Lẹyin ti Tinubu ba wọn da si i Awọn aṣofin Eko sọrẹnda, wọn ni awọn ko yọ Ambọde mọ

Spread the love

Lẹyin ipade alaafia ti Aṣiwaju Bọla Tinubu ṣe pẹlu gomina ipinlẹ naa ati awọn aṣofin pẹlu awọn agbaagba ẹgbẹ APC kan niluu Eko lo kede pe wọn ko ni i yọ Gomina Ambọde nipo mọ, o si fi da gbogbo eeyan loju pe gomina naa yoo lo ọdun mẹrin rẹ pe nipo ijọba.

Bẹẹ lo ni gbogbo ẹka ijọba mẹtẹẹta nipinlẹ Eko, gomina ati awọn ọmọ igbimọ rẹ, awọn aṣofin ati ileeṣẹ eto idajọ ti pinnu lati ṣiṣẹ papọ ki alaafia le jọba nipinlẹ naa, ki itẹsiwaju si tun le wa fun un.

Tinubu ṣalaye fawọn oniroyin lẹyin ipade yii pe loootọ ni awọn wahala diẹdiẹ wa laarin ijọba ati awọn aṣofin lati nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin, iru eyi ti ko le ṣe ko ma wa ni agbọn oṣelu. O ni ohun tawọn si ṣe ni lati wadii ohun to ṣe okunfa wahala naa ati ọna abayọ si i. Aṣiwaju ni mọlẹbi kan ṣoṣo lawọn, bi mọlẹbi ba si wa, ko le ṣe ki ede aiyede ma wa.

Tinubu ni, “a ti pinnu pe ko ni i si ohun to jọ pe wọn fẹẹ yọ gomina nipo, ohun to ṣe pataki ni pe ki ẹka ijọba mejeeji yii jọ ni ajọsọ ọrọ, ki wọn fohun ṣọkan, ki wọn si bọwọ fun ara wọn ninu ojuṣe ti onikaluku n ṣe, ohun ti eto oṣelu pe fun niyẹn’’

Aṣiwaju ni bi awọn ko ba tete pana ọrọ naa, ki i ṣe ipinlẹ Eko nikan ni yoo ṣakoba fun, bẹẹ gẹlẹ ni yoo ṣe fun orileede lapapọ.

Bẹ o ba gbagbe, o ti to bii oṣu kan bayii ti ija abẹnu ti n lọ laarin awọn aṣofin ipinlẹ Eko ati Gomina Ambọde.  Eto iṣuna ọdun yii la gbọ pe o kọkọ fa wahala laarin wọn pẹlu bi wọn ṣe ni awọn aṣofin fẹsun kan Ambọde pe ko yọju sile igbimọ, iwe lo kan kọ lori eto iṣuna rẹ pe ki awọn aṣofin ṣayẹwo rẹ, ki wọn si ṣe atunṣe ti wọn ro pe o yẹ. Ṣugbọn awọn aṣofin binu pe arifin ni igbesẹ ti gomina gbe yii, afi ko yọju sawọn funra rẹ lati waa gbe eto iṣuna yii kalẹ niwaju awọn.

Lẹyin eyi ni iroyin tun gbe e pe Ambọde fẹẹ lọ sileegbimọ naa lọsẹ to lọ lọhun-un lati gbe aba iṣuna ọhun kalẹ, bẹẹ lawọn oniroyin si ti wa nibẹ lati wo bi gbogbo nnkan yoo ṣe lọ, afi lojiji ti nnkan tun yi biri, ni wọn ba tun ni gomina ko wa mọ.

Ọrọ naa lo si di wahala nla laarin ẹka ijọba mejeeji yii, o si le debii pe awọn aṣofin n gbe igbesẹ lati yọ gomina. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o na owo kan ti awọn gẹgẹ bii aṣofin ko fọwọ si, nidii eyi, awọn fẹẹ rọ ọ nipo gẹgẹ bii gomina.

Bi awuyewuye yii ṣe n lọ lọwọ ni awọn to jẹ alatilẹyin Ambọde naa jade sita pẹlu akọle loriṣiiriṣii pe wọn ko gbọdọ yọ ọ. Ile igbimọ aṣofin ni wọn gba lọ lati lọọ fẹhonu han pe ti wọn ba yọ gomina, wahala nla ni yoo da silẹ.

Ṣugbọn awọn kan to sun mọ Ambọde ti n gbe e kiri tipẹ pe ki i ṣe pe gomina naa na owo kankan lai gbaṣẹ gẹgẹ bi awọn aṣofin wọnyi ṣe n sọ, wọn ni owo lo dija silẹ laarin wọn. Ẹni naa sọ pe o pẹ ti awọn aṣofin ti n da gomina yii laaamu pe ki o gbe awọn owo kan jade ti awọn maa fi polongo ibo lati pada sileegbimọ naa, eyi ti Ambọde ni ko le ṣee ṣe.

ALAROYE gbọ pe gbogbo ọna ti awọn aṣofin yii mọ ni wọn lo lati ri i pe owo naa bọ si wọn lọwọ, ṣugbọn wọn ni ohun ti Ambọde sọ fun wọn ni pe o san ki wọn kuku yọ oun nipo ju ki oun ko biliọnu rẹpẹtẹ to jẹ ti awọn eeyan ipinlẹ Eko fun awọn aṣofin yii.

Koda, bi ki i baa ṣe pe Aṣiwaju Tinubu da si ọrọ naa ni, ọsẹ yii ni ireti wa pe awọn aṣofin naa iba mu ileri wọn lati yọ Ambọde nipo ṣẹ. Ṣugbọn pẹlu idasi yii, Tinubu ni ko si ohun to jọ bẹẹ mọ, pe ọkunrin naa maa lo saa rẹ pe lai si iyọnu. Ṣugbọn ohun ti ẹnikẹni ko le sọ ni boya Ambọde pada fun awọn aṣofin naa lowo ni alaafia fi waye.

Ṣugbọn eyi to wu ko jẹ nibẹ, Gomina Ambọde le sun ko fọwọ rọri bayii, ko si tun diju rẹ mejeeji pẹlu ohun ti ọga wọn ti sọ pe yoo lo ọdun mẹrin rẹ pe.

 

 

(23)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.