Lọjọ wo la fẹẹ sinmi ninu wahala Buhari pẹlu awọn aṣofin

Spread the love

Ọsẹ to kọja yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari fọwọ si eto iṣuna ọdun yii, iyẹn bọjẹẹti, owo ti ijọba yoo na fun ọdun 2018. Ninu oṣu kẹfa, ọdun ta a wa yii, ọdun ti da si meji, ṣugbọn ijọba Naijiria ṣẹṣẹ gbe eto inawo tirẹ jade fun ọdun to ti da si meji naa ni. Ohun ti wọn n pe ni bọjẹẹti (Budget) ni owo ti ijọba orilẹ-ede kan yoo na fun akoko kan, eto ti wọn si ṣe ni Naijiria nibi ni pe owo ti ijọba yoo na lati oṣu kin-in-ni titi di oṣu kejila ọdun kan ni bọjẹẹti tiwa. Itumọ eyi ni pe ọrọ gbogbo to ba kan bọjẹẹti yii, o yẹ ki wọn ti pari ẹ, o pẹ tan ninu oṣu kin-in-ni, ọdun tuntun, nitori bi bọjẹẹti yii ko ba jade, awọn eeyan ti wọn wa nidii ọrọ aje ati okoowo ko ni i le ṣe ohunkohun. Ọpọlọpọ awọn ileeṣẹ ni yoo kawọ duro ti wọn ko ni i le ṣe ohunkohun, nitori wọn ko mọ iye ti ijọba fẹẹ gbe jade ati ibi ti wọn fẹẹ na owo wọn si. Eyi ni bọjẹẹti ṣe ṣe pataki. Bi ijọba kan ba wa, to ba jẹ ẹgbẹ oṣelu tirẹ lo ni ọmọ to pọ julọ nile igbimọ aṣofin, eto bọjẹẹti yii ki i pẹ rara, nitori ko too di pe bọjẹẹti yii de iwaju igbimọ ni awọn agbaagba ẹgbẹ wọn yoo ti jọ pade pẹlu awọn aṣofin yii, ati aarẹ funra rẹ, ti wọn yoo jọ sọ bi ọrọ owo naa ti jẹ. Ti wọn ba ti ṣe eleyii ni abẹle ti ẹnikẹni ko mọ, nigba ti bọjẹẹti ba de ile-igbimọ, geere ni yoo lọ. Eleyii ni yoo jẹ pe awọn eeyan naa ti ṣe iṣẹ abẹle to yẹ ki wọn ṣe daadaa. Ṣugbọn adanwo gidi ni ijọba APC, lati ori Aarẹ Buhari funra ẹ titi de ori awọn aṣofin. Adanwo buruku gbaa ni wọn fun gbogbo ọmọ Naijiria. Ija ti wọn n ba ara wọn ja ko jẹ ki nnkan lọ bo ṣe yẹ ko lọ, ko jẹ ki nnkan lọ deede rara, o si n di idagbasoke Naijiria lọwọ. Ninu ofin ilẹ wa, bi awọn aṣofin ko ba fọwọ si owo kan, ijọba tabi aarẹ rẹ ko gbọdọ na an, to ba n na iru owo bẹẹ, o n ru ofin ilẹ yii ni, iru ọrọ bẹẹ si le ṣe akoba gidi fun un lọjọ iwaju, nitori aarẹ to ba ru ofin ile-igbimọ, lilọ ni yoo lọ. Ṣugbọn Buhari n ru ofin ile-igbimọ daadaa, nitori awọn aṣofin funra wọn ko ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe: wọn ko mọ iṣẹ wọn ni iṣẹ, ọlẹ si tun pọ laarin wọn. Eleyii ni wọn fi n tako ara wọn, bẹẹ ọmọ APC naa ni gbogbo wọn. Bọjẹẹti ti wọn gbe jade yii, Buhari sọ pe gbogbo iṣẹ ti oun fẹẹ ṣe fun ilu lawọn aṣofin ti ge danu, wọn tun din owo iṣẹ oun ku, bẹẹ ni awọn aṣofin ni awọn ko le ṣe ki awọn ma ṣe iṣẹ awọn, wọn ni gbogbo iṣẹ ti Buhari n sọ pe oun fẹẹ ṣe yii, oju kan lo rọ gbogbo ẹ si, ilẹ Hausa nikan lo ko gbogbo iṣẹ idagbasoke lọ. Ta waa ni ka gbagbọ? Eyi ti Buhari sọ yii, ọrọ gidi ni, ṣugbọn ohun ti awọn aṣofin paapaa wi naa ko ṣee rọ danu, abi bawo ni aarẹ yoo ṣe ko gbogbo iṣẹ to fẹẹ ṣe fun Naijiria si ilẹ Hausa nikan. Wọn fi ṣe oun paapaa ni! Tabi wọn ti ṣe ipade tẹlẹ pe ki oun naa ta Naijiria fawọn Hausa ni, nigba ti ki i ṣe oun ni yoo kọkọ ṣe ijọba ni Naijiria. Ṣugbọn ju gbogbo ẹ lọ, ẹgbẹ APC ni ko pe awọn aṣaaju wọn ki wọn si ba wọn sọrọ, ki wọn le ṣejọba Naijiria ko dara. Bi bẹẹ kọ, ẹgbẹ naa yoo ṣofo ara, yoo ṣofo ẹmi paapaa lasiko ibo to n bọ, nitori ko sẹni ti yoo dibo fun wọn.

(54)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.