Lori ọrọ awọn ajinigbe, awọn aṣaaju PDP ati APC sọko ọrọ sira wọn.

Spread the love

Awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC ti bẹrẹ  si i sọko ọrọ sira wọn lori wahala ijinigbe tawọn eeyan ipinlẹ Ondo n koju.

 

Alukoro ẹgbẹ PDP ni Ẹkun Iwọ-Oorun orilẹ-ede yii, Ayọ Fadaka, lo kọkọ fi atẹjade kan sita nibi to ti fi aidunnu rẹ han lori ipo ti eto aabo ipinlẹ Ondo wa.

 

O ni ọrọ awọn ajinigbe naa ti n kọja bo ṣe yẹ pẹlu bi wọn ṣe n fi ojoojumọ ji awọn eeyan gbe lawọn oju ọna to wọ ipinlẹ Ondo, yatọ si awọn mi-in ti wọn ti ji gbe ninu ile wọn.

 

Fadaka ni oun to ba ẹgbẹ awọn ninu jẹ lori iṣẹlẹ naa ni iha ko kan mi ti Gomina Rotimi Akeredolu ati ijọba rẹ n kọ si ipenija aabo tawọn eeyan to n ṣejọba le lori n koju.

 

Ninu atẹjade ọhun lo ti bẹnu atẹ lu bi Akeredolu ati ẹgbẹ APC ṣe n parọ fawọn eeyan orilẹ-ede yii pe ohun gbogbo n lọ deede nipinlẹ Ondo, dipo ti wọn i ba fi kegbajare, ki wọn si wa gbogbo ọna ti wọn yoo fi kapa awọn ajinigbe naa.

 

Gbogbo wahala to n ṣẹlẹ ọhun lo ni o ṣi n tẹsiwaju latari bi ijọba ṣe kuna lati ṣagbekalẹ ofin ati ilana tọwọ yoo fi tete tẹ awọn oniṣẹẹbi naa, ki wọn si koju ijiya to ba yẹ, eyi to le jẹ arikọgbọn fun awọn mi-in to ba tun fẹẹ huwa ọdaran.

 

O ni o ṣee ṣe ki ijọba yii tẹ siwaju lati maa ja awọn araalu kulẹ titi di igba ti oun funra rẹ yoo fi mọ pe loootọ loun ko kun oju oṣuwọn lati tukọ ipinlẹ Ondo.

 

Yoruba bọ, wọn ni isọrọ ni igbesi, pẹlu bi Akọwe iroyin fun gomina, Ṣẹgun Ajiboye, ko ṣe fọrọ falẹ to fi sare fun Fadaka lesi ọrọ rẹ.

 

Ajiboye sọ ninu atẹjade to fi sita pe okiki lasan lẹgbẹ PDP n wa lori ọrọ ti wọn sọ nitori pe ọrọ ko dun lẹnu iya ole, o ni ipo ifasẹyin ati aifọkanbalẹ ti ipinlẹ Ondo wa lọwọlọwọ ko ṣẹyin wọn.

 

O juwe ẹsun ti Fadaka fi kan Akeredolu lori iha to kọ sọrọ awọn ajinigbe bii irọ patapata, o ṣalaye pe o yẹ ki oun funra rẹ gbọ nipa ipade nla kan ti gomina ṣẹṣẹ ṣe pẹlu gbogbo awọn ẹṣọ alaabo, awọn ọba ati awọn Hausa to wa nipinlẹ naa lori ati wa ọna abayọ si ipenija eto aabo.

 

O fi kun un pe ni kete tijọba gbọ nipa iṣẹlẹ olukọ poli Ọwọ to ku sọwọ awọn ajinigbe ni gomina ti lọ sileewe ọhun lati ba wọn kẹdun, to si jẹ pe ṣaaju igba naa ni ijọba ti kọkọ ṣeto ọpọlọpọ ọkọ Hilux fawọn ọlọpaa nitori eto aabo awọn araalu.

 

Ajiboye kilọ fun ẹgbẹ PDP ti Fadaka n gbẹnusọ fun pe ki wọn lọọ sinmi agbaja, nitori pe ja awọn eeyan ipinlẹ Ondo kulẹ lasiko ti wọn fi n ṣejọba.

 

 

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.