L’Oṣogbo, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn fẹsun ipaniyan kan foju bale-ẹjọ

Spread the love

Florence Babaṣọla

Awọn marun-un ti igbagbọ wa pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun torukọ wọn n jẹ Ẹiyẹ Confraternity, Nasirudeen Jamiu, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, Ganiyu Saheed, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Adebisi Idris, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Adeoye Sodiq ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Kasali Afeez toun naa jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelogun ti wọn fẹsun kan pe wọn pa Monsuru Lawal ni wọn ti foju bale-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo bayii.

Ẹsun mẹta ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu gbigbimọ-pọ huwa buburu, ipaniyan ati jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn fi kan awọn olujẹjọ yii.

Agbefọba, Inspekitọ Eliṣa Oluwaṣegun, ṣalaye pe awọn olujẹjọ ọhun pẹlu awọn mi-in ti ọwọ ko ti i tẹ ni wọn huwa ọhun lagbegbe Isalẹ-Ọṣun, lọjọ kẹsan-an, oṣu keje, ọdun yii.

Oluwaṣẹgun sọ siwaju pe gbogbo ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ ni alakalẹ ijiya wọn wa labala ikẹrinlelọgọta (64) ati okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin (516) ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Nigba to n ka idajọ rẹ, Onidaajọ A.O. Ajanaku paṣẹ pe ki agbefọba fi ẹda iwe ẹsun naa ranṣẹ si ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Ọṣun fun imọran to tọ lori ẹ.

O waa paṣẹ pe ki wọn ko awọn olujẹjọ naa satimọle ilu Ileṣa titi di ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ti ile-ẹjọ yoo tun mẹnuba ọrọ wọn.

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.