L’Oṣogbo, ọwọ tẹ awọn ọmọ orileede Togo ti wọn gba ọna eru wọ Naijiria

Spread the love

Ọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri si iwọle-wọde awọn ajeji, ẹka tipinlẹ Ọṣun (Nigerian Immigration Service, Osun state Command), ti tẹ awọn ọmọ ilẹ Togo meji, Ametchonwoun Alexandre Adodo ati Awoudya Yao Francis, lasiko ti wọn n gbiyanju lati gba iwe irinna gẹgẹ bii ọmọ orileede Naijiria.

 

Awọn ọmọkunrin yii ni wọn gba mu ninu ọgba ileeṣẹ naa to wa niluu Oṣogbo, nigba ti wọn fẹẹ ya fọto fun paali irinna ọhun.

 

Gẹgẹ bi iwadii ṣe fi han, ṣe lawọn afurasi mejeeji wọ orileede Naijiria lai ni iwe-irinna kankan, ti wọn si tun fẹẹ dọgbọn gba iwe-irinna orileede yii lati le raaye wa iṣẹ lọ sorileede Kenya.

 

A gbọ pe awọn afurasi naa ti yi orukọ wọn pada; Ametchonwoun pe ara rẹ ni Adebayọ Alexandre, nigba ti Awoudya sọ ara rẹ di Adebayọ Francis, kawọn eeyan ma baa fura si wọn.

 

Lẹyin ti aṣiri tu lawọn mejeeji jẹwọ pe loootọ lawọn wọ orileede Naijiria lati orileede Togo lai ni iwe-irinna kankan, ati pe ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Saheed Ajibọla ti gba ẹgbẹrun lọna marunlelọgọta Naira (#65,000), lati ba awọn gbe iwe-irinna orileede Naijiria jade.

 

Awọn afurasi naa sọ siwaju pe ẹnikan lo mu awọn de ọdọ Saheed, o si ṣeleri pe oun yoo gba iwe-irinna orileede yii jade fawọn mejeeji lọna irọrun, ki awọn baa le lanfaani lati wa iṣẹ lọ si orileede Kẹnya ko too di pe awọn ko owo le e lọwọ.

 

Nigba to n sọrọ ni tiẹ, Saheed Ajibọla ni oun ko mọ rara pe awọn afurasi naa ki i ṣe ọmọ orileede Naijiria, o ni oun kan ran wọn lọwọ lati gba iwe idanimọ ijọba ibilẹ kan ni Badagry ni.

 

Ọga agba ileeṣẹ naa, Ọgbẹni Adebọwale Idowu, ṣalaye fun awọn oniroyin pe ṣe ni awọn afurasi naa lo ayederu iwe idanimọ ijọba ibilẹ kan lati Badagry, nipinlẹ Eko, eleyii ti Saheed gba fun wọn.

 

O ni ni kete tiwadii ba pari lori ọrọ wọn ni awọn mẹtẹẹta yoo foju bale-ẹjọ.

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.