Lọjọ ti mo ba di gomina ni mo maa gba LAUTECH pada fun ipinlẹ Ọyọ- Akala

Spread the love

Odu ni Ọtunba Adebayọ Alao-Akala nipinlẹ Ọyọ. Yatọ si pe o ti ṣe igbakeji gomina, too tun dibo wọle gẹgẹ bii gomina, oun ni oloṣelu to ni iriri ju ninu awọn to n dupo gomina ipinlẹ naa ninu idibo oṣu to n bọ. Akala ti figba kan darapọ mọ Ajimọbi ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Party (APC). Ki lo tun fa ija laarin wọn to fi di ohun ti wọn tun kọyin sira wọn bayii? Bawo l’Ajimọbi ṣe fẹẹ kọyin Akala atọmọ ẹ sira wọn, kin ni iyẹn naa naa si n gbero lati ṣe pada fun Ajimọbi? Iwọnyi atawọn nnkan mi-in ni Akala sọ pẹlu akọroyin wa, ̣ỌLAWALE AJAO.

 

ALAROYE: Kẹ ẹ too darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, a gbọ pe Gomina Ajimọbi waa ba yin niluu oyinbo lati ba yin sọrọ; adehun wo lo wa laarin yin lọjọ naa tẹ ẹ fi darapọ mọ ẹgbẹ wọn?

 

Akala: Ko si nnkan ta a jọ ṣe ladehun funra wa, mi o si beere nnkan kan lọwọ ẹ. A jọ gba pe a jọ maa ba ara wa ṣe naa ni. Mo kan ro pe o yẹ ka jọ maa ṣẹgbẹ ni. Asiko ti mo ti ri i pe a ko le jọ ṣaṣepọ mọ ni igba ta a fẹ dibo abẹle ẹgbẹ APC. Nigba ti asiko idibo abẹlẹ si sun mọ ti mo ti ri i pe ọkunrin yii fẹ ba temi jẹ ninu oṣelu ni mo ṣe ba ẹsẹ mi sọrọ.

 

ALAROYE: Nigba tẹ ẹ ti wa di ọmọ ẹgbẹ APC tẹ ẹ si n gbero lati dupo gomina, njẹ Ajimọbi figba kankan fi yin lọkan balẹ pe ẹyin lawọn maa ṣatilẹyin fun lati ri tikẹẹti ọhun gba

Akala: Emi o beere pe ki wọn fun mi ni nnkan kan. Ohun ti mo kan sọ ni pe ẹyin ni gomina, ẹyin lẹ mọ bẹ ẹ ṣe le ṣe e lati jẹ ki ẹni to kunju oṣunwọn gba ipo lẹyin yin,  nigba ti asiko ba to, ẹyin naa lẹ maa mọ ba a ṣe maa to o. Ti eeyan ba fẹẹ to nnkan, latilẹ lo ti maa to o. ṣugbọn wọn ko to o latilẹ. Wọn ko faaye silẹ fun gbogbo awa oludije lati jọ fibo yanju ẹ. Ile teeyan ko ba si ti jọ mọ, yoo ṣoro lati jọ kan iru ile bẹẹ. Nigba ti mo ti ri i pe wọn o fun mi lanfaani lati kan ile yẹn ni mo ṣe tete tun ero mi pa.

 

ALAROYE: A gbọ pe gomina fi ipo sẹnetọ lọ yin nigba kan, ki lo de ti ẹ ko faramọ iyẹn?

Akala: Ti wọn ba fẹẹ fun mi ni sẹnetọ, o yẹ ki wọn fun mi lanfaani lati lẹnu lori awọn to maa dipo oṣelu mu lẹkun idibo mi. Emi kọ ni mo fa ẹni to jẹ alaga ijọba ibilẹ Ṣaki silẹ, mi o mọ nipa bi alaga kansu Igboho atawọn bii Okeho, Iwereele, Isẹyin, Tede ati Igbẹti ṣe debẹ. Kin ni mo waa wa fun? Mo kan wa gbanduku ni. Ko si ẹni ti mo fẹẹ ke si ninu oṣelu pe ibi ta a fẹ lọ yii, ṣe ka lọ abi ka ma lọ. Mo waa wo o pe ti mo ba duro sinu ẹgbẹ yii, awọn eleyii aa kan sọ mi di ẹdun arinlẹ ni.

 

ALAROYE: Awọn kan ni ikunsinu kan lo ti wa laarin ẹyin pẹlu gomina, nitori ẹ ni ko jẹ ki o ṣatilẹyin fun yin?

Akala: Ija ko si nibẹ. Ninu oṣelu, eeyan gbọdọ duro deede, bi bẹẹ kọ, wọn oo taari eeyan ṣubu, oluwa ẹ yoo si parẹ. Nigba to jẹ pe oṣelu da lori kin ni mo fẹẹ ṣe, kin lo fẹẹ ṣe.  Ohun to ṣẹlẹ ni pe nigba ta a jọ wa yẹn, mo ro pe a le jọ ṣe papọ ni, ṣugbọn nigba to ya, mo ri i pe ọrọ wa ko bara wọn mu. Ti ọrọ ko ba ti bara wọn mu, o san ki eeyan fi ẹgbẹ yẹn silẹ nigba ti ki i (Ajimọbi), ṣe ọga mi, ti emi naa ki i si i ṣe ọga rẹ.

 

ALAROYE:sọ nigba naa kan pe Oloye Joseph Tegbeh lAjimọbi fẹ fun ni tikẹẹti, awọn apẹẹrẹ wo lẹ ri tẹ ẹ fi sọ bẹẹ, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe Tegbeh ọhun naa ni wọn pada fun.

 

Akala: Ootọ ni mo sọ bẹẹ. Ohun to si jẹ ki n sọ bẹẹ ni pe o ti fi han pe ohun ti wọn fẹ ṣe niyẹn nigba ti Ajimọbi ti n ba awọn eeyan sọrọ labẹnu pe ki wọn faaye silẹ fun Tegbeh lati dupo yẹn. Mo gbọdọ ba ẹsẹ ara mi sọrọ pẹlu awọn ololufẹ mi nitori ti wọn o ba to o daadaa lati oke, ti mi o si tete kuro nibẹ, wọn maa yan awọn ọmọ mi jẹ nitori emi naa lawọn eeyan temi naa nidii oṣelu ti wọn lawọn ipo kan ti awọn naa fẹẹ di mu.

 

ALAROYE: Laipẹ yii lẹ fẹsun kan ẹgbẹ APC pe wọn ti lẹdi apo pọ pẹlu ajọ INEC lati ṣe ojooro ninu idibo oṣu to n bọ. Ki lẹ ri?

Akala: A ti n gbọ finrinfinrin ọna ti wọn fẹẹ gba ṣe magomago, awa naa si ti duro de wọn. To ba jẹ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe atunto ti awọn eeyan ni ki wọn ṣe nipa eto idibo, iba daa. Ka maa wo o bọ boya wọn aa gba ki awọn ti ẹrọ idibo ko gba ọmọ ika ọwọ wọn laaye lati dibo. Mo ti ni iriri to pọ nipa INEC. Mo mọ nnkan ti wọn le ṣe, mo mọ nnkan ti wọn o le ṣe. A o ba ara wa nibẹ nigba ti asiko ibo ba to.

 

ALAROYE: Ẹ ti ṣe gomina tẹlẹ, kin lo de tẹ ẹ tun fẹ dupo yẹn?

Akala: Lakọọkọ na, ẹtọ mi gẹgẹ bii ọmọ Naijiria rere ni lati ṣe ọdun mẹjọ nipo, mo si ti ṣe ọdun mẹrin ṣaaju. Mo si ṣe takọkọ daadaa. Lọna keji, awọn araalu sọ pe latigba ti mo ti kuro nibẹ, ilu ko daa mọ, ti mo ba le gbiyanju lati tun waa ṣe e lẹẹkan si i, inu awọn maa dun o. Mo si sọ fun wọn pe ma a ronu si i. Nigba to si ya, mo fun wọn lesi pe mo ti ṣetan. Mo si ti ṣeleri pe eyi to ku ninu igbesi aye mi, ki n fi ran awọn eeyan lọwọ ni.

 

ALAROYE: Awọn kan ni latigba tẹ ẹ ti de inu ẹgbẹ ADP lẹgbẹ ọhun ko ti toro mọ, ṣe ẹ n ba awọn kan ninu wọn ja ni?

 

Akala: Awọn to sọrọ yẹn kan sọ ọ boya nitori pe wọn fẹẹ fi ẹhonu kan han ni. Ko si wahala kankan to wa ninu ẹgbẹ yẹn ti ko si ninu ẹgbẹ mi-in. Ọrọ ẹgbẹ kọ lo ṣe pataki ju, eeyan lo wa ninu ẹgbẹ ti ẹgbẹ fi n jẹ ẹgbẹ, eeyan naa lo si kuro ninu ẹgbẹ ti ijakulẹ fi n ba ẹgbẹ. Awọn araalu lo maa dibo, INEC lo si maa ka ibo. Ju gbogbo ẹ lọ, ko si awuyewuye kankan mọ ninu ẹgbẹ bayii.

 

 

ALAROYE: Gẹgẹ bii ẹni to ti wa nipo ọhun tẹlẹ, awọn aiṣedeede wo lẹ kiyesi ninu iṣejọba gomina to wa lode bayii tẹ ẹ gbero lati ṣatunṣe si bẹ ẹ ba depo yẹn pada?

 

Akala: Ohun ti mo ri to n jẹ araalu niya pọ. O ṣe mi laaanu pe mo lanfaani lati gba ijọba to wa nipo bayii nimọran, ṣugbọn ko gba gbogbo imọran mi wọle. Ko si si ohun ti mo le ṣe si i nigba ti mi o si ninu ijọba. Emi naa ti ṣejọba ri, o si ni bi eto ọrọ aje ilu ṣe ri nigba yẹn. Ta a ba ni ka gbe e sẹgbẹẹ ara wọn, idi ti awọn eeyan ṣe maa n pe mi ni ‘O yatọ’ ‘O yatọ’ ki i ṣe ọrọ ẹnu lasan, nitori pe ijọba mi tu araalu lara ni. Awọn kan dori ijọba, wọn n lulu bamubamu la yo, awọn o mọ pe ebi n pa iyalayaa ẹlomin-in.

 

Ọmọ yin, Ọnarebu Ọlamijuwọnlọ Akala ti di alaga ijọba ibilẹ Ogbomoṣọ lorukọ ẹgbẹ APC, njẹ ẹ ko ro pe awọn adari ẹgbẹ APC dọgbọn fi ipo yẹn tan an lati le pin ibo Ogbomọṣọ ati agbegbe ẹ mọ yin lọwọ. Ṣe igbesẹ yii ko ni i pa yin lara?

 

****Akala: Ko le si ipalara kankan. Jẹ ki n fun ẹ lapẹẹrẹ kan, lọwọlọwọ bayii, gomina ipinlẹ Ogun n dupo sẹnetọ lorukọ ẹgbẹ APC, o si fa ẹnikan kalẹ lati dupo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu mi-in. Ọmọ mi mọ ohun to n ṣe, awọn ni wọn ko mọ ohun ti wọn n ṣe. Ṣe ọmọ mi yoo maa wa pẹlu wọn lati maa tako emi baba ẹ ni. Ibi to ba ri ko wa, ko le tako mi laelae. ̣Ṣe wọn gbadura ki ọmọ tiwọn naa tako wọn. Ori wọn ni o pe. Ọmọ mi ko ni i fẹẹ ba ọjọ iwaju ara rẹ jẹ. Ọlamijulọ ti ẹ n wo yẹn, ibi to ṣi n lọ ju gbogbo ipo wọnyi lọ. Ọjọ iwaju ẹ ṣe pataki si i. Orukọ rere baba rẹ ti wa nibẹ fun un lati lo nigbakuugba. Ohun to ba wu u lo le ṣe. Nigba to ba to asiko, ibi ti mo ba ni ko lọ lo maa lọ. Ipo to wa yẹn, wọn ko yan an sibẹ, wọn dibo yan an ni. Ko ye wọn lonii ni, yoo ye wọn lọla. ***

 

 

ALAROYE: Ko si bi wọn ṣe le yọ orukọ yin kuro ninu iwe itan ipinlẹ Ọyọ, ẹ ti ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ ṣaaju…

 

Akala: (O ja ọrọ gba mọ oniroyin lẹnu)  Mi o ṣe gomina nikan, nnkan pọ ti mo fi ju gbogbo awọn yooku lọ. Mo ṣe alaga ibilẹ, mo ṣe igbakeji gomina, mo ṣe gomina, mo tun ṣe igbakeji gomina, mo tun wa ṣe gomina. Ṣe o ri i pe iriri pọ.

 

ALAROYE: Lẹyin tẹ ẹ ti kuro ninu PDP, wọn bẹ yin pe kẹ ẹ waa tun ile tẹ ẹ ti kọ ṣe, ki lo de tẹ ẹ kọ lati pada sibẹ nigba to jẹ pe ọkan ninu awọn opo to gbe ẹgbẹ ọhun ro ni ipinlẹ yii ni yin?

 

Akala: Ẹ ṣeun fun ibeere yẹn. Ki i ṣe pe mi o fẹẹ pada. Ko si ikora-ẹni-nijaanu mọ ninu ẹgbẹ yẹn lo jẹ ki n kuro. Ṣo o mọ pe ninu oṣelu, eeyan maa n ni olori, olori si maa n ni awọn eeyan to dide lati ara rẹ. Awọn kan wà ti eeyan maa wo pe eleyii, àti-ránmún-un-gangan rẹ ko ṣẹyin eekanna mi. To ba waa di pe iru awọn yẹn fẹẹ maa fọwọ lalẹ le oluwa ẹ lori, afi ki onitọhun tete wa wọrọkọ fi ṣada. Laarin kan, ọga mi, Agba-oye Rashidi Ladọja atawọn kan fẹẹ pada, wọn si waa ba mi sọrọ pe ki n jẹ ka jọ pada sinu PDP. Mo ni ti wọn ba le gbe ẹgbẹ yẹn le e lọwọ, mo fara mọ ọn, nitori ọga mi lo jẹ, ti o ba mu tirẹ tan, ki emi naa maa mu temi. Ṣugbọn nigba ti wọn ko ba ti fi mi sipo to yẹ ki wọn fi mi si, kin ni mo tun wa n wa nibẹ. Ṣugbọn PDP ko ṣe awọn eto ẹgbẹ yẹn bo ṣe yẹ. Ọga mi to si duro sibẹ, wọn fi oju rẹ gbolẹ gbẹyin ni. Ti wọn ba waa le fi oju ọga mi gbolẹ, ti emi ba duro sibẹ, ṣe wọn ko ni i fi oju mi gbo igi.

 

ALAROYE: Ẹgbẹ oṣelu PDP lo ti n ṣakoso ijọba ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ fun ọdun diẹ sẹyin, ẹyin naa si wa lara awọn to fi abudara ẹgbẹ naa gbayi nitori orukọ wọn lẹ fi ṣe gomina, tẹ ẹ bag be ẹgbẹ yẹn lori oṣunwọn bayii, ipo wo lẹ ro pe PDP yoo wa ninu oṣelu ipinlẹ Ọyọ?

 

ALAROYE: Ọna wo lẹ ro pe ẹ le gba wa ojutuu si ipo foni-ku-fọla-dide to n koju ọpọ awọn ileewe giga to jẹ tijọba ipinlẹ Ọyọ, paapaa Fasiti imọ ẹrọ Ladoke Akintọla (LAUTECH) niluu Ogbomọṣọ?

Akala: Yoruba maa n powe kan, wọn aa ni kinni yii kinni mi ni, o yatọ si kinni yii, kinni wa ni. Ṣe ẹ ri gbogbo nnkan ti ọpọ eeyan ba ti n jumọ lo papọ, ko le si amojuto to daa fun nnkan naa to nnkan ti ẹni kan ṣoṣo da ni, to jẹ pe oun nikan naa lo n mojuto o. O da bii ki eeyan meji jọ maa sin aja kan. Ẹni kin-in-ni ko ni i fun aja yẹn lounjẹ, aa lo yẹ ki ẹni keji ti fun un lounjẹ, ẹni keji naa aa ni nitori oun ro pe ẹni kin-in-ni ti fun un lounjẹ ni ko jẹ ki oun paapaa fun un lounjẹ. Nipa bẹẹ, ebi a waa maa pa aja yẹn. Ohun to n da LAUTECH laamu niyẹn. Ki wọn (ipinlẹ Ọṣun) maa lọ, ki wọn jẹ ki awa naa (ipinlẹ Ọyọ), gbadun fasiti gẹgẹ bi awọn ipinlẹ yooku ṣe n gbadun fasiti wọn. Nigba ti wọn da ipinlẹ Ekiti silẹ lara Ondo, kin lo de ti Ekiti ati Ondo ko jọ maa jumọ ni fasiti to wa ni ipinlẹ Ondo lẹyin ti Ekiti naa ti da fasiti tiwọn silẹ, Ondo n da ni fasiti wọn, Ekiti naa fọwọ mu tiwọn ni gẹgẹ bi ipinlẹ Ogun naa ṣe da fasiti tara wọn ni. Ki lo wa de to jẹ pe lẹyin ti wọn fa ipinlẹ Ọṣun yọ lara ipinlẹ Ọyọ, awa Ọyọ tun ni lati maa ba Ọṣun pin fasiti to wa ninu ipinlẹ tiwa lẹyin ti awọn Ọṣun ti da tara wọn silẹ tan. O waa jẹ pe ipinlẹ Ọyọ to dagba ju nilẹ Yoruba kan dagba lasan ni, awa ko da fasiti kankan ni ni tiwa. Ilẹ Yoruba nikan ni mo ka yẹn o, bo ṣe wa kaakiri Naijiria niyẹn o. Mo si ti riran ri gbogbo ẹ. Nigba ti mo wa nipo gomina, mo ti gba LAUTECH fun ipinlẹ Ọyọ nikan tẹlẹ. Nigba ti ẹni to debẹ lẹyin mi debẹ lo tun da a pada. Ani Ọṣun gan-an to jẹ ọmọ wa ta a bi lanaa yii, awọn paapaa ti da fasiti silẹ, Ọlọrun paapaa ko fẹran iyanjẹ. Ti Ọlọrun ba jẹ ki n debẹ o, lọjo ti mo ba ti debẹ naa ni ma a ti bẹrẹ si i gba LAUTECH pada fun ipinlẹ Ọyọ.

 

 

ALAROYE: Awọn eeyan gba pe ẹ dalẹ Ladọja labẹnu ni wọn ṣe yọ ọ nipo tẹ ẹ fi ṣe adele gomina ko too di pe ileẹjọ da Ladọja pada sibẹ.

 

Akala: Ọmọde lo n ṣe ọ. Ohun ti ofin sọ ni pe ti wọn ba yọ gomina, igbakeji gomina lo kan lati dele de gomina. Nigba ti mo n sọrọ lẹẹkan, mo ni mo ṣe igbakeji gomina, mo ṣe gomina, mo tun ṣe igbakeji gomina ki n too ṣe gomina. Ṣe ẹni to ba ti ṣe gomina a tun maa pada ṣe igbakeji ni? nigba ti wọn yọ Ladọja ni mo kọkọ ṣe gomina. Nigba ti wọn si da wọn pada sipo pada, mo tun pada si ipo igbakeji mi ki n too dibo wọle fun ipo gomina lẹẹkeji lẹyin ti saa emi ati ọga mi pari. Ṣebi a jọ ni tikẹẹti ni. Ko si ọrọ pe eeyan da eeyan kankan nibẹ yẹn. Awọn ti ko ba mọ nnkan kan lo maa n sọ bẹẹ yẹn.

 

ALAROYE: Awọn kan gba pe niṣe lẹ du ipo ọdun 2015 yẹn lati ba ibo Ladọja jẹ ki Ajimọbi le wọle, ṣe loootọ ni? Akala: Mi o gbapooti lati ba ibo ẹnikankan jẹ, mo dupo lati wọle ni. Ti mo ba fẹẹ fi ipo ti mo n du ba ibo jẹ, o yẹ ki n jẹ ki ẹni ti mo ba n ṣatilẹyin fun wọle ni Ogbomọsọ, nitori mo lẹnu niluu Ogbomọṣọ. Ohun ti awọn eeyan kan n sọ yẹn, ahesọ lasan ni. Ohun ti mo kan ṣe nigba ti mo ti ri i pe o ti wọle ni pe mo pe e lori foonu, mo ki i ku oriire nitori agba oṣelu ni mi, ilọsiwaju ipinlẹ Ọyọ si jẹ mi logun.

 

ALAROYE: Kin ni ki awọn eeyan wa maa reti ninu ijọba yin tuntun bẹ ẹ ba wọle?

Akala: A o jẹ ki ọrọ aje ipinlẹ Ọyọ rugọgọ si i. A o si jẹ ki aye dẹrun fawọn eeyan. Ọbẹ ti wọn ti tọwo ri lemi Akala. Wọn ti mọ bi mo ṣe dun to. Ma a ṣe e to maa daa ju ti tẹlẹ lọ nitori mi o ni i fẹẹ ba orukọ ara mi jẹ fawọn ọmọ mi lọjọ iwaju. Bi ipinlẹ Ọyọ ṣe wa yii, nnkan ko rọgbọ fun araalu mọ, ìkorò lawọn eeyan n jẹ. Ki wọn maa reti igbaye-gbadun, nitori a maa jẹ ki eto ọrọ aje ipinlẹ Ọyọ daa si i.

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.