Lori ẹsun ijinigbe, ọmọ iya mẹrin gba idajọ iku l’Akurẹ

Spread the love

Niṣe ni igbe ẹkun gba gbogbo agbegbe ile-ẹjọ giga to wa lagbegbe Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, kan lẹyin ti Onidaajọ A.O. Odusọla paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun awọn ọmọ iya mẹrin kan, Olumide Orogbemi, Sunday Orogbemi, Kẹhinde Orogbemi ati Ọmọsuyi Orogbemi

lori jijẹbi ẹsun ijinigbe ati ipaniyan ti wọn fi kan wọn.

 

Baba awọn ọdaran ọhun, Alagba Earnest Orogbemi, ati ọmọ rẹ mi-in, Idowu Orogbemi, atawọn mẹrẹẹrin ti wọn dajọ iku fun ni wọn fẹsun meji ọtọọtọ ti i ṣe ijinigbe ati ipaniyan kan nigba ti igbẹjọ ṣẹṣẹ bẹrẹ.

 

Wọn ni awọn mẹfẹẹfa lọwọ ninu jiji Dada Olusọla gbe lati ilu Igbọkọda, lọ sinu igbo kan nitosi Zion, lori ọrọ ilẹ kan ti wọn n fa mọ ara wọn lọwọ.

 

Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan wọn pe wọn ṣeku pa Margaret Jimi to loyun oṣu meje sinu nibi ti wọn ti n gbiyanju ati fipa ji i gbe lori ọrọ ilẹ yii kan naa.

 

Onidaajọ Odusọla sọ nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ pe gbogbo ẹri ti wọn fi siwaju ile-ẹjọ fidi ẹ mulẹ pe loootọ lawọn mẹrẹẹrin jẹbi ẹsun ijinigbe ati ipaniyan ti wọn fi kan wọn.

 

Adajọ ọhun waa paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun awọn ọmọ baba ọhun mẹrẹẹrin titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.

 

Ṣugbọn o ni ki wọn da baba silẹ ko maa lọ sile rẹ layọ ati alaafia nitori pe ko si ẹri to fihan pe o lọwọ ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

 

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.