Lọjọ Keresi,eeyan mẹta ku ninu ijamba oju popo nipinlẹ Ogun

Spread the love

Ajọ ijọba apapọ to n ri si irinna ọkọ loju popo, Federal Road Safety Commission,(FRSC), ẹka tipinlẹ Ogun, ti sọ ọ di mimọ pe ijamba ọkọ mẹrin lo ṣẹlẹ kaakiri ipinlẹ Ogun lọjọ ọdun Keresimesi to kọja yii, eeyan mẹta lo si dagbere faye.

Atẹjade ti kọmanda wọn nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Clement Ọladele fọwọ si, ṣalaye pe oju ọna marosẹ Benin si Ọrẹ, lagbegbe J4, ni ijamba akọkọ ti waye. O ni eeyan marun-un lo wa ninu mọto meji ti wahala naa kan, ọkunrin lawọn maraarun, meji ku ninu wọn, awọn mẹta si farapa gidi.

Awọn ọkọ to ni asidẹnti ọhun ni Toyota Sienna ti nọmba ẹ jẹ AAA113XY, ati  ọkọ akero Ford mi-in to ni nọmba XB538 GBD. Ileewosan Roono to wa n’Ijẹbu-Ode ni wọn ko awọn to ṣeṣe lọ, wọn si tọju awọn oku si mọṣuari.

Ijamba ọkọ keji ko mu ẹmi lọ, ṣugbọn ko sẹni to sun ile rẹ lalẹ ọjọ Keresi naa ninu awọn mẹrindinlogun ti wọn ni asidẹnti naa, ijamba to ṣẹlẹ laago mẹwaa alẹ kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn naa lagbara pupọ.

Ọkunrin mẹwaa, obinrin mẹfa, ni wọn ṣeṣe yanna-yanna loju ọna Abẹokuta si Ṣagamu lọjọ naa. Ọkọ meji ti wọn kọlu ara wọn naa ni Toyoya Hiace ti nọmba ẹ jẹ ABG121XA, ati ọkọ akẹru toun ni nọmba LSD 126XR. Ọsibitu Jẹnẹra Abẹokuta ni wọn ru gbogbo wọn lọ.

Ọna marosẹ Eko s’Ibadan ni ijamba kẹta ti ṣẹlẹ, alẹ naa ni gẹgẹ bi AKEDE AGBAYE ṣe gbọ. Aago mọkanla ku iṣẹju marundinlogoji ni mọto VolvoMEK721 XA, ti i ṣe tirela, ko si idaamu laarin ọna, awakọ rẹ si farapa gidi.

Ọsibitu Supreme Global, ni Ṣagamu, loun naa sun mọju.

Ọkada meji lo fa iku ẹni kan ni Owode-Idiroko lọjọ Keresi yii kan naa. Ọkada Bajaj meji ni wọn fori gbari, ti eeyan meji fi farapa pupọ, ti ẹni kẹta si ku loju-ẹsẹ.

Ọsibitu Jẹnẹra Ọta ni wọn gbe awọn to ṣeṣe lọ,wọn gbe oku lọ si mọṣuari.

Gbogbo ijamba yii lo ṣee dena bawọn FRSC ṣe wi, iyẹn to ba ṣe pe awọn awakọ n tẹle ofin irinna bo ṣe yẹ.

Kọmanda Ọladele gba wọn nimọran pe ki wọn maa ranti pe gbogbo ibi ti ọna ti pin si meji loju ọna marosẹ Ibadan ni iṣẹ ṣi n lọ lori wọn, eeyan ko gbọdọ sare kọja ida aadọta nibẹ (50km per hour), bẹẹ ni wọn ko gbọdọ sare ya ọkọ to wa lẹgbẹẹ silẹ, iwa to lodi sofin irinna ni.

Yatọ si eyi, awọn ti wọn n wakọ alẹ naa gbọdọ ri i daju pe wọn n riran daadaa lalẹ ki wọn too gbe mọto sọna, ki wọn ma baa fi ẹmi tiwọn ati tawọn alaiṣẹ ṣofo.

Beeyan ba fẹẹ fi ibudo iṣẹlẹ ijamba ọkọ to ajọ FRSC leti, nọmba 122 ni wọn ni ki tọhun pe. Tabi ki wọn lọ sori ẹka  ayelujara www.frsc.gov.ng, atiwww.facebook.com/frscnigeria.

 

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.