Lọjọ kan ṣoṣo, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin mẹrin kuro ninu ẹgbẹ APC l’Ọṣun

Spread the love

Pẹlu bi idibo gomina ipinlẹ Ọṣun ṣe ku ọjọ mejidinlogun bayii, ẹgbẹ oṣelu APC ti sọ pe ki gbogbo awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ti wọn kuro ninu ẹgbẹ naa lọsẹ to kọja kọwe fi aaye wọn silẹ.

Lati ọsẹ bii mẹta sẹyin ni igbalẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun ti n yọ lẹyọkọọkan, bi awọn agbaagba ṣe n kuro lawọn ọdọ n kuro, bi ọkunrin ṣe n lọ naa lawọn obinrin n lọ, ohun ti wọn si n tẹnumọ ni pe iyanjẹ ti pọ ju ninu ẹgbẹ naa.

Ọrọ yii ko yọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin silẹ rara, Ọnọrebu Clement Akanni Ọlọrunwa to wa latijọba ibilẹ Ila, nibi ti Oloye Bisi Akande ti wa lo kọkọ digba-dagbọn kọja sinu ẹgbẹ oṣelu PDP. Lopin oṣẹ to kọja yii ni awọn mẹrin mi-in tun dana sun igbalẹ, wọn si bọ sinu ẹgbẹ oṣelu miiran.

Ọnọrebu Abdullahi Ibrahim to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Iwo nile igbimọ aṣofin kuro ninu ẹgbẹ APC lọ sinu ẹgbẹ oṣelu ADP, bẹẹ naa ni Ọnọrebu Kamardeen Debọ Akanbi to wa latijọba ibilẹ Ẹdẹ ati Ọnọrebu Tajudeen Famuyide latijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ileṣa.

Ko tan sibẹ, aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Odo-Ọtin nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Ọnọrebu Ọlaolu Oyeniran, naa sọ pe oun ko tẹle Arẹgbẹṣọla mọ, o ni ẹgbẹ ti Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla lọ loun naa yoo lọ, iyẹn ẹgbẹ oṣelu ADC.

Ni bayii, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun ti ku mọkandinlogun dipo mẹrinlelogun ti wọn jẹ tẹlẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP ni mẹta, ẹgbẹ ADP ni mẹta, nigba ti ẹgbẹ ADC ni ẹyọ kan.

Nigba ti awọn mẹta ti wọn darapọ mọ ẹgbẹ ADP n sọrọ, wọn ni ẹgbẹ to lafojudi, ti ki i gba imọran, to si fẹran iyanjẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC, awọn si ti ṣetan bayii lati ri i pe ẹgbẹ naa kuro nijọba nipinlẹ Ọṣun lasiko idibo gomina to n bọ lọna yii.

Ninu ọrọ tirẹ, Ọnọrebu Akanbi ni oun wa lara awọn ti wọn mu ẹgbẹ oṣelu APC wọ ilu Ẹdẹ, oun si tun ti ṣetan bayii lati ja irawọ ẹgbẹ naa pẹlu gbogbo awọn eeyan oun nibẹ nitori Alhaji Adeoti to jẹ oludije labẹ egbẹ oṣelu ADP lawọn yoo ṣiṣẹ fun.

Adehun ti Arẹgbẹṣọla ṣe fun awọn ni pe oun yoo lo ọdun mẹjọ, lẹyin rẹ, oun yoo gbejọba fun ọmọ ẹgbẹ APC to wa nipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe ara Eko mi-in bii tiẹ lo tun pinnu lati gbejọba fun, lai ka ariwo ti gbogbo awọn ti n pa lati ọjọ yii pe ẹkun Iwọ-Oorun Ọṣun lo tọ lati dupo gomina.

Ni tiẹ, Ọnọrebu Famuyide ni ẹgbẹ kan ṣoṣo to wa fun awọn araalu nipinlẹ Ọṣun ni ẹgbẹ ADP, o rọ wọn lati ṣamulo kaadi idibo wọn daadaa, ki wọn si fi ibo wọn le awọn ‘ajẹlẹ’ kuro nipinlẹ Ọṣun lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Ọjọgbọn Adeolu Durotoye to jẹ igbakeji oludije fun ipo gomina gboṣuba fun awọn aṣofin ọhun fun igbesẹ akin ti wọn gbe lati kọ iyanjẹ, o ni ẹgbẹ ADP nikan lo duro fun ireti ati ọjọ ọla to logo nipinlẹ Ọṣun, nitori pe gbogbo ibi ti bata ti n ta awọn araalu lẹsẹ lawọn ti mọ, eto si ti wa loniruuru ọna lati dẹrin pẹẹkẹ wọn.

Bakan naa ni ọkan lara awọn asiwaju ẹgbẹ naa, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi, ṣalaye pe itara ti awọn fi ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu APC naa lawọn yoo lo lati fi da ẹgbẹ naa pada sibi to ti wa, ti ẹgbẹ ADP yoo si di apewaawo nipinlẹ Ọṣun.

Igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu ADP nipinlẹ Ọṣun, Alhaji Issa Adeṣiji, ki awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun naa kaabọ sinu ẹgbẹ onitẹsiwaju tootọ, o ni awọn ti wọn ko ṣiṣẹ kankan ni wọn n jere ẹgbẹ oṣelu APC bayii, idi si niyẹn ti ẹgbẹ naa fi n yọ lẹyọkọọkan bii igbalẹ.

Issa ni, “Oyin ati iyọ ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun, asia ẹgbẹ naa ti faya, ni bayii, ẹgbẹ ADP ti ṣetan lati gbajọba. Mo fẹẹ rọ gbogbo awọn oludibo lati ṣatilẹyin fun Alhaji Moshood Adeoti, ẹ dibo fun wa, ẹ ko si ni kabaamọ.”

Ṣugbọn kia ni agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Barista Kunle Ọyatomi, sọ pe yoo jẹ nnkan ti yoo dun mọ ẹgbẹ naa ninu ti awọn aṣofin ti wọn kuro naa ba rọra kọwe fipo wọn silẹ. O ni ko si ẹni to di wọn lọwọ lati lọ sinu ẹgbẹ to ba wu wọn, ṣugbọn ko ni i bojumu ki wọn si jokoo sile igbimọ aṣofin to jẹ pe labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn fi yan wọn sibẹ.

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.