Lẹyin ti wọn le Tifẹọla nibi iṣẹ loun atọkọ rẹ lọọ ja ọga ẹ lole l’Oṣogbo

Spread the love

Kọmisanna ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Adeoye Fimihan ti ke si gbogbo awọn araalu lati mọ iru ọmọọdọ tabi dẹrẹba ti wọn yoo maa gba ṣiṣẹ pẹlu bi aye ṣe n gbẹgẹ si i lojoojumọ bayii.

 

O sọrọ yii lasiko to n ṣafihan obinrin kan ati ọkọ rẹ ti wọn lẹdi apo pọ mọ dẹrẹba to n wa iya agba ẹni ọdun mejilelọgọrin kan, ti wọn si ko ẹru to to miliọnu mejidinlogun naira ninu ile rẹ lẹyin ti wọn na iya naa bii kiku bii yiye.

 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agbegbe Kọla-Balogun, niluu Oṣogbo, ni iya agba naa, Victoria Biọla Balogun, n gbe pẹlu ọkọ rẹ, wọn si gba Tifẹọla Ibitẹyẹ, ẹni ọdun mejilelogoji gẹgẹ bii ọmọọdọ wọn lati maa ran niṣẹ, ko si maa dana fun wọn.

 

Loṣu diẹ sẹyin, ọrọ kan ṣe bii ọrọ laarin awọn mọlẹbi yii ati Tifẹọla, wọn si ni ki Tifẹọla maa lọ sile rẹ, ko ma wulẹ ba awọn ṣiṣẹ mọ. Igbesẹ awọn tọkọ-taya yii ko dun mọ Tifẹ ninu, o si pinnu pe afi koun gbẹsan lara wọn.

Nigba to dele, oun ati ọkọ rẹ, David Ibitẹyẹ, jọ lẹdi apo pọ, wọn lọọ ba Alagba Azeez Hammed toun jẹ dẹrẹba awọn tọkọ-taya yii pe kawọn jọ̣ digun ja awọn mọlẹbi naa lole, lẹyin ọpọlọpọ ọrọ didun, Alagba Azeez, ẹni ọdun marunlelọgọta naa gba lati ba wọn ṣiṣẹ papọ.

 

Ki iṣẹ laabi ti wọn fẹẹ ṣe naa le rọrun daada, David tun lọ siluu Ibadan lati lọọ ko awọn janduku mẹta mi-in, nigba to si di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹrin, ọdun yii, wọn fori le ile Iya Balogun lati lọọ mu ipinnu wọn ṣẹ.

A gbọ pe wọn kọkọ na iya yii daadaa ki wọn too bẹrẹ si i ko gbogbo nnkan to wu wọn ninu ile. Wọn ko awọn nnkan ẹṣọ to jẹ goolu olowo iyebiye, wọn ko awọn ohun eelo inu ile to n lo ina, wọn ko foonu oriṣiiriṣii mẹta, bẹẹ ni wọn ko ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din mẹwaa naira.

Apapọ owo nnkan ti awọn afurasi ọhun ji lọjọ naa, gẹgẹ bi kọmisanna ọlọpaa ṣe sọ fawọn oniroyin jẹ miliọnu lọna mejidinlogun naira.

 

Lẹyin iṣẹlẹ yii ni ọkọ iya agba yii lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti iwadii si bẹrẹ lori ẹ, ko si pẹ rara ti ọwọ fi tẹ gbogbo awọn ti wọn ṣiṣẹ naa, ti wọn si jẹwọ pe loootọ ni.

 

CP Fimihan ṣalaye pe iwadi ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, ati pe ni kete tawọn ọlọpaa ba ti pari iwadii wọn ni awọn afurasi ọhun yoo foju bale-ẹjọ, ko baa le jẹ ẹkọ fawọn to ba tun n gbero lati san aṣọ iru iwa bẹẹ ṣoro.

@@@@@@

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.