Loootọ ni, Buhari ko fẹran awa ọmọ Naijiria rara

Spread the love

Nigba ti eeyan ko ba lowo lọwọ, ti ko ba si ni ipo agbara, iwa to ba n hu, iwa oniwa ni o. Ẹni to ba fẹẹ mọ ẹni to jẹ ọmọluabi, tabi to dara niwa, ko ba olowo ṣe, ko ba alagbara ṣe, iwa ti awọn mejeeji yii ba hu, paapaa nigba ti wọn ko ni ohun ti wọn fẹẹ gba lọwọ ẹnikẹni, iru ẹni bẹẹ ni ki eeyan gbọkan tẹ, tabi ko pe leeyan gidi. Beeyan ba sọ ni 2015 pe bi Buhari yoo ṣe ri ree, ko sẹni ti yoo gbagbọ o. Fun pe Buhari yoo jade pe oun yoo ṣejọba Naijiria fun ọdun mẹrin mi-in si i jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ eeyan, o si fihan gbangba pe baba arugbo naa ko fẹran ọmọ Naijiria rara, ipo ọla, ipo agbara ati aye alabata ti wọn n jẹ ni Aso Rock ti wọ ọ loju debii pe ko tilẹ nibẹru Ọlọrun. Oun naa paapaa mọ pe ohun to n lọ nilẹ yii ko daa, iṣẹ ko si, owo ko si, inira ba gbogbo eeyan; Buhari naa mọ! Loootọ, “ẹmi n fẹ,” iyẹn ni pe o le wu baba yii ko ṣe daadaa fun wa ju bayii lọ, “ṣugbọn o ṣe ailera fun ara rẹ.” Buhari ko lagbara ti yoo fi ṣejọba ilẹ yii, koda, ko ni ọgbọn ati laakaye ti yoo fi ṣe e. Awọn ole, awọn ti iwa ẹlẹyamẹya ti fọ lori, awọn eeyankeeyan to ko ti ara rẹ ni wọn n ba a ṣejọba yii, ko si ni ọna kan ti yoo fi ka wọn lọwọ ko, tabi ko fi dari wọn, awọn gan-an ni wọn n dari rẹ. Iyẹn lo ṣe jẹ pe bo ba jẹ baba yii fẹran orilẹ-ede yii loootọ, to fẹran awọn eeyan ibẹ, niṣe lo yẹ ko sọ pe oun ko ṣejọba lẹẹkeji, nitori ara oun ko ya daadaa, ati pe nitori oun ki i ṣe ọmọde mọ. Ọrọ iṣejọba Naijiria nilo ọdọ to leegun, to lagbara, to si ni laakaye ti yoo fi sare kiri. Loootọ bi eeyan ba lagbara ti ko ba ni laakaye ati ọgbọn ti yoo fi ṣejọba yii, nnkan ko ni i lọ daadaa, ṣugbọn eyi to buru ju ni ki eeyan ma ni agbara, ko ma tun ni laakaye ti yoo fi ṣejọba. Bẹẹ, afi ti a ba n tan ara wa, ohun to n ṣẹlẹ si Buhari lọwọlọwọ bayii niyẹn. Nigba ti wọn beere lọwọ oun naa pe ki lo de to fi tun fẹẹ ṣejọba lẹẹkeji, o ni nitori awọn ọmọ Naijiria n sọrọ, wọn n pariwo. Ariwo kin ni wọn n pa! Ọrọ wo ni wọn n sọ! Oun naa mọ pe oun ko le sọ pe awọn ọmọ Naijiria lo ni ki oun maa bọ waa ṣejọba, o mọ pe irọ buruku niyẹn, ko si ọmọ Naijiria gidi kan, yatọ si awọn ti iṣẹ ati oṣi ti pa laakaye wọn run, ti yoo sọ pe Buhari loun fẹ. Ṣebi gbogbo ilu lo dibo fun Buhari lọdun 2015, gbogbo wa la n pe e pe oun la fẹ, bi o ba waa di asiko yii ti a ba n sọ pe a ko fẹ ẹ, ṣe iyẹn jẹ pe a ko gbọn ni tabi a ko ni laakaye. Ohun to ṣẹlẹ ni pe wọn purọ fun gbogbo ọmọ Naijiria, irọ naa si mu wa. Ṣugbọn gbogbo wa ti ri i pe irọ ni wọn pa fun wa. Wọn pọn Buhari ni ewe bii ọlẹlẹ, wọn sọ fun wa pe ko si iru rẹ, a si ti ri i pe irọ ni. Loootọ ni iṣoro wa ni Naijiria, o si le ma ṣee yanju ni ọdun mẹrin, ṣugbọn ki i waa ṣe ki ẹni to leri pe oun yoo yanju iṣoro wa ma ri ọna kankan gba laarin ọdun mẹta to debẹ, ko ma ri ibi kankan lọ, ko ma mọ ohun ti yoo ṣe ju ko maa bu awọn ti wọn ti gbejọba silẹ lọ. Ọjọ wo ni a oo ṣe eleyii da? Buhari ko ni imọ nipa iṣẹ ijọba, gbogbo eyi ti a n sọ pe o ṣe ni 1984, iṣẹ Tunde Idiagbọn ni. Bakan naa ni ko mọ nipa eto iṣọkan Naijiria, bo ba n wa iṣọkan wa ni, ko ni i gba awọn Fulani laaye lati maa pa ọmọ Naijiria gbogbo. Ṣebi loju wa ni Ọbasanjo ṣe tu ẹgbẹ OPC ka nijọsi, ṣugbọn Buhari ko ṣe bẹẹ, o n fọwọ bo awọn Fulani apaayan lori ni. Olowo wo lo waa wa niluu yii bayii ti ara ko ni. Ṣe bi a oo ti tun ṣe e fọdun mẹrin ree. Ẹni to ba n sọ isọkusọ pe bi Buhari ba lo ọdun mẹrin mi-in ni nnkan yoo yipada, tọhun ko ni i gbọn layelaye o. Nnkan n bajẹ, Buhari ko si loogun atunṣe, kaka ko si lọ lo loun o lọ mọ yii, ohun to si fihan niyẹn pe ko fẹran wa.

(53)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.