Lori ọrọ ile wọn tawọn ọmọ onilẹ fẹẹ wo, awọn eeyan Abusọrọ rawọ ẹbẹ si Deji

Spread the love

Ọgọọrọ awọn eeyan to n gbe lagbegbe Abusọrọ, Olu Foam, l’Akurẹ, ni wọn ṣe iwọde alaafia lọ si Aafin Deji ilu Akurẹ, Ọba Aladelusi Aladetoyinbo, lori ile wọn tawọn ọmọ onilẹ kan fẹẹ wo.

 

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ lati ẹnu Abilekọ Abimbọla Grace to jẹ ọkan lara awọn lanlọọdu adugbọ naa, o ni o ti le logun ọdun tawọn ti ra ilẹ tawọn kọle si yii, ti ko si sẹni to waa yọ awọn lẹnu.

 

Ọdun 2017 lo ni ọkan ninu awọn idile to n ba ara wọn ja gba idalare nile-ẹjọ pe awọn lo lẹtọọ si gbogbo ilẹ to wa lagbegbe naa, ti kootu ko-tẹmi-lọrun si tun fidi idajọ yii mulẹ ninu oṣu kejila, ọdun 2018.

 

Awọn idile ti ile-ẹjọ da lare lo ni wọn fi dandan le e pe ọkọọkan awọn lanlọọdu to n gbe lagbegbe ọhun gbọdọ san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (#500,000), lati tun ilẹ ti awọn ti kọle si ra.

 

O ni lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ lawọn ẹbi ọhun gba lati din owo ti wọn n beere fun naa ku si ẹgbẹrun lọna ọta lelugba o din mẹwaa Naira (#250,000).

 

Gbogbo arọwa awọn lati igba naa boya awọn ẹbi ọhun tun le din owo ọhun ku diẹ si i ti ko seso rere lo ni o ṣokunfa bi wọn ṣe wa si Aafin Deji ko ba awọn da sọrọ naa.

 

Ọkan ninu awọn olugbe adugbo naa to jẹ obinrin lo sọ pe o deede ṣubu lulẹ, to si ku lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja lọ lọhun-un nigba to gbọ pe awọn ẹbi naa n gbe katakata bọ lati fi wo ile wọn.

 

Lẹyin wakati diẹ ti wọn ti wa laafin ni olori awọn oṣiṣẹ Deji too yọju si wọn, to si ni ki awọn araadugbo naa lọọ kọ gbogbo ohun to jẹ ẹdun ọkan wọn sinu iwe, ki wọn si mu un pada wa fun oun.

 

A gbọ pe Ọba Aladetoyinbo pada ba wọn da sọrọ ọhun, to si fi awọn eeyan naa lọkan balẹ pe wọn ko ni i wo ile wọn titi ti wọn yoo fi ri ọrọ ọhun yanju laafin.

 

Iroyin ta a gbọ laaarọ kutukutu ọjọ keji ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ni pe awọn ọmọ onilẹ ti bẹrẹ si i wo ile lagbegbe naa.

 

Akọroyin wa ṣabẹwo sibẹ, a si ri abilekọ kan to sun silẹ ti wọn n rọ omi le lori. Obinrin ọhun ni wọn lo daku nigba to ri katapila to gbe ẹnu ti ile wọn to fẹẹ maa wo o. O fẹrẹ to bii ọgbọn iṣẹju lẹyin ta a ti wa nibẹ ki wọn too ri ẹni to daku naa ji pada saye.

 

Niṣe lawọn eeyan adugbo naa kunlẹ, tawọn mi-in si dọbalẹ, ti wọn n rababa niwaju ọkan ninu awọn ọmọ onilẹ naa pẹlu katakata to gbe wa lati fi wo awọn ile to ba ti kuna lati fọwọ sowọ pọ pẹlu rẹ.

 

Awọn ile kan la ri ti wọn ti yọ diẹ ninu paanu to wa lori wọn, ti katakata ọhun si n wo awọn fẹnsi ti wọn mọ yi awọn ile ti wọn ko ti i kọle si lulẹ.

 

Mọto ọlọpaa ta a ba nibẹ to meje, awọn ọmọ onilẹ la gbọ pe wọn ko awọn ọlọpaa atawọn tọọgi wa lati fi daabo bo ara wọn nitori ibẹru akọlu ti wọn lero pe awọn eeyan le ṣe si wọn.

 

Ko ti i si odidi ile kan pato ti wọn wo lulẹ titi ta a fi kuro laduugbo naa ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ yii. Ọkan ninu awọn ọmọ onilẹ ọhun la gbọ to n kilọ fawọn to kọle sori ilẹ naa pe oun fun wọn lọsẹ mẹta pere ki wọn fi waa san owo ilẹ toun n beere lọwọ wọn.

Gbogbo akitiyan wa lati ri Akọwe iroyin Deji, Ọgbẹni Michael Adeyẹye, ba sọrọ ka le mọ igbesẹ ti wọn n gbe laafin lori iṣẹlẹ ọhun lo ja si pabo.

 

 

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.