fẹẹ de Amẹrika laye ijọba Trump yii, o ni ohun to le gan-an ni. Oun naa kuku mọ, o mọ pe ijọba Naijiria le ṣu oun rugudu nijọ kan, nigba ti yoo ba si laju bayii, iwaju ile Trump gan-an ni wọn yoo gbe e si, o ko tiẹ niyẹn. Buruji ko fẹ ki eleyii ṣẹlẹ, ibi kan naa to si le sa wọ ni inu APC, nibi ti ohun gbogbo yoo ti lọ si ilu isinmi. Njẹ ẹyin APC, ẹ ku ojulọna, Buruji Kasamu n bọ, ọkunrin to koriira Amẹrika de gongo, o loun ko fẹ koun ati Trump tilẹ foju kan ara awọn. Ṣonṣo meji, wọn o gbọdọ foju rinju! Eewọ ni!

(69)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.