Loṣu kẹrin, 1964, ija awọn Yoruba ati Ibo inu ẹgbẹ NCNC le si i, TOS Benson lawọn Ibo fẹẹ pa oun

Spread the love

Ni Ọjọruu, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹrin, ọdun 1964, odidi iṣẹju mẹwaa lawọn aṣofin fi le ara wọn jade sita gbangba, ti wọn ko jokoo sọrọ kan, to jẹ ẹjọ ni wọn n ro laarin ara wọn ni gbangba ode. Ohun to si fa a ni pe ọrọ ti fẹẹ dija ninu ile lọhun-un ni, ki ọrọ ma si di ija, ko ma di ohun ti awọn aṣofin n sọ ṣia funra wọn, tabi ti wọn n yọwọ ẹṣẹ, iyẹn ni ẹni to n dele fun alaga ile igbimọ naa, Ọgbẹni Emmanuel Akwiwu, ṣe paṣẹ ki kaluku bọ sita na, ki wọn lọọ sinmi, lẹyin iṣẹju mẹwaa ni ki wọn too pada wọle. Ayọ Rosiji, aṣaaju ẹgbẹ Dẹmọ, NNDP, lo n sọrọ nile-igbimọ aṣofin naa, nibẹ ni ariwo ti bẹrẹ lọtun-un losi, bawọn kan ti n pariwo ‘Noo Noo Noo’, bẹẹ lawọn mi-in n fọwọ gba tabili ‘gbaa gbaa gbaa’, ti awọn mi-in si n yaka sira wọn lọọọkan nitori ọrọ to n tẹnu wọn jade, ki ọrọ naa ma si le ju bẹẹ lọ ni adele alaga ṣe le wọn sita.

Ohun to fa wahala ko ju ọrọ ija laarin awọn ọmọ Ibo ati awọn ọmọ Yoruba to ti bẹrẹ lati bii ọjọ meloo kan sẹyin lọ. Ija buruku to n ṣẹlẹ nitori ọrọ ileeṣẹ reluwee, ati awọn ileeṣẹ mi-in, ti awọn ọmọ Ibo ṣe olori, ti wọn wa n le awọn ọmọ Yoruba ti wọn ti jẹ ọga danu, tabi ti wọn n yọ wọn kuro nipo wọn, ti wọn n fi awọn ọmọ Ibo si i. Ẹni ti ọrọ naa si da le lori ju lọ ni Ọmọwe Okechukwu Ikejiani, ẹni ti wọn lo ti fi aburo tirẹ kan, Ikejiani, ṣe bii igbakeji rẹ, to jẹ nileeṣẹ reluwee yii nikan, awọn Ikejiani ti wọn jẹ ọga n lọ bii mẹta mẹrin. Wọn si royin pe ọkunrin naa ko bikita fẹnikan, ko ti i pẹ rara to paṣẹ ki wọn yọ Ọgbẹni Modupẹ Alade kuro nipo rẹ, manija kan ni Alade, ọga si ni. Ohun ti wọn si tori ẹ le e naa ko ju pe wọn ni o n lọọ ṣofofo awọn ohun to n lọ fun awọn Yoruba, paapaa ijọba Western Region.

Nitori ọrọ Alade yii ni wọn ṣe ranṣẹ pe Minisita Raymond Njoku, wọn ni ko waa sọ ti ẹnu rẹ. Idi ti wọn ṣe pe Njoku ni pe oun ni ọga fun Ikejiani ti i ṣe alaga ileeṣẹ reluwee, bo sa ṣe le wu ki imu alagbaro gun to, ẹni to ba gbe oko fun un ro naa ni ọga rẹ. Awọn aṣofin mọ pe ti awọn ba ti le ri Njoku, ti awọn fi ẹjọ ọmọọṣẹ rẹ sun un, yoo mọ ohun ti yoo ṣe si ọrọ rẹ, bi ko ba si waa ṣe nnkan kan si i, awọn funra wọn yoo mọ bi awọn yoo ṣe dajọ to ba yẹ. Ohun ti awọn kan ṣe n ro pe Njoku le ma da si ọrọ naa bo ṣe yẹ ni pe Ibo ni Njoku, Ibo ni Ikejiani, awọn Ibo ki si i deede tako ara wọn, wọn yoo maa gbe lẹyin ara wọn ni. Asiko ti wọn n mura lati ranṣẹ pe Njoku yii ni oun naa n mura lati waa ri wọn, o fẹẹ sọrọ lori bọjẹẹti, iyẹn owo ti ileeṣẹ rẹ yoo na fun ọdun naa, o fẹẹ waa ṣalaye bi wọn ti ṣe fẹẹ na an, ati iye ti wọn fẹ gan-an.

Ṣe bi ko ba waa ṣalaye bẹẹ ki awọn aṣofin yii fi ọwọ si i, ko si bi owo naa ṣe le to o lọwọ, ko si si bi o ṣe le ri owo na nileeṣẹ rẹ. Eyi ja si pe bi awọn aṣofin ti nilo Njoku lasiko naa, bẹẹ naa loun naa nilo wọn. Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹrin yii waa ni minisita naa wa, to ni ileeṣẹ oun fẹẹ na owo to le diẹ ni miliọnu kan owo Pọn-un, pe ki awọn aṣofin ba awọn fọwọ si i. Bi Akwiwu ti i ṣe adele alaga ile-igbimọ naa ti ṣi ijokoo, to si ṣalaye pe Raymond Njoku ree o, o waa beere aṣẹ lati na owo bayii fun idagbasoke ileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ, ninu eyi ti reluwee, ọkọ oju omi, ti ofurufu ati bẹẹ bẹẹ wa, ki awọn aṣofin yẹ iwe to wa lọwọ wọn wo, ki wọn si beere ohun ti wọn fẹẹ beere lọwọ rẹ, bẹẹ ni Ayọ Rosiji dide, o ni ọrọ to wa nilẹ ko tilẹ ti i kan ti owo nina rara, ohun to wa nilẹ ju ti bọjẹẹti lọ.

Bo ti sọ bẹẹ lawọn aṣofin ti wọn jẹ ọmọ Ẹgbẹ NNDP, ẹgbẹ Dẹmọ pariwo pe, “Bẹẹ ni o!” Sugbọn kia lawọn aṣofin NCNC naa bẹrẹ si i pariwo lọdọ tiwọn lọhun-un, wọn ni kin ni wahala to ba Rosiji, ọrọ bọjẹẹti lawọn ba wa, ọrọ bọjẹẹti naa si ni ki awọn sọ ki awọn maa lọ. Ṣugbọn alaga ile-igbimọ naa ni ki wọn jẹ ki Rosiji sọ ti ẹnu rẹ, eeyan ki i pa ohun mọ agogo lẹnu. Ati pe niṣe ni a aa jẹ ki ẹlẹẹẹdẹ pe ẹẹdẹ, bi ẹlẹẹẹdẹ ba ni ẹẹdẹ, eeyan ki i sare ba a pari rẹ pe ẹẹdẹgbẹjọ, abi bo ba jẹ ẹẹdẹgbẹrin lo fẹẹ wi nkọ! Nibẹ ni ara ti rọ awọn aṣofin ọmọ NCNC ti wọn ti fẹẹ maa bẹwu silẹ gbe apẹrẹ wọ, wọn ṣe mẹdọ diẹ, wọn n reti ohun ti Rosiji fẹẹ sọ. Awọn ọmọ NNDP naa gbe jẹẹ fungba diẹ, awọn naa ko kuku ti i mọ ibi ti ọrọ yoo tilẹ fori ti si, wọn kan n pariwo nitori pe ọmọ ẹgbẹ wọn lo fẹẹ sọrọ ni.

N ni Rosiji ba bẹrẹ ọrọ. O ni oun sọ pe ki awọn ma ti i sọrọ bọjẹẹti nitori ohun to n lọ lawọn ileeṣẹ ijọba apapọ kan, nitori awọn iwa ẹlẹyamẹya to n lọ, paapaa ni awọn ileeṣẹ to wa labẹ Njoku gẹgẹ bii minisita. O ni Njoku gbọdọ ṣe alaye fawọn idi ti iwa ẹlẹyamẹya fi gbilẹ nileeṣẹ reluwee to bẹẹ, paripari rẹ ni idi ti wọn fi n le awọn Yoruba, eyi to si jẹ koko ju ni ti Modupẹ Alade ti wọn ṣẹṣẹ le nibẹ. Ko sọ ju bẹẹ lọ, nigba naa lọrọ yii di ariwo gidi, ti awọn ọmọ NCNC yari, wọn ni ki lo de ti Rosiji yoo beere iru ọrọ bẹẹ yẹn lọwọ ẹni to waa ṣalaye bọjẹẹti ti ileeṣẹ rẹ fẹẹ na, ewo la gbe, ewo lọkunrin yii ju, ko sẹni kan ti yoo da a lohun ibeere bẹẹ, awọn ko tilẹ ni i gba ni tawọn. Bawọn ti n pariwo lawọn ọmọ ẹgbẹ NNDP naa ni ko sọna fọlọtẹ, afi ko sọda ni, awọn ko le jokoo kawọn NCNC maa halẹ mọ eeyan awọn.

Ni adele alaga ba pariwo “ọọda!” o si lu hama onigi rẹ mọ ori tabili, n lawọn eeyan ba tun dakẹ diẹ, bẹẹ lọkunrin naa sọrọ, “Họnọrebu Rosiji, ẹ maa ba ọrọ yin lọ!” Rosiji ni iwa ẹlẹyamẹya to n lọ ni ileeṣẹ reluwee buru pupọ, eyi to si ya oun lẹnu ni pe ọkunrin to n ṣe alaga ibẹ, Ikejiani, sọ fun oun funra oun ti oun n sọrọ yii pe ko si ohun ti ẹnikẹni le fi oun ṣe, koda minisita paapaa ko le yẹ oun lọwọ wo. O ni nigba to n ba oun sọrọ, o halẹ pe ki oun Rosiji wo oun daadaa o, ẹnikẹni to ba ṣeeṣi na ika kan soun, ki i ṣe pe oun yoo ge ika naa jẹ nikan kọ o, oun yoo kan tọhun lọrun ni. Ọrun rẹ yoo kan, ibi ti ọrọ rẹ ba si ja si lo ja si yẹn. Rosiji sọ fun wọn ni ile-igbimọ lọjọ naa pe ọkunrin Ikejiani ti wọn fi ṣe alaga ileeṣẹ reluwee yii ko ri ara rẹ bii oṣiṣẹ rara, afi bii Ọlọrun lo ṣe n wo ara rẹ.

Rosiji ni bawo leeyan yoo ṣe maa ṣiṣẹ nibi kan ti yoo tori ti oun jẹ alaga, ti yoo si sọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ kan loun yoo fiya jẹ nitori wọn jẹ ẹya kan, tabi pe wọn wa lati apa ibi kan ni orilẹ-ede yii. O ni ohun ti Ikejiani n sọ fawọn eeyan niyẹn, pe wiwa ti oun wa si ileeṣẹ reluwee yii, lati waa fiya jẹ awọn Yoruba ni, ati lati waa gba awọn ipo ti wọn ti wa kuro lọwọ wọn, nitori pupọ ninu awọn ipo naa, ọmọ Ibo lo tọ si. Rosiji ni nigba ti ọkunrin naa n ba oun sọrọ, ko sọ iyẹn loju oun o, nitori bo ba sọ bẹẹ, oun iba ti fi nọmba jo o, oun iba si ti ṣalaye fun un pe ileeṣẹ reluwee ki i ṣe ti baba ẹni kan tabi ti ẹya kan, gbogbo Naijiria lo ni in. O ni Njoku lo wa nibẹ yẹn

oun lọga rẹ, Ikejiani si ti ni apa ọga oun ko ka oun, bawo lawọn aa ṣe waa fun Njoku lowo! Rosiji ni ki Njoku kọkọ lọọ yanju ọrọ reluwee ko too pada waa ba awọn.

Nibi ni ọrọ ti di ariwo rẹpẹtẹ, to si di pe awọn aṣofin ko gbọ ara wọn ye mọ rara, nitori awọn ọmọ NCNC n sọ pe kantankantan ni Rosiji n sọ lẹnu yẹn, ọrọ ti ko tilẹ mu sẹnsi dani ni. Awọn NCNC yii ni kin ni Rosiji n gbe to n gbin, wọn ni nibo lo wa nigba ti awọn ọmọ Ẹgbẹ Dẹmọ rẹ n yọ wọn lẹnu ni Ileṣa, ti wọn ti ileewe Ileṣa pa, ṣebi Yoruba ni gbogbo awọn to wa nibẹ, abi o fẹẹ sọ pe oun ko mọ pe awọn Akintọla n ṣe ohun ti ko dara si awọn ara Ileṣa ni, ki lo waa de ti ko gbe iru ọrọ bẹẹ wa siwaju ile-igbimọ, ṣe eyi ti oun ṣe yẹn ki i ṣe iwa ẹlẹyamẹya ni. Awọn ọmọ Dẹmọ naa yara, wọn ni ọrọ to wa nilẹ yii ko kan ọrọ Ileṣa, gbogbo ọmọ Yoruba lo wa lẹyin awọn lori ohun ti awọn n sọ, ohun ti awọn si n sọ naa ni pe ki awọn Ibo sinmi ẹlẹyamẹya, nitori Naijiria yii ti gbogbo wa ni.

Nibi ti wọn sọrọ de niyẹn ti adele alaga fi le wọn sita. Ṣugbọn nigba ti wọn de ita naa, ọrọ naa ko yipada, iyatọ to kan wa nibẹ ko ju pe awọn ẹgbẹ NCNC duro sọtọ, wọn n sọ tiwọn, awọn Dẹmọ naa si duro sọtọ, wọn n sọ tiwọn. Awọn ẹgbẹ oṣelu to ku naa duro, wọn n ba wọn yẹ ọrọ naa wo sọtun-un sosi, awọn ọmọ ẹgbẹ NPC, iyẹn ẹgbẹ awọn Hausa kan n fi wọn rerin-in ni tiwọn ni. Ohun to wa lọkan awọn yẹn ni pe gambari pa Fulani ko lẹjọ ninu, bi awọn Yoruba ati Ibo to n yọ awọn ti awọn jẹ Hausa lẹnu lati ọjọ yii ba bẹrẹ ija bayii laarin ara wọn, ko si idi ti awọn fi gbọdọ ba wọn da si i, bo wu wọn ki wọn kan ara wọn loogun, bo ba si jẹ wọn yoo fẹṣẹ yọ ara wọn leyin naa ni, ko si eyi to buru nibẹ o jare. Ṣugbọn nigba ti iṣẹju mẹwaa pe ti awọn eeyan naa si pada de, inu onikaluku ti rọlẹ, o jọ pe wọn ti fi ọgbọn agba si i.

Bi ọrọ naa ṣe ri ni pe nigba ti wọn fi pada de yii, adele alaga ko pe Rosiji lati waa sọrọ mọ, Raymond Njoku ti i ṣe minisita naa lo pe, o ni ko waa ṣalaye ọrọ ti wọn bi i, ko si sọ ohun to n ṣẹlẹ gan-an fawọn. Nigba naa ni ọkan ninu awọn aṣofin lati Plateau, Solomon Lar, sọ pe ki alaga ma ṣe bẹẹ. O ni Ayọ Rosiji lo n sọrọ lọ lọwọ ti awọn fi tuka, ohun ti ofin si sọ ni pe aṣofin kọọkan ni ẹtọ to ọgbọn iṣẹju lati fi sọrọ, o si da oun loju pe Aṣofin Rosiji ko ti i lo to ọgbọn iṣẹju ti awọn fi tuka lẹẹkan. Alaga naa rẹrin-in, o ni ki Solomon Lar ma tun da ọrọ pada sẹyin, nitori o da oun loju pe Solomon Lar ko le sọ iye iṣẹju ti Rosiji fi sọrọ nigba to n sọrọ, bi ko ba si ti le sọ iye iṣẹju to lo, ko le mọ boya o ti lo ọgbọn iṣẹju rẹ pe tabi ko ti i lo o pe. Ju gbogbo rẹ lọ, oun ti ba Rosiji sọrọ, Rosiji si ti sọ pe oun ko lọrọ ti oun fẹẹ sọ mọ, oun si dupẹ lọwọ rẹ pe o ṣe bẹẹ, “Họnọrebu Rosiji, ẹ ṣeun!”

Ẹrin ni Rosiji n rin, eyi lo si fi han pe ọkunrin olori awọn aṣofin naa ko ba a sọrọ, o kan lo ọgbọn agba fun gbogbo wọn ni. Ṣugbọn ko ma di pe wọn n jẹ ekuru ko tan, ẹni kan tun n gbọn ọwọ rẹ si awo ni Rosiji ko ṣe ba a jiyan, o fi ọrọ naa silẹ fun un. Nigba naa ni Raymond Njoku gba ori aga yii, o si dupẹ lọwọ gbogbo wọn. Oun naa ni gbogbo ọrọ ti Rosiji sọ pata niwaju awọn ọmọ ile-igbimọ yii, gbogbo rẹ lo ti kọkọ pe oun to sọ foun. O ni koda, o sọ ju bẹẹ lọ o, awọn ọrọ kan wa to jẹ to ba sọ sita, yoo da nnkan ru gan-an ni, ṣugbọn oun dupẹ pe Rosiji lo ọgbọn agba, ko sọ iru ọrọ adijasilẹ bẹẹ jade. O ni akọkọ ohun ti oun fẹẹ sọ ni pe lati asiko naa lọ, oun ti ṣofin, ofin naa si ti mulẹ pe wọn ko ni i fiya kan jẹ ẹnikẹni nileeṣẹ naa mọ, wọn ko ni i da ẹnikẹni duro, bẹẹ ni wọn ko si ni i gbe ipo ẹni kan fun ẹni kan.

Njoku ni gbogbo awọn ti wọn mọ oun mọ pe ọmọ Naijiria tootọ loun, oun ko si ni i duro nibi ẹlẹyamẹya laelae. O ni oun ti sọ fun wọn ki wọn kọwe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ nileeṣẹ reluwee naa foun, wọn si ti kọwe naa, oun ti gba a sọwọ. Nibi to sọrọ de niyẹn ti awọn aṣofin ti tun pariwo, “Ki lo wa ninu iwe ti wọn kọ fun ẹ, ṣalaye ẹ, sọ ọ jade ka gbọ, sọ ọ sita bayii bayii!” Njoku fẹsọ da wọn lohun, o ni oun yoo sọ ọ fun wọn, ki wọn ṣa ṣe suuru foun di ọjọ mi-in, nitori ọrọ naa ju ohun ti wọn yoo maa sọ nibẹ yẹn lọ. O ni ohun ti oun ṣa fẹẹ fi da wọn loju ni pe gbogbo ohun ti wọn sọ pe o n ṣẹlẹ nileeṣẹ yẹn, iru ẹ ko tun ṣẹlẹ mọ, bo ba ṣẹlẹ, ọmọ ale ni ki wọn pe oun. Eleyii dun mọ awọn aṣofin ninu, ni gbogbo wọn ba pariwo, wọn si patẹwọ fun Njoku, wọn ni o ṣe iyẹn daadaa.

Ṣugbọn ọrọ naa pari nile-igbimọ ni, ko pari laarin awọn oloṣelu, o si jọ pe wọn ti kilọ fun Ikejiani ko tọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ, pe awọn ko fẹ ariwo tabi ija kankan mọ. Koda, nibi ti ọrọ naa le de, awọn ileeṣẹ aarẹ, iyẹn ọfiisi Oloye Nnamdi Azikiwe, kọwe si Ikejiani lati kilọ fun un daadaa, wọn ni ko mọ ohun ti yoo sọ ati awọn ọrọ ti yoo maa ti ẹnu rẹ jade. Ki i ṣe ọrọ to sọ sawọn to ku ni wọn tori rẹ n ba a wi o, wọn ni nibi to ti n rojọ, o ṣalaye debi kan to ti sọ pe ṣebi aarẹ orilẹ-ede yii, ṣebi Ibo bii toun ni. Ileeṣẹ aarẹ ni laye rẹ, ko ma sọ iru ọrọ bẹẹ mọ, ko ma fi aarẹ Naijiria we ara rẹ nibi yoowu to ba ti n sọrọ, nitori aarẹ Naijiria ki i ṣe fun ti Ibo, ti gbogbo ọmọ Naijiria ni. Loootọ ni ileeṣẹ reluwee ni ki i ṣe ohun ti ọkunrin naa sọ niyẹn, pe itumọ ti oun fun ọrọ naa yatọ si eyi ti ileeṣẹ aarẹ sọ yii, sibẹ, ọrọ naa jo wọn lara.

Eyi jẹ ki Ikejiani ṣe mẹdọ, ko sinmi diẹ, ko si pariwo mọ. Awọn eeyan ro pe ọrọ naa ti tan ni, aṣe awọn kan wa ti ko tan ninu wọn rara. Awọn ọmọ Ibo to wa ninu ileeṣẹ reluwee, ati ẹgbẹ awọn ọmọ Ibo nibi gbogbo lapapọ, awọn ṣẹṣẹ gbe omi ija kana ni, wọn ni awọn yoo foju ẹni to da gbogbo eleyii silẹ han eemọ, wọn mura lati fi oju TOS Benson ri mabo. Ọrọ naa ti n lọ ni abẹlẹ ti ẹnikan ko mọ, ija naa ti n ***ho wẹrẹwẹrẹ, ẹẹkan naa lo si bu jade gbau, nigba ti TOS Benson funra rẹ pariwo sita. Bi oun ti pariwo lawọn Ibo gba a, ọrọ si di ohun ti awọn agbaagba naa tun n da si. Awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ tilẹ binu, wọn ni nibi ti ọrọ de duro yii, ki TOS Benson fi ẹgbẹ wọn silẹ fun wọn, ko maa bọ ninu Ẹgbẹ Ọlọwọ, Nigerian National Dẹmọcratic Party, Ẹgbẹ Dẹmọ. Ko si sohun to fa eyi ju ogun ti ẹgbẹ awọn ọmọ Ibo gbe ti i lọ.

Ẹ maa ka a lọ ninu Alaroye lọsẹ to n bọ.

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.