Lori awọn ile ti wọn ti pa, Fayoṣe ati Ọmọtọṣọ sọko ọrọ si EFCC

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe ati Dokita Samuel Ọmọtọṣọ ti sọko ọrọ si ajọ to n gbogun ti ṣiṣẹ owo ilu baṣubaṣu, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), lẹyin ti wọn ti awọn ile kan pa, eyi ta a gbọ pe wọn ni Fayoṣe lo ni wọn.

Ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja ni ajọ EFCC ya bo ilu Ado-Ekiti, ti wọn si lọọ ti awọn ile kan pa. Awọn ile naa ni ilegbee, ọsibitu, ileepo, ileeṣẹ redio Our People’s Voice, ati ile itura to wa lagbegbe Baṣiri, GRA, Fajuyi, Okeṣa ati Ijigbo.

Eyi waye lẹyin bii oṣu kan ti ileeṣẹ to n ri si aato ilu ti ile kan ti wọn pe ni ti Fayoṣe lagbegbe GRA, niluu Ado-Ekiti, pa.

Iroyin to gba ilu lọsẹ to kọja ti EFCC ti awọn ile naa ni pe nitori Fayoṣe ni, eyi ko si ṣẹyin ẹjọ ti wọn n ba a fa pe o gba owo lọwọ oludamọran eto aabo ilẹ yii tẹlẹ, Ọgagun Sambo Dasuki, bẹẹ lo hu awọn iwa ti ko bofin mu mi-in.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹwaa si mọkanla lawọn aṣoju ajọ naa ti awọn ile ọhun pa, nigba ti akọroyin wa si debẹ la ri akọle ti wọn kọ sara awọn ile naa pe: ‘’Pẹlu aṣẹ EFCC: a n ṣewadii ile yii lọwọ, kuro ni sakaani yii’’.

Nigba ta a kan si i, Layi Ọyawa to jẹ manija ileeṣẹ redio Our People’s Voice, o ṣalaye pe oun ko mọ idi ti EFCC ṣe waa ka awọn mọ. O ni Babatunde Ọmọtọba lorukọ ọga-agba ileeṣẹ naa, abẹ Ijemu Nigeria Limited si ni redio ọhun wa.

O waa ni iwadii ni EFCC sọ pe awọn fẹẹ ṣe, ki wọn maa ṣe e lọ, awọn naa yoo maa ba iṣẹ lọ.

Ninu alaye ti Dokita Samuel Ọmọtọṣọ ṣe lori ileewosan igbalode rẹ ti EFCC gbẹsẹ le l’Okeṣa, o ni o yẹ ki ajọ naa ṣewadii wọn daadaa ki wọn too maa gbe ile ti pa laimọ ẹni to ni in.

Gẹgẹ bi ọnarebu naa ṣe sọ, ‘’Ti ọrọ yii ba jẹ lori bi mo ṣe jẹ oloootọ si Ọmọwe Ayọdele Fayoṣe ni, o jẹ nnkan to ba ni lọkan jẹ. Mo ti n ṣiṣẹ dokita oyinbo fun bii ọdun mejidinlogun, mo tun jẹ aṣofin, mo si ni orukọ rere ti mo fi n lo igbesi-aye mi.

‘’Inunibini ni EFCC fi n pa nnkan-ini mi pọ mọ ti Fayoṣe, o si yẹ ki wọn ti ṣewadii wọn daadaa ki wọn too maa ba mi lorukọ jẹ. Mo fi asiko yii ke si gbogbo eeyan lati ma gba igbesẹ EFCC yii gbọ, bẹẹ ni mo ke si ọga-agba wọn ko kilọ fawọn ọmọ rẹ ki n le gbe aye mi lalaafia.’’

Ninu esi ti Fayoṣe kede rẹ nipasẹ Lere Ọlayinka to jẹ akọwe iroyin fun un, o ni EFCC kan n fiya jẹ awọn alaiṣẹ pẹlu bi wọn ṣe n ti ile wọn pa ni.

O ni, ‘’ Naijiria nikan ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ yoo ti maa ti ile kiri ki wọn too mọ awọn to ni wọn. Mo n fi asiko yii sọ fun gbogbo eeyan pe emi kọ ni mo ni awọn ile yẹn, ẹnikẹni lo si le ṣe iwadii lori wọn.

‘’Gbogbo ọna ni EFCC fi fẹẹ ba orukọ mi jẹ nitori bi mo ṣe duro lori ootọ, to ba si jẹ lati oke ni wọn ti ran wọn niṣẹ, ki wọn fi tọmọ jẹ ẹ.’’

 

(41)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.