Lipẹde ji ọkada gbe, ko rowo gba beeli ara ẹ, lo ba dero ẹwọn

Spread the love

Fun pe o ji ọkada Bajaj gbe, ti ọlọpaa si mu un, ti wọn gbe e dele ẹjọ, ti ko si rowo gba beeli ara  ẹ, ọkunrin kan, Wọle Lipẹde, ti dero ọgba ẹwọn Ọ́bá, l’Abẹokuta, bayii.

Ọjọ Ẹti to kọja yii ni wọn gbe Lipẹde wa si kootu majisireeti to wa n’Iṣabọ, l’Abẹokuta. Ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ ni pe lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun yii, o ji ọkada Bajaj kan ti nọmba rẹ jẹ FFF874 WK, eyi ti i ṣe ti ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Yẹmi Oguntolu, lagbegbe Oke-Ilewo, Abẹokuta.

Ẹsun yii tako abala ọọdunrun ati mẹtalelọgọrin (383), ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ogun ti wọn tunṣe lọdun 2006, o si nijiya ninu pẹlu. Nigba ti wọn ka ẹsun rẹ si i leti, olujẹjọ loun ko jẹbi.

Adajọ Adeọla Adelaja faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira (100,000), pẹlu oniduro meji niye kan naa. O ni bi Lipẹde ba ri eto beeli naa ṣe lasiko, ki wọn gba beeli rẹ, ṣugbọn bi ko ba pe, ki wọn maa gbe e lọ sọgba ẹwọn Ọba taara. Nigba ti ko si ri eto naa ṣe bi adajọ ṣe wi, kia ni wọn gbe e sinu ọkọ ẹlẹwọn, o si balẹ sọgba ẹwọn gẹgẹ bii aṣẹ kootu

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.