Leyin ti won gba beeli Saheed to ji eya ara moto lo tun loo jale n’Ilorin

Spread the love

Lẹyin to lọọ ji awọn ẹya ara ọkọ ko ni ṣọọbu Tunde Ọgbẹni Adeniyi, dẹrẹba ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Saheed Abdulraheem, ti ri ẹwọn oṣu mẹjọ he.

Abdulraheem to n gbe niluu Eji, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara lo wọnu ṣọọbu kan lagbegbe Alagbado, niluu Ilọrin, nibi to ti ji awọn ẹya ara ọkọ towo gbogbo ẹ jẹ ẹgbẹrun lọna igba le ogoji Naira, (#240,000.00), gbe

ni Lanre Gada, lagbegbe Alagbado.

Adeniyi ti wọn ji nnkan rẹ lo lọọ fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti tọwọ fi tẹ ọdaran ọhun.

Ọlọpaa to ṣoju ijọba, Inspẹkitọ Isaac Yakubu ni ki ile-ẹjọ tete dajọ ọkunrin naa, niwọngba to ti loun jẹbi ẹsun yii.

Agbefọba yii ni iwa ọdaran ti di baraku fun Abdulraheem. Lọjọ karun-un, oṣu kọkanla, ọdun yii, lo lọọ jale ni ṣọọbu kan ti wọn ti n ta ẹya ara ọkọ. Bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ gba beeli rẹ nigba naa pẹlu ẹgbẹrun mẹta Naira dipo ko ṣẹwọn oṣu mẹta. O ṣalaye pe anfaani sisan ẹgbẹrun mẹta Naira naa lo mu ki ọdaran yii gba ominira lẹyin to san owo ọhun tan.

Ṣugbọn nigba to maa di ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla yii kan naa, laarin ọjọ marun-un sira wọn lo tun lọọ jale ninu ṣọọbu mi-in.

O rọ ile-ẹjọ lati ma ṣe fun un ni anfaani sisan owo itanran nitori pe o ṣi le tẹsiwaju lati maa huwa ọdaran naa lọ tabi ko tun ṣe eyi to ju bẹẹ lọ.

Adajọ J.B Salihu ni ọdaran naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, o waa paṣẹ pe ko lọọ ṣẹwọn oṣu mẹjọ lai si anfaani sisan owo itanran.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.