Lori iku Ayọ Daramọla, mọlẹbi ni kawọn ọlọpaa mu Fayoṣe kiakia

Spread the love

Wahala mi-in tun ti bẹrẹ laarin mọlẹbi Oloogbe Ayọdele Daramọla ati Ayọdele Fayoṣe bayii pẹlu bi awọn eeyan naa ṣe kegbajare lọ sọdọ ọga-agba ọlọpaa ilẹ yii, Ibrahim Idris, pe ko ba awọn fi pampẹ ọba gbe gomina ana ọhun nitori o mọ nipa iku ọmọ awọn.
Ninu atẹjade kan ti Dare Daramọla to jẹ aburo oloogbe kọ lorukọ mọlẹbi ni wọn ti rawọ ẹbẹ naa, eyi si waye nitori Fayoṣe ti gbejọba silẹ bayii, anfaani imuniti to ni ti pari.
Ṣe lọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ọdun 2006, lawọn kan ya bo ile Ayọdeji Daramọla to wa niluu Ijan-Ekiti, ti wọn si ṣeku pa a, latigba naa lawọn mọlẹbi oludamọran fun banki agbaye yii si ti n wa idajọ ododo.
Gẹgẹ bi iwe ẹhonu ti mọlẹbi naa kọ, Fayoṣe lọwọ ninu iku oloṣelu naa nitori o woye pe ko fẹ koun ṣe saa keji, ati pe awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party ati Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ to jẹ aarẹ nigba naa fọwọ si Daramọla gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ naa fun ibo ọdun 2007.
Wọn ni asiko ti oloogbe naa sọ pe oun ko dije mọ ni wọn ṣeku pa a, awọn tọwọ si tẹ lori iṣẹlẹ naa tọka si Dayọ Okondo ati Goke Ọlatunji ti wọn jẹ ọmọọṣẹ Fayoṣe. Lasiko iṣejọba Oloye Ṣẹgun Oni ni wọn ko awọn eeyan naa lọ si kootu, ṣugbọn rogbodiyan oṣelu ko jẹ ki igbẹjọ tẹsiwaju.
‘’Nigba ti Fayoṣe gori aleefa lọdun 2014, igbẹjọ bẹrẹ, ṣugbọn wọn fagile ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan awọn ti wọn mu. Nigba to ri i pe wọn ṣi le gbe ẹjọ ọhun dide lọjọ iwaju lo lẹdi apo pọ pẹlu awọn lọọya kan lati bẹrẹ igbẹjọ tuntun lori ẹjọ oloogbe ati ti Tunde Ọmọjọla ti wọn pa niluu Ifaki-Ekiti lọdun 2005, ki wọn le fagile mejeeji lẹẹkan naa.
‘’ Awọn oninuure kan lo jẹ kawọn oniroyin gbọ, ti wọn fi tu aṣiri ọrọ naa, bẹẹ lo jẹ pe awọn adajọ mẹta ọtọọtọ nile-ẹjọ giga Ado-Ekiti lo yẹra fun ẹjọ naa. Ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ati ile-ẹjọ to ga julọ gan-an ti ṣedajọ tẹlẹ pe kawọn ọlọpaa mu Fayoṣe nitori o lẹjọ lati jẹ lori ọrọ naa.
‘’Ni bayii to ti kuro nipo, to si ti le jẹjọ, ati nitori pe ẹjọ naa ko ti i pari, ki ọga-agba ọlọpaa ba wa mu un gẹgẹ bii ọkan lara awọn afurasi ki igbẹjọ le bẹrẹ ni pẹrẹwu.’’
Ẹwẹ, ibi tọrọ yii n lọ lawọn araalu n woye pẹlu bo ṣe jẹ pe ilu Abuja ni Fayoṣe wa bayii lati ba ajọ to n gbogun ti ikowojẹ (EFCC), lalejo lori ẹjọ to ni lọdọ wọn, ko si sẹni to mọ nnkan ti yoo ṣẹlẹ lọhun-un.

(40)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.