Lọjọ ti Tafawa Balewa da awọn oṣiṣẹ ijọba ẹgbẹrun kan silẹ lẹẹkan naa, orin lawọn yẹn n kọ fun un

Spread the love

Balewa tun gbe tuntun de, isi ga ju

Ni ọjọ kẹjọ oṣu kẹfa ọdun 1964, o pe ọsẹ kan geere ti awọn oṣiṣẹ ti da iṣẹ silẹ ni Naijiria, ohun to si le nibẹ ni pe ọrọ naa ti di pe gbogbo oṣiṣẹ Naijiria ni wọn ko ṣiṣẹ mọ. Micheal Okpara, olori ijọba ilẹ Ibo, Eastern Region, ti pe Alaaji Tafawa Balewa to n ṣe olori ijọba apapọ pe ko pe awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin Naijiria, ki wọn jokoo, ki wọn le yanju ọrọ yii. O ni bi awọn ọmọ ile-igbimọ naa ba jokoo, nigba to jẹ gbogbo Naijiria lọrọ kan, wọn yoo le jiroro lori ọrọ naa, wọn yoo mọ ohun to yẹ ki wọn ṣe ati bi wọn ṣe fẹẹ ṣe e, ọrọ yii yoo si rọlẹ, awọn oṣiṣẹ yoo gbọ ẹbẹ, tabi ki awọn ṣe ohun ti wọn ba fẹ fun wọn. O sọ fun olori ijọba Naijiria naa pe lati maa ba awọn oṣiṣẹ ṣe agidi bayii ko le ṣe Naijiria ati ijọba rẹ lanfaani, ohun to yẹ ijọba ni lati farabalẹ gbọ ọrọ wọn, ki wọn si jọ jokoo lati jọ yanju ọrọ yii laarin ara wọn.

Ṣugbọn Sardauna ni Sokoto ti i ṣe olori ijọba wọn nilẹ Hausa, Northern Region, ati Ladoke Akintọla, ti i ṣe olori ijọba Western Region, kilọ fun Balewa pe ko ma gbọ ohun ti awọn eeyan bii Okpara n sọ yii o, nitori bo ba gbọ, to pe awon aṣofin, ẹyin awọn oṣiṣẹ ni awọn aṣofin NCNC ati ti AG yoo wa, wọn yoo si sọ gbogbo aṣofin NPC di ọta awọn araalu ni, paapaa nigba to jẹ wọn ko ni i le ṣe gbogbo ohun ti awọn oṣiṣẹ yii fẹ ki wọn ṣe fun wọn. Wọn ni ki wọn fi wọn silẹ, ki wọn jẹ ki wọn maa ba ija naa lọ, ki ijọba si maa wa ọna ti yoo fi ṣẹ wọn lapa. Wọn ni bi ijọba ba ti le ri wọn ṣẹ lapa ti wọn halẹ mọ wọn, boya ọlọpaa ni wọn lo abi ṣọja, ti awọn oṣiṣẹ naa ba fi le bẹrẹ ija laarin ara wọn, o ti pari niyẹn, ko si ohun ti wọn yoo le ṣe mọ, bẹẹ nijọba ko ni i san kọbọ, ohun ti ijọba ba fẹ ni yoo ṣe.

O jọ pe ohun ti ijọba fẹẹ lo ree ti wọn fi sọ pe awọn ti gbọ pe awọn kan fẹẹ fi ipa gbajọba lọwọ Balewa ni, awọn oṣiṣẹ ni wọn si fẹẹ lo lati gbajọba ọhun. Nigba naa, ohun ti awọn ẹgbẹ oṣelu NPC, paapaa Sardauna, n lo ree lati fi ṣe jamba fun awọn alatako wọn. Ohun ti wọn lo fun Ọbafẹmi Awolọwọ naa ree, ni gbogbo asiko ti awọn oṣiṣẹ si da iṣẹ silẹ yii, Awolọwọ wa lẹwọn nigba yii, wọn ti sọ ohun ati ọpọlọpọ ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu rẹ sẹwọn, wọn ni wọn fẹẹ fipa gbajọba lọwọ Balewa ni. Nidii eyi, nigba ti wọn ba ti gbe ọrọ naa jade, ti wọn si halẹ mọ awọn alatako wọn, kaluku yoo sa pada sẹyin, nitori wọn ko ni i fẹẹ ṣẹwọn, wọn mọ pe ẹni ti ijọba naa yoo ko ba ni wọn n wa. Iyẹn ni ko ṣe ya awọn eeyan lẹnu pupọ nigba ti ijọba naa kede pe awọn eeyan kan lo fẹẹ gbajọba lọwọ awọn, wọn kan fẹẹ lo awọn oṣiṣẹ yii lasan ni.

Ẹgbẹ Action Group tori eleyii binu, wọn ni Balewa kan da bii bebi tawọn ọmọde fi n ṣere lasan ni, nitori gbogbo ohun to n ṣe yii ki i ṣe iwa rẹ, awọn ti wọn n ti i wa nibi kan. Wọn ni ṣe nitori ti awọn oṣiṣẹ n beere ẹtọ wọn bayii ni wọn ṣe sọ pe wọn fẹẹ gbajọba lọwọ wọn, ki lo ṣe wọn to jẹ gbogbo ẹni to ba ti n beere ẹtọ rẹ, tabi to ba ni ki wọn ṣejọba Naijiria daadaa ni wọn n fi ẹsun ifipagbajọba kan. Wọn ni gbogbo eleyii ko ya awọn lẹnu o, awọn ti mọ pe iwa ati iṣe awọn ẹgbẹ NPC niyi, ẹgbẹ to fẹẹ maa fi tipatipa ṣejọba le gbogbo ọmọ Naijiria lori. Ohun to n bi ẹgbẹ naa ninu ju ni pe ijọba fẹẹ purọ mọ awọn oṣiṣẹ yii, ko si mu awọn aṣaaju wọn, ki wọn ti wọn mọle, ki wọn le ṣe ohun to ba wu wọn fun wọn nibẹ, bo tilẹ jẹ pe ko si ẹsun gidi kan ti wọn fi kan wọn, to jẹ irọ pọnnbele ni wọn pa mọ wọn.

Action Group ni ko si ohun to buru ninu ohun ti awọn oṣiṣẹ wọnyi n beere, ṣebi wọn fẹ owo iṣẹ wọn lasan ni. Bi wọn ba si ni awọn fẹ Pọn-un mẹwaa, to ba jẹ pọn-un marun-un nijọba ni, ṣebi yoo fun wọn. Ẹgbẹ naa ni eyi ti ijọba n sọ pe alaṣeju lawọn oṣiṣẹ lori pe wọn ni awọn ko fẹ ki wọn sọ owo awọn di yẹbẹyẹbẹ, Action Group ni awọn naa fara mọ iru ọrọ ti awọn oṣiṣẹ sọ yii, nitori ijọba kan naa ni, oṣiṣẹ kan naa si ni, ko siyatọ ninu wọn. Ohun ti ijọba Balewa wi ni pe awọn ko le maa san owo ti awọn yoo san fun oṣiṣẹ to ba wa ni ilu nla bii Eko, fun awọn oṣiṣẹ ti wọn ba wa ni awọn ilu ti ko tobi bii rẹ, tabi ni wahala bii Ibadan. Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ binu, wọn ni awọn ko gba, owo ti oṣiṣẹ ijọba kan ba n gba ni Eko ni eyi to wa ni Pọta naa yoo maa gba, bo ba ti jẹ ipo kan naa ni ipo wọn. Ẹgbẹ Action Group ni tawọn oṣiṣẹ lawọn faramọ.

Wọn ni idi ti awọn fi faramọ eleyii ni pe ijọba funra rẹ naa lo n gbe oṣiṣẹ ti wọn ba gba ni Eko lọ si Ibadan, tabi ki wọn gbe e lọ si Pọta, tabi ki wọn gbe e lọ si awọn ilu ti ko tilẹ lorukọ gidi kan, o si ṣee ṣe ko jẹ Eko ni wọn ti gba iru oṣiṣẹ bẹẹ. Oṣiṣẹ ti wọn ba waa gbe lọ si ilẹ ajoji, nibi ti ko ti lẹnikan, ṣebi o yẹ ki owo tirẹ tilẹ ju ti awọn ti wọn wa niluu tẹlẹ lọ ni, bawo ni ijọba yoo ṣe waa din iru owo ẹni bẹẹ ku. Wọn ni bii ẹni to fẹẹ fiya jẹ awọn oṣiṣẹ naa ni o, eyi ko si dara. Awọn oṣiṣẹ ni awọn ti rẹdi, wọn ni bi ijọba ba ti ṣetan lati sọrọ lori awọn ohun ti awọn sọ kalẹ yii, awọn ti ṣetan lati ba wọn ṣepade, nitori awọn naa ko fẹ ki idaṣẹsilẹ awọn ba eto ọrọ aje Naijiria jẹ rara. Ṣugbọn ijọba lo n sa lati ba awọn oṣiṣẹ ẹ yii sọrọ, wọn ko fẹẹ ṣepade pẹlu wọn, nitori o jọ pe wọn ti mọ pe bi awọn ba jọ pade, ohun tawọn oṣiṣẹ yii ba fẹ yoo ṣẹ.

Kinni kan ni o, Balewa funra rẹ ti jokoo si Eko, ko pada si Bauchi, nibi to ti n lo isinmi rẹ mọ, o ni oun ko le lọ, afi ti ọrọ naa ba yanju. Awọn akede rẹ si sọrọ lori eyi, wọn ni ki wọn wo bi Balewa ti fẹran Naijiria to, oun lo kọ ti ko le sinmi mọ yii o, to ni oun yoo yanju ọrọ awọn oṣiṣẹ to daṣẹ silẹ naa ki oun too pada, bi ko ba si ṣee ṣe mọ, oun yoo pa isinmi naa ti, oun yoo maa ba iṣẹ oun lọ. Ṣe Michael Okpara lo ti kọkọ gba a nimọran pe ko le lọọ jokoo si Bauchi, ko ni oun n lo liifu kan o, abi isinmi wo ni yoo ni oun n ṣe nigba ti gbogbo Naijiria ko ba ṣiṣẹ. O ni ko jokoo si Eko ko yanju ọrọ yii, iyẹn nikan lawọn eeyan yoo fi mọ pe awọn ni olori ijọba gidi. Eyi ni inu awọn mi-in ṣe dun loootọ nigba ti Balewa jokoo si Eko, to n paṣẹ ohun ti awọn minisita rẹ yoo ṣe, to si n halẹ mọ awọn oṣiṣẹ pe ki wọn pada sẹnu iṣẹ wọn.

Eyi ni wọn n sọ lọwọ nigba ti gbogbo awọn tiṣa pata lawọn naa ko ṣiṣẹ mọ, wọn ni ki ijọba apapọ san owo tuntun ti igbimọ Morgan ni ki wọn san, bi wọn ko ba si ti san an, awọn n ba awọn oṣiṣẹ to ku lọ niyi, awọn naa ko ṣiṣẹ mọ. Itumọ eyi ni pe awọn ọmọ ileewe naa ko ni i lọ sibi ẹkọ wọn mọ o, ko ni i si ileewe nibi kan, abi nigba ti awọn tiṣa ko ba ṣiṣẹ, ko ṣa si ẹni ti yoo kọ wọn nileewe, ko si ni i si ẹni ti yoo ṣi ilẹkun ileewe paapaa fun wọn. Eleyii ba awọn ti wọn n ṣejọba paapaa lẹru, wọn ni iru ki tun leleyii, ọrọ naa si tubọ bi Balewa ninu. Ṣugbọn sibẹ, ọkunrin naa ni oun ko le pe awọn asofin lati waa jirooro kankan lori ọrọ yii, nitori ohun to n ṣẹlẹ yii, ọrọ ijọba ni, ijọba oun lo si le yanju rẹ, ki i ṣe ki oun pe awọn aṣofin apapọ ki wọn maa waa da sọrọ ti ko kan wọn, tabi ki wọn ba nnkan jẹ ju bo ti wa lọ.

Ẹgbẹ NCNC sọrọ lori eyi, wọn ni awọn faramọ gbogbo ohun ti Michael Okpara ti i ṣe olori ẹgbẹ awọn ti wi fun Balewa pe ko pepade awọn aṣofin apapọ. Bo ba si jẹ ko le pepade awọn aṣofin apapọ, ko pe ipade awọn Prẹmia, iyẹn ni pe ko pe Akintọla, Ahmadu Bello, Osadebe ati Okpara wa si Eko, ki wọn ṣepade lori ọrọ awọn oṣiṣẹ naa, bi wọn ba ti le ṣe e, ọrọ le tibẹ yanju, nitori awọn agbaagba naa yoo mọ ohun ti wọn le ṣe, nigba to jẹ awọn ni olori ijọba. Wọn ni eyi ti ijọba n sa kiri, to n halẹ mọ awọn oṣiṣẹ, to si kọ lati ba wọn jokoo ṣe ipade yii fihan pe ijọba Balewa ko mọ ohun to fẹẹ ṣe ni. Bi ọrọ ba si daru mọ olori ijọba lọwọ bayii, awọn ẹlẹgbẹ rẹ ni yoo ke si ti wọn yoo jọ fikunlukun lori rẹ, ti wọn yoo si mọ ohun ti wọn yoo ṣe. NCNC ni Balewa ko le ba gbogbo oṣiṣẹ Naijiria ja lẹẹkan, bo ba n ba wọn ja, yoo pa ijọba rẹ lara ni.

Awọn Akintọla ko fẹ iru ipade bẹẹ, nitori wọn mọ pe Okpara yoo bori, nitori yoo mu Denis Osadebe ti ipinlẹ Mid-West mọra, nigba to jẹ ẹgbẹ wọn, iyẹn NCNC, lo n ṣejọba nibẹ. Bi Okpara ba gba ibi kan ti Osadebe naa gba ibi kan, to si jẹ nnkan kan naa ni wọn jọ n sọ, to si tun jẹ ohun ti araalu n fẹ ni, ọrọ yoo di iṣoro fun Balewa ati ijọba rẹ. Iyẹn ni wọn ṣe gba ọkunrin olori ijọba naa nimọran pe ko ma pe ipade kankan, ko maa halẹ mọ wọn, ko maa dẹruba wọn, nigba to ba ya, yoo bori wọn. Iyẹn ni Balewa ṣe n fi ohun lile sọrọ fun awọn oṣiṣẹ yii pe ti wọn ko ba pada si ẹnu iṣẹ wọn laarin ọjọ meji pere, ohun ti wọn o lero pata yoo ṣẹlẹ si gbogbo wọn. Amọ bo ṣe sọ eyi naa ni awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ẹka ti Western Region, labẹ Akintọla, gan-an jade, ti wọn ni nibi ti ọrọ de duro yii, ki Balewa fi ipo rẹ silẹ nikan lo dara julọ.

Wọn ni Balewa ti fihan pe oun ko le ṣe olori ijọba Naijiria ko gun rege, nigba ti ko le tọju awọn oṣiṣẹ ti wọn n ṣe gbogbo iṣẹ ijọba. Wọn ni awọn ko yọ ọrọ naa sọ o, lẹyin ọpọ iwadii awọn ti awọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ati aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ ni West ṣe lawọn ti mọ pe ohun ti yoo ṣe Naijiria lanfaani ju ni ki Balewa kọwe fi iṣẹ rẹ silẹ, ko pada si abule wọn, ko si lọọ maa ṣe iṣẹ agbẹ to ni oun fẹẹ ṣe. Ọrọ yii ka Balewa lara, nitori ko ronu pe oṣiṣẹ tabi ẹnikan le sọ iru ọrọ bẹẹ yẹn soun ni Naijiria, nigba to jẹ gbogbo wọn lo fẹran oun. Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ti wọn sọ bẹẹ naa sọ pe ko sẹni to ro pe Balewa naa yoo sọ iru ọrọ to sọ fawọn oṣiṣẹ yẹn si wọn, nigba to jẹ eeyan daadaa to maa n farabalẹ gbọrọ ni wọn mọ ọn si. Bi Balewa ṣe sọ pe awọn oloṣelu kan lo n lo awọn oṣiṣẹ Western Region, bẹẹ naa lawọn oṣiṣẹ yii sọ pe awọn oloṣelu kan lo n lo oun Balewa funra ẹ.

Bi ọrọ ba ti da bayii, awọn ọlọpaa Naijiria ki i yee sọ pe aja ijọba lawọn, wọn yoo si maa gbo “gboo” “gboo” “gboo” mọ gbogbo ẹni to ba n ba ijọba ja ni. Iyẹn lo ṣe jẹ pe wọn ko fi awọn olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ yii silẹ, bi wọn ba mu wọn loni-in ti wọn ni ki wọn maa lọ sile, wọn yoo tun ni ki wọn maa bọ lọdọ awọn lọla. Bi wọn ba tun debẹ lọla, wọn yoo tun da wọn duro titi tilẹ yoo fi ṣu, lẹyin naa ni wọn yoo sọ pe ọga wọn to fẹẹ ba wọn sọrọ ko si nile, wọn yoo tun pada wa lọla ni o. Awọn ti ina ọrọ naa si n jo ju ni Alaaji Haruna Adebọla ti i ṣe olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ yii, Michael Imoudu to jẹ olori awọn oṣiṣẹ reluwee, Ọgbẹni Chukwuka ati Wahab Goodluck, wọn ko fi ọdọ awọn ọlọpaa yii silẹ nigba kan, nitori awọn ọlọpaa ko yee pe wọn pe ki wọn waa rojọ. Ohun to waa ya wọn lẹnu ju ni pe eyi ko da idaṣẹsilẹ naa duro, o tubọ n le si i ni.

Agba ki i wa lọja ki ori ọmọ tuntun wọ, iyẹn lo mu Ẹni-ọwọ, Biṣọọbu Seth Kale, olori ijọba Aguda l’Ekoo, pe awọn oṣiṣẹ naa si ipade idakọnkọ, o ni ki wọn wa, ki wọn ṣe apọnle foun, ki wọn jẹ ki awọn jọ sọrọ boya oun le ribi da si ọrọ to wa nilẹ naa, ko too di pe kinni naa bajẹ ju bo ṣe wa naa lọ. Biṣọọbu Kale ni oun ko ni ki wọn wa sọdọ oun o, oun loun yoo waa ba wọn ni ile-ẹgbẹ wọn, ki awọn le jọ sọrọ yii. Bi Biṣọọbu Kale si ti wi lo ṣe, o gbera, o di ile ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ yii ni Ebute-Mẹta. Ṣugbọn nigba to debẹ, ko si aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ yii kankan nibẹ, awọn oṣiṣẹ funra wọn lo pọ julọ nibẹ, nitori wọn ko fi ile-ẹgbẹ yii silẹ nigba kan. Bi wọn ṣe ri Biṣọọbu yii bayii, ariwo ni wọn bẹrẹ si i pa, wọn ni, “Kin ni Biṣọọbu n wa o. Ibi ki i ṣe ṣọọṣi, bẹẹ ni oni ki i ṣe Sannde, kin ni biṣọọbu waa n wa o.”

Biṣọọbu Kale ko dahun, kaka bẹẹ, o wọ inu ile wọn lọ, o jokoo sibẹ, awọn oṣiṣẹ ko si yee kọrin lati beere ohun to n wa. Awọn oṣiṣẹ naa ni asiko ti awọn wa yii ki i ṣe asiko iwaasu rara, awọn ko fẹ kẹnikẹni waasu fawọn. Bi ọrọ kan ba wa ti Biṣọọbu fẹẹ sọ, ọdọ Balewa ni ko lọ, nitori Balewa lo sọ pe oun fẹẹ le gbogbo awọn oṣiṣẹ danu, oun lo niidi iwaasu, nitori awọn paapaa ti rẹdi fun un. Awọn oṣiṣẹ yii ni fun Biṣọọbu lati fi Balewa silẹ ki wọn maa waa ba awọn sọrọ ki i ṣe ohun to ba ofin Ọlọrun mu o, Balewa lo lọrọ, oun lo ko owo awọn dani, owo awọn lawọn si fẹẹ gba, ki Biṣọọbu tete lọọ ba a. Sibẹ, ojiṣẹ Ọlọrun naa ko kuku lọ o, o jokoo sibẹ ni. Ibi to ti jokoo ti ko lọ naa ni olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lapapọ yii ti de, bi Alaaji Adebola si ti ri Biṣọọbu yii lo sare lọ sọdọ rẹ, wọn si mu un sẹgbẹẹ kan lati ba a ṣepade pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ mi-in to ti de.

Amọ wọn ko gbadun ipade naa, nitori ariwo, “Oni ki i ṣe Sannde” ni awọn oṣiṣẹ naa n pa ni gbangba, nigba ti ọrọ naa ko si loju, awọn aṣaaju yii bẹ Biṣọọbu Kale pe ko maa lọ, awọn naa yoo pada waa ri i, ṣugbọn bo ba jẹ o raaye loootọ ni, ko lọọ ba Balewa to n ba awọn oṣiṣẹ ja, ko ṣalaye fun un pe ohun to yẹ ko ṣe ni ko pe awọn naa sipade kan, ko si gbọ tẹnu awọn. Wọn ni ki Biṣọọbu Kale sọ fun Balewa pe gbogbo ohun to n daamu le lori yii, ati gbogbo wahala to n fa lẹsẹ yii, ọrọ to n gbọ lati ẹnu awọn minisita rẹ lo fi n huwa sawọn, bẹẹ awọn yẹn ko sọ ododo to wa nidii ọrọ naa fun un. O ni bi wọn ba sọ ododo ibẹ fun un ni, ti Balewa ko ba si gbọ ọrọ awọn ọga rẹ oloṣelu, ko si ohun to le ninu gbogbo ohun to wa nilẹ yii rara, bi awọn ba ti jọ jokoo laarin wakati mẹta, awọn yoo yanju rẹ pata. N ni Biṣọọbu Kale ba lọ.

Ṣugbọn Biṣọọbu Kale ko ti i ri aaye jiṣẹ awọn oṣiṣẹ yii fun Balewa, nigba ti ọkunrin naa jade lojiji, to si ṣe ohun tẹnikan ko ro pe yoo ṣe. O ni lẹsẹkẹsẹ, loju kan naa, oun da gbogbo awọn oṣiṣẹ Naijiria silẹ, ki onikaluku gba ile rẹ lọ. O ni ijọba ko ni oṣiṣẹ mọ, awọn yoo gba awọn oṣiṣẹ tuntun ni, awọn ko fẹ awọn ti wọn ti wa nibẹ tẹlẹ mọ, nitori ọlọtẹ ni gbogbo wọn. O ni ki oṣiṣẹ kan ma de ileeṣẹ ijọba kankan o, nitori awọn yoo rọ ọlọpaa da sita loju-ẹsẹ bayii, ẹni ti ọlọpaa ba si ti gba mu, o n lọ sẹwọn ree, nitori ẹsun pe o fẹẹ doju ijọba bolẹ ni wọn yoo fi kan an, ki eku ile gbọ ko sọ fun toko o. N lọrọ ba di “haa” “hẹn-ẹn,” n lawọn oṣiṣẹ ba n kọrin kiri, “Balewa tun gbe tuntun de, isi ga ju!”

 

 

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.