Lori ẹsun idigunjale ile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn yẹgi fawọn meji l’Akurẹ

Spread the love

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

Adajọ ile-ejọ giga kan to wa l’Akurẹ ti paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fawọn ọkunrin meji kan, Dada Ojo ati Emeka Alieze, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn lori pe wọn jẹbi ẹsun idigunjale ti wọn fi kan wọn.

Wọn fẹsun kan awọn ọdaran mejeeji yii lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ pe wọn digun ja awọn eeyan kan lole loju ọna marosẹ Akurẹ si Ileṣa ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹsan-an, ọdun 2017.

Awọn ẹlẹrii bii marun-un ti Agbefọba, Ọgbẹni Ọlajumọkẹ Ogunjọbi, ko wa sile-ẹjọ ni wọn fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni awọn ọdaran ọhun digun ja awọn lole, bẹẹ ni wọn tun royin ohun toju wọn tun ri lọwọ wọn.

Ọkan ninu awọn ẹlẹrii ọhun, Ṣẹgun Akinyọkun, ni ẹnu iṣẹ loun atawọn oṣiṣẹ yooku wa ni ileepo kan to wa ninu ọja Iṣikan, l’Akurẹ, ti awọn ọdaran ọhun fi waa ba awọn lalejo tibọn-tibọn.

Ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ọhun ni gbogbo owo tawọn pa lọjọ naa ateyi to wa lọwọ gbogbo awọn onibaara ti wọn ba lọdọ awọn lasiko ọhun ni wọn fipa gba lẹyin ti wọn ti kọkọ paṣẹ pe ki gbogbo eeyan dojubolẹ.

Ọlọpaa kan, Samson Adebayọ, ninu ẹri tirẹ ni ọfiisi loun wa lọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ọdun naa ti ẹnikan to n jẹ Adeọla Adekunle fi waa fẹjọ sun lagọọ awọn pe awọn adigunjale da oun lọna, ti wọn si fibọn gba ọkọ ayọkelẹ Nissan Primera oun lọ.

Ọkọ ọhun ti nọmba rẹ jẹ FKJ474EE lo ni awọn ri gba pada lẹyin ọjọ diẹ, tawọn si fi pampẹ ọba gbe awọn ti wọn ji i gbe.

Lẹyin ọpọlọpọ ariyanjiyan laarin agbefọba ati awọn agbẹjọro to n gbẹnu sọ fawọn ọdaran wọnyi, ile-ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe loootọ lawọn ti wọn fẹsun kan ọhun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Idi niyi ti Onidaajọ Ademọla Bọla fi ni ki wọn lọ yẹgi fawọn mejeeji titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.