Lọjọ ti Fẹla taku ni kootu, Awọn ọlọpaa atadajọ sa lọ fun un gbẹyin ni o

Spread the love

Ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹta, ọdun 1977, lawọn ọlọpaa fi ọgbọn ji Fẹla gbe ni kootu, lẹyin ti wọn gba beeli rẹ lori ẹsun ti awọn ọlọpaa fi kan an tẹlẹ pe ko kọ awọn ọmọ to n ba a ṣiṣẹ lẹkọọ to daa lawọn yẹn fi lọọ dana sun alupupu ṣọja, ti wọn si ba a jẹ. Ọjọ keji ti wọn ji i gbe lọ yii naa ni wọn tun gbe e lọ si kootu mi-in, ti wọn ni wọn ba ibọn nile rẹ lọjọ ti ija yii ṣẹlẹ, ibọn ti wọn si ba naa lo jẹ ki ọrọ naa di wahala rẹpẹtẹ, nitori awọn ṣọja ni wọn ro pe o fẹẹ yinbọn naa pa awọn ni. Lọjọ naa, Adajọ Victor Famakinwa taku pe ko si bi oun ṣe le fun Fẹla ni beeli o, nitori ijọba ti gbe ofin tuntun kan dide, ofin ologun ni, ofin naa ni wọn si fi mu Fẹla bayii, bẹẹ ohun ti ofin yii sọ ni pe ẹni ti wọn ba ti mu bẹẹ, ile-ẹjọ kan ko lanfaani lati da a silẹ, wọn ko le gba beeli rẹ, koda, wọn o lẹtọọ lati beere ohun to ṣe ti wọn fi mu un pamọ.

Bayii ni Fẹla wa ni ọgba ẹwọn o, oun ati awọn ọmọọṣẹ rẹ meji kan, wọn ko gba beeli rẹ, ẹjọ bii oriṣii mẹta lawọn ọlọpaa ijọba si pe sọrun oun nikan. Ṣugbọn ọrọ naa ko tan laarin ilu rara, ariwo lọtun-un ariwo losi ni, koda, awọn oniroyin kaakiri agbaye ni wọn n kọ ero wọn lori ọrọ naa, ti wọn si n sọ pe ika ni ijọba yii, pe ijọba Ọbasanjọ ki i ṣe ijọba to ba awujọ agbaye mu mọ, nitori iwa ika ti awọn ṣọja naa hu. Awọn mi-in tiẹ n sọ pe ti wọn ba mu awọn ṣọja ti wọn ṣe iṣẹ buruku bẹẹ, ki wọn gba aṣọ lọrun wọn kia, ki wọn si ju awọn naa sẹwọn, nitori ọdaran pọnnbele ni wọn. Ṣugbọn awọn kan ni ki i ṣe ẹwọn ni ki wọn sọ wọn si, wọn ni ki wọn pa wọn taara ni, pe bii idigunjale ni iwa awọn naa, nitori ibọn ni wọn gbe lọ sile Fẹla ti wọn fi tipa ba awọn ọmọbinrin rẹ sun, ti wọn si ji wọn ni nnkan ko lọ.

Ijọba Ọbasanjọ ko tete mọ ohun ti wọn yoo ṣe si ọrọ naa rara, iyẹn ni wọn ṣe ni ki igbimọ ti awọn gbe dide tete bẹrẹ iṣẹ, ki wọn maa ba iṣẹ iwadii wọn lọ, ki awọn fi le ronu lori ọna ti wọn yoo gbe ọrọ naa gba, nitori kinni naa ti fẹẹ fẹju ju bi awọn paapaa ti ro o si lọ. Ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje oṣu kẹta, 1977, igbimọ tijọba gbe dide lati wadii ohun to ṣẹlẹ tawọn ṣọja fi dana sun ile Fẹla ti wọn si ba dukia rẹ jẹ bẹrẹ ijokoo wọn. National Theatre ni wọn fi ijokoo naa si, nibẹ ni wọn ti ni ki gbogbo ẹni to ba mọ kinni kan nipa bi ọrọ naa ti ṣe ṣẹlẹ, ati ohun to fa idi ija ọhun gan-an, waa ba awọn, ko si ṣalaye ohun to mọ. Wọn ni awọn ko wa lati da ẹnikẹni lẹjọ, ki i ṣe tawọn lati sọ pe ẹnikan lo jẹbi tabi ẹnikan lo jare, ohun ti ijọba ni ki awọn waa ṣe ni lati wadii bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ, ki awọn ri i pe ko si kinni kan tawọn ko mọ nipa iṣẹlẹ naa, ki awọn si gbe abajade iwadii awọn siwaju ijọba, ko ju bẹẹ lọ.

Ṣebi awọn meji pere ni wọn kuku tiẹ wa ninu igbimọ naa, ki i ṣe igbimọ elero rẹpẹtẹ, nitori bẹẹ, iwọnba lawọn naa le da aṣa oriṣiiriṣii mọ, ko sawọn ti yoo ba wọn ṣiṣẹ bi wahala ba ti pọ ju. Adajọ Kalu Anya ni olori igbimọ, ẹni keji rẹ to jẹ akọwe, to si tun jẹ oludamọran ati alafọrọlọ ni Wing Commander Hamza Abdullahi, ọmọ ogun ofurufu loun. Awọn mejeeji yii naa ni wọn jọ jokoo pirimu lọjọ ti igbimọ naa bẹrẹ ipade, ohun ti Adajọ Anya si kọkọ sọ ni pe awọn o ni i gba awọn lọọya laaye lati waa maa fi ọrọ awijare ati ariyanjiyan da awọn duro, nitori iṣẹ igbimọ naa ki i ṣe iṣẹ ẹjọ-jijẹ, iwadii alaye lasan ni. O ni bo ba jẹ awọn fẹẹ lo abajade iwadii naa fun keesi ni, iyẹn ni awọn le sọ pe ki awọn lọọya maa bọ, ki awọn naa waa da si i, ṣugbọn awọn ko fi kinni naa ṣẹjọ, awọn kan fẹẹ fi wadii ohun to ṣẹlẹ gan-an ni.

Nibẹ ni ija si ti kọkọ bẹrẹ o. Lọọya awọn Fẹla, Tunji Braithwaite, ni iru ọrọ wo ni Adajọ Anya to mọ nipa ofin ati iwadii daadaa n sọ lẹnu yii, o lo ya oun lẹnu pe odidi adajọ ile-ẹjọ giga ni yoo maa sọ iru ọrọ bẹẹ jade. O ni igbimọ to sọ pe ki i ṣe ti onidaajọ yii, to ni awọn ko ba ti ẹjọ-gbigbọ wa, abajade iwadii ti igbimọ naa ba ṣe ni ijọba yoo gun le lati fi gbe igbesẹ yoowu ti wọn ba fẹẹ gbe lori ọrọ yii, bawo waa ni iru igbimọ bẹẹ yoo ṣe ni oun ko fẹ awọn agbẹjọro, ṣe tẹnikan ba wa sibẹ to ba waa purọ, ki i ṣe awọn lọọya ni yoo fi ọrọ wa a lẹnuwo nibẹ lati mọ idi okodoro ni. Braithwaite ni oun ni lọọya awọn Fẹla, ọrọ banta-banta bẹẹ yẹn ko si le maa lọ ki oun loun o ni i da si i, tabi ki igbimọ to n wadii ni ọrọ naa ko kan oun. O ni oun ti wa siwaju igbimọ naa, oun si ti wa, ki wọn niṣo nilẹ ki wọn maa ba ẹjọ wọn lọ.

Bayii ni igbimọ naa bẹrẹ ẹjọ wọn, Anya si tun wo gbogbo awọn ti wọn jokoo nibẹ, lo ba tun fa ikilọ mi-in yọ. O ni awọn oniroyin loun fẹẹ kilọ fun, gbogbo wọn pata. O ni bi wọn ti n wo oun yẹn o, ko si ohun ti oun koriira ju laye oun ju keeyan purọ mọ oun lọ. O ni oun koriira awọn oniroyin ti wọn maa n gbe ahesọ kiri o, tabi ti wọn yoo maa kọ ohun ti oun ko sọ sinu awọn iwe iroyin wọn. O loun o fẹ ki wọn sọ pe adajọ kan lo n kanra mọ awọn, iyẹn loun ṣe tete n fohun silẹ bayii o, pe ki gbogbo oniroyin to wa siwaju igbimọ naa, ti wọn si mọ pe awọn yoo ba awọn ṣiṣẹ titi tawọn yoo fi yanju ẹ fi eti ara wọn gbọ, ki wọn ma kọ ohun ti oun ko ba sọ jade o. Adajọ naa ni bi oun ba sọrọ kan ti ko ba ye wọn, ki wọn tete beere lọwọ oun, oun yoo tun ṣalaye fun wọn. Ṣugbọn ti wọn ba kọ ohun toun o sọ, ija niyẹn o.

Bẹẹ ni igbimọ naa bẹrẹ ẹjọ wọn. Awọn ẹlẹrii ti wa, awọn ti ọrọ kan naa ko si gbẹyin. Wọn ko ri awọn ṣọja ti wọn yoo jẹrii tabi ti wọn yoo ṣalaye bi ọrọ ti jẹ, tabi ohun to fa ija, awọn ọlọpaa ni wọn ri nibẹ, bẹẹ ki i ṣe ọlọpaa lo dana sun ile. Ṣugbọn ni ti awọn Fẹla, awọn ẹlẹrii oriṣiiriṣii lo wa nibẹ, koda, bi ara Bẹẹkọ ti i ṣe aburo Fẹla ko ti ya to, wọn gbe e sori kẹkẹ debẹ ni, nigba ti wọn si ti i wọle siwaju igbimọ naa, awọn eeyan kun lọ hun-un, wọn ni awọn ṣọja yii ki i ṣeeyan, ẹranko lo pọ ninu wọn. Lẹyin ti wọn ti kun tan, ti wọn fẹẹ bẹrẹ ẹjọ ni Braithwaite fo dide, o si sọ fun Adajọ Anya ati ẹni keji rẹ pe lara ohun ti oun n wi gan-an lo ṣẹlẹ yii o. O ni ko si bi ọrọ ti le lọ to, eeyan ki i fari lẹyin olori, bi igbimọ yii yoo ba gbọ ẹjọ, ti wọn yoo si wadii ọrọ bi wọn ti ni awọn fẹẹ wadii yii, afi ki Fẹla wa nikalẹ, nigba to jẹ ori ẹ lọrọ ti ṣẹlẹ.

Braithwaite ni bi awọn ti n sọrọ yii, Fẹla wa ninu ọgba ẹwọn, oun ko si waa mọ bi igbimọ naa yoo ti maa ba iwadii wọn lọ ti ko ni i daru bo ba debi kan. Eleyii bi ẹni keji Anya ninu, iyẹn Hamza Abdullahi, ṣe ologun loun, oun ko si raaye ẹjọ wẹwẹ. O ni ki Braithwaite sinmi o jare, ko si ohun to kan awọn ninu ẹni to wa siwaju igbimọ ati ẹni ti ko wa, iṣẹ tawọn lawọn jokoo ti awọn n ṣe. O ni ẹni to ba mọ pe oun ni ọrọ i sọ, to mọ pe ọrọ naa kan oun, oun funra rẹ ni yoo mọ bi yoo ti wa siwaju igbimọ, ki i ṣe iṣẹ tawọn lati maa wa ẹlẹrii kan kaakiri. Hamza ni bi ọrọ ba kan Fẹla, yoo mọ bi yoo ti jade ni, bi ko ba ti wa siwaju igbimọ awọn, a jẹ pe awọn ko gba pe ọrọ naa kan an niyẹn, bo ba kan an, yoo jade wa. Hamza ko ṣalaye bi Fẹla yoo ti jade wa siwaju igbimọ, bẹẹ o mọ pe o wa ninu ahamọ.

Awọn eeyan paapaa kun hun-un, bi wọn si ti kun yii jẹ ki Hamza funra rẹ mọ pe oju onisọkusọ ni wọn fi n wo oun, pe awọn eeyan ti wọn wa nibẹ ko fẹran ọrọ ti oun sọ. Adajọ Anya lo gba a silẹ. O ni o daa bi Fẹla ba le wa, nitori bi lọọya rẹ ti wi yii, ori ẹ lọrọ gbogbo da le. Ṣugbọn o ni ko si agbara lọwọ awọn lati gba a jade nibi to wa, koda, awọn ko le paṣẹ kan fun ijọba, awọn ko si le fun wọn nimọran lori ẹ, nitori ki i ṣe iṣẹ ti wọn gbe le awọn lọwọ niyẹn, ati pe igbimọ awọn ki i ṣe ile-ẹjọ, ile-ẹjọ nikan lo si le gba beeli eeyan lọdọ ọlọpaa, ki i ṣe awọn. Braithwaite ni oun mọ pe iṣẹ igbimọ naa ko debẹ loootọ, ṣugbọn ohun ti oun n sọ ni pe nigba to jẹ ijọba lo ti Fẹla mọle ki i ṣe ọlọpaa, ijọba lo si gbe igbimọ yii naa dide, o yẹ ki wọn jọ mọ bi wọn yoo ti sọ kinni naa laarin ara wọn, ti wọn yoo jẹ ki Fẹla jade ko le waa fẹnu ara rẹ sọ bi ọrọ ti jẹ.

Nibi ti wọn ti n sọrọ yii lọwọ lawọn ọlọpaa meji kan ti wọle wẹrẹ: ẹni to pe wọn ati bi tiwọn ti jẹ, ẹnikan ko mọ. Ṣugbọn igba ti wọn wọle, ọdọ Braithwaite ni wọn lọ taara, wọn ni awọn ni iroyin ayọ kan fun un. Niyẹn naa ba tẹti bẹlẹjẹ, o fẹẹ gbọ iroyin ayọ ti wọn mu wa. Awọn ni wọn sọ fun un pe ofin kan-n-pa ti ijọba ologun apapọ fi mu Fẹla, wọn ti gbẹsẹ kuro lori ẹ bayii o, iyẹn ni pe ko si ofin ologun to de ọkunrin olorin naa mọ, bi lọọya rẹ ba fẹ, o le lọọ ṣeto beeli rẹ nibi to ti n ṣe e lọ tẹlẹ, o si ṣee ṣe ki wọn fi i silẹ, nitori ofin ologun kan ko da a duro mọ, bi adajọ ba si ti sọ pe ọrọ rẹ la beeli lọ, bo ba fun un, ko si ẹni ti yoo mu un mọ, awọn ọlọpaa ko si ni i gbe e lojiji bi wọn ti ji i gbe lọjọsi. Ọrọ naa ko ye Braithwaite, o si beere pe ṣe awọn ọga wọn lo ran wọn soun ni abi wọn n ṣe tara wọn ni, awọn yẹn ni awọn kan waa sọ fun un bii ọrẹ ni o.

Ṣugbọn ọrọ naa ju bẹẹ lọ, nitori bi awọn ti n sọ fun un yii, bẹẹ ni oniṣẹ mi-in de pe awọn ọlọpaa ma ti tun n gbe Fẹla lọ sile-ẹjọ ti majisireeti ti wọn ti ni wọn ko ni i gba beeli ẹ lọjọsi o, ko si tun mọ iru ẹjọ ti wọn fẹẹ pe e lọtẹ yii, tabi ohun ti wọn n tori ẹ gbe e lọ. Awọn ti wọn sọrọ naa fun Braithwaite ni bi ko ba fẹ ki nnkan mi-in ṣẹlẹ, ko ma jẹ wọn yoo ko bọwọbọwọ tabi ẹsun apaayan bọ Fẹla lọwọ, ko tete yaa maa sare lọọ pade rẹ nibi ti wọn n gbe e lọ. Ni Braithwaite ba tun ki ere mọlẹ, ọrọ tun di girigiri, lo ba di Saint Ann’s Migistrate Court, niwaju Adajọ Victor Famakinwa. Amọ ki i ṣe adajọ yii nikan lo ri nibẹ, o tun ba ọrẹ rẹ ti wọn jọ maa n fa ọrọ mọ ara wọn lẹnu, iyẹn agbẹjọro ijọba, Egegele. Ọwọ ọtun ọkunrin naa ti yoo si tun wo bayii, o ri Fẹla nibẹ ti iyẹn n sa a, “Tunji Tunji”, wọn ti gbe e debẹ ki oun too de.

Braithwaite kọju si Egegele pe ṣe ko si nnkan ti wọn tun gbe Fẹla wa si kootu lojiji, amọ ki ọkunrin naa too dahun, Adajọ Famakinwa pe awọn mejeeji pe ki wọn ma wulẹ fi akoko ṣofo, ṣe ko si nnkan ti oun tun ri wọn lojiji, ki lo tun de o! Nibẹ ni Egegele ti ṣalaye, o ni jẹẹjẹ loun jokoo ti ọga wọn pata ni ipinlẹ Eko, iyẹn kọmiṣanna awọn ọlọpaa, ranṣẹ pe oun pe ki oun sare gbe Fẹla lọ si kootu, ki awọn lọọ sọrọ beeli ẹ ti awọn ti pa ti lati ọjọ yii wa, nitori ijọba apapọ ti ni awọn ko fofin lile ti wọn fi de e tẹlẹ de e mọ. O ni ọrọ beeli naa loun tori ẹ wa o, bi wọn ba fẹẹ fun Fẹla ni beeli, ki wọn fun un, awọn ọlọpaa ko ni i da a duro mọ, nitori ko si ọrọ rẹ kan lọdọ awọn, bo ba fẹẹ lọ sile, o le maa lọ, ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko lo ni ki oun sọ bẹẹ. Bi ọrọ naa iba si ti da bii nnkan idunnu to, ibinu ni Tunji Braithwaite fi fo dide. O ni, “Agbẹdọ!”

 

Njẹ ki lo tun de? Braithwaite ni oun to fẹẹ ṣẹlẹ yii ko ṣẹlẹ ri ninu iwe ofin ilẹ Naijiria, nnkan ti ko si dara gbaa ni. O ni ọrọ beeli Fẹla ti kuro niwaju Adajọ Famakinwa, nitori nigba ti oun ti beere lọwọ rẹ pe ko fun Fẹla ni beeli, to si ti ni oun ko le fun un loun ti gbe ẹjọ naa lọ si ile-ẹjọ giga l’Ekoo, ile-ẹjọ giga naa lo si lẹtọọ lati gbọ ẹjọ yii, ki wọn si ṣalaye boya adajọ majisireeti naa huwa to tọ abi iwa rẹ ko dara labẹ ofin. O ni bi awọn ọlọpaa ba waa ni ẹjọ kan, tabi ti wọn ba ni ọrọ mi-in, iwaju ile-ẹjọ giga yii lo yẹ ki wọn lọ, ki i ṣe ki wọn tun sare jabajaba wa sọdọ adajọ majisireeti ti wọn ti ni ko le gba beeli ẹni ti wọn mu wa, tadajọ naa si ti gbọrọ si wọn lẹnu. Braithwaite ni awọn ko tọrọ beeli lọwọ Famakinwa mọ, ko maa gbe beeli rẹ lọ, ile-ẹjọ giga ti awọn ti lọ ni yoo yanju ọrọ bo ba jẹ oun lo jare, bo si jẹ awọn ni.

Bi wọn ti bẹrẹ si i fa ọrọ yii lọ fa a bọ niyi, Braithwaite si ti ba Fẹla sọrọ pe awọn ko ni i gba beeli naa, nitori o ni ohun ti oun fẹẹ fa jade nibi ọrọ naa nigba ti adajọ ile-ẹjọ giga ba da Famakinwa lẹbi, to si da awọn lare. O ni yatọ si ọwọ tawọn le fi ọrọ naa gba lọjọ iwaju, yoo tun ran ẹjọ ti wọn n pe ijọba apapọ lọwọ ni, awọn yoo si le ri owo gọbọi ti awọn fẹẹ gba lọwọ wọn gba. Ni Fẹla ba taku pe ki wọn ma fun oun ni beeli, ọrọ ti lọọya oun sọ loun yoo tẹle, ko si ohun ti atimọle wọn fi ṣe oun, ki wọn fi oun sibẹ ki oun maa jẹun si wọn lọrun, ṣebi ohun ti wọn fẹ tẹlẹ naa sa niyẹn. Ọrọ naa ko fi ọkan Adajọ Famakinwa balẹ, bẹẹ ni Egegele naa n kuru, to n ga, o ni oun ko ko iru eleyii ri lati ọjọ ti oun ti n ṣe keesi, ki wọn sọ pe ki ọdaran gba beeli ko ni oun ko gba, awọn eeyan naa kan fẹẹ koba oun ati awọn ọlọpaa lọdọ ijọba apapọ ni.

Ẹ wo o, nigba ti Adajọ Famakinwa ati Egegele ro gbogbo rẹ paapaapaa, n ladajọ ba dajọ. O ni pẹlu ọrọ to wa niwaju oun, ati pe lọọya Fẹla ti wa siwaju oun tẹlẹ lati waa beere beeli, to si jẹ awọn ọlọpaa lo da oun duro nigba naa, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa ti ni awọn ko da oun duro mọ yii, oun gba beeli ọkunrin naa, oun gba beeli rẹ ni igba Naira, koda, oun ko beere oniduuro, orukọ rẹ funra rẹ, Fẹla, loun fi fun un ni beeli yii, nitori ẹni ti gbogbo ilu mọ ni. Bẹẹ ni adajọ fun Fẹla ni beeli nigba to loun ko fẹ mọ, ti wọn ni ko maa lọ sile rẹ to loun ko lọ.

Bẹẹ bi wọn ti n gbọ ẹjọ iyẹn lọwọ, ẹjọ mi-in wa ti wọn tun n gbọ lọwọ ni ile-ẹjọ giga l’Ekoo, awọn Fẹla naa lo pe iyẹn naa, ohun ti wọn si tori ẹ pe ẹjọ ni pe nnkan kan ko gbọdọ ṣe Fẹla ni atimọle to wa, ati pe ki ijọba kọkọ sare san awọn owo itanran kan ki Fẹla fi tọju ara rẹ nitori awọn iya tawọn ṣọja ijọba fi jẹ ẹ. Wọn n gbọ ẹjọ iyẹn lọwọ ni deede akoko kan naa ti wọn n fa wahala ọrọ beeli niwaju Famakinwa. Lọọya kan, Kanmi Iṣọla Osobu, lo n ro ẹjọ iyẹn niwaju adajọ, oun naa si ya ipata lọọya bayii nigba naa, nitori awọn ti iwa wọn ba ba ti Fẹla mu lo n ba ṣe.

Eyi to waa pa awọn eeyan lẹrin-in ni nigba ti wọn dajọ tan pe wọn gba beeli Fẹla ti Fẹla jokoo sile-ẹjọ nibẹ, ti adajọ dide to wọ Ṣemba ẹ lọ, tawọn ọlọpaa funra wọn si poora mọ Fẹla loju ti ko rẹni kan mọ. Ko ri adajọ, ko ri ọlọpaa, oun ati lọọya ẹ nikan pẹlu awọn ero lo ku, wọn kọ ọ si famili ẹ lọrun, awọn ọlọpaa ni ko si ibi ti awọn fẹẹ gbe e lọ. Ko kuku tiẹ sẹni to ri wọn mọ, wọn ti sa lọ, nigba ti ko si si ohun mi-in ti lọọya ati Fẹla funra ẹ le ṣe mọ, ni wọn ba ti Fẹla wọ mọto, ni Tunji Braithwaite ba gbe e lọ sile.

 

(86)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.