Lori lẹta wọn sileeṣẹ aṣọbode, Fayoṣe sọko ọrọ si EFCC

Spread the love

O jọ pe ọrọ Gomina Ayọdele Fayoṣe tipinlẹ Ekiti ati ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra, ‘Economic and Financial Crimes Commission’ (EFCC), yoo  lagbara diẹ lẹnu ọjọ mẹta yii pẹlu bi lẹta kan ṣe jade lọsẹ to kọja, ninu eyi ti EFCC ti ni ki ileeṣẹ aṣọbode maa ṣọ gomina naa ko ma sa lọ.

Ninu lẹta ọhun ti adari ajọ EFCC, Ibrahim Magu, fọwọ si ni wọn ti ta ileeṣẹ aṣọbode lolobo pe awọn n wa Fayoṣe fun igbimọpọ ṣiṣẹ ibi, ṣiṣe magomago nipo gomina, iwa jẹgudujẹra, ole jija ati ikowojẹ. Wọn ni awọn fura si i pe o le fẹẹ gba awọn ẹnu ibode ori ilẹ, ori omi tabi oju ofurufu sa lọ, nitori naa, ki wọn maa ṣọ ọ, ki wọn si pe awọn tọwọ ba tẹ ẹ.

Lara lẹta naa to ni nọmba 3000/EFCC/ABJ/EG/TA/VOL.59/010 ni oriṣiiriṣii afikun wa, eyi tawọn to tẹ lọwọ fi si i lati fi han pe o ṣe pataki. Bakan naa ni lẹta mi-in ti B.A Amajam to jẹ igbakeji ọga-agba ileeṣẹ aṣọbode fọwọ si tẹle e, ninu eyi to ti paṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ abẹ rẹ lati mu ọrọ naa lọkun-un-kundun.

ALAROYE gbọ pe EFCC ti da Fayoṣe loun lori lẹta to kọ si wọn pe oun n bọ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu to n bọ, wọn ni logunjọ, oṣu yii, ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee ọtunla ni ko wa.

Nigba to n fesi si awọn lẹta yii lorukọ Fayoṣe, oludamọran pataki lori ibanisọrọ igbalode fun gomina naa, Lere Ọlayinka, bẹnu atẹ lu igbesẹ ti EFCC gbe, o ni ko pọn awọn ati ijọba apapọ le rara.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘’Ijọba apapọ yii kan naa lo jẹ ki Kẹmi Adeọsun to ṣe ayederu iwe-ẹri agunbanirọ fiṣẹ silẹ, ko si kuro lorilẹ-ede yii. Ki lo de ti wọn ko gbe iru igbesẹ bẹẹ lori Adeọsun?

‘’EFCC to jẹ pe biliọnu kan ni wọn yoo fi ṣewadii ẹni to ji biliọnu kan. Wọn maa mu ẹni to ji ogun miliọnu, wọn maa fi biliọnu sanwo fawọn lọọya to maa rojọ ni kootu. Ole maaluu to n le ole to gbe adiẹ ni wọn.

‘’Gomina ti kọ lẹta si wọn pe oun n bọ, wọn waa ni ko maa bọ logunjọ, oṣu yii. Ofin Naijiria ko faaye gba iru ẹ, ọjọ ti Fayoṣe ba gbejọba silẹ ni anfaani imuniti yii kuro lọwọ rẹ.

‘’Ki EFCC duro de e, ki i ṣe ojo rara, o maa kan si wọn. Ẹ sọ fun Magu ko ma ṣe bii ọmọ ẹgbẹ APC, ko ṣiṣẹ ẹ bii iṣẹ.’’

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.