Lẹyin ti saa ijọba rẹ pari, Fayoṣe yọju si EFCC l’Abuja gẹgẹ bo ṣe ṣeleri

Spread the love

Bi a ti n kọ iroyin yii, ilu Abuja ni gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Ayọdele Fayoṣe wa, o si ṣee ṣe ko ti yọju si ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ wa, (EFCC), ti wọn kọwe ranṣẹ si i pe awọn fẹẹ ri lori awọn owo ipinlẹ naa kan to ṣe mọku mọku lonii, ọjọ Iṣẹgun.
Ko too kuro ni Ado Ekiti ni Sannde, ọjọ Aiku, ọsẹ yii, lo ti kọkọ dagbere fun gbogbo awọn ara ipinlẹ Ekiti, to si dupẹ lọwọ wọn fun atilẹyin ti wọn ṣe fun un nigba to wa lori ipo gẹgẹ bii gomina ipinlẹ ọhun.
Ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja ni gomina tẹlẹ yii ti kọkọ lọ kaakiri ilu Ado, nibi to ti gbe akọle kan to kọ pe, “Ẹ ṣeun o, ẹyin ara ipinlẹ Ekiti, o dabọ o” lọwọ. Bẹẹ ni awọn iyalọja, awọn ọlọkada atawọn araalu gbogbo naa n ki i. Ọpọlọpọ awọn oju popo to wa niluu yii ni gomina gbe motọ rẹ gba, to si n juwọ si awọn eeyan, to n ki wọn pe wọn ṣeun atilẹyin ti wọn ṣe fun oun nigba ti oun wa nile ijọba.
Ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Fayoṣe, iyawo rẹ, to fi mọ igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Oluṣọla Kọlapọ ati iyawo rẹ, awọn ti wọn jọ ṣiṣẹ atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lọ sile ijọsin yii fun isin idupẹ pataki. Gbogbo wọn ni wọn jọ kọwọọrin lọ si ileejọsin to wa nile ijọba, nibi ti wọn ti ṣe isin idagbere fun un ko too kuro nibẹ.
Nibi isin idagbere ọhun ni Fayoṣe ti dupẹ lọwọ awọn ara ipinlẹ Ekiti fun atilẹyin ti wọn fun un lasiko to fi n ṣejọba. Fayoṣe, ẹni to sunkun nibi isin idagbere naa sọ pe oun ko ni i jinna si awọn ara ipinlẹ Ekiti, o ni ki awọn eeyan naa ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun, ki wọn si nigbagbọ ninu rẹ pe ohun rere ko ni i fo ipinlẹ naa ru.
Siwaju si i, o sọ pe oun n fi ipo gomina silẹ bii ẹni ti o nitẹlọrun, to si gbe igbe aye to ni apẹẹrẹ. Ọkunrin ti wọn maa n pe ni Oshokomọlẹ yii sọ pe, “Inu mi dun, ọkan mi si balẹ, mo si dupẹ lọwọ yin, ẹ ṣeun gan-an ni. Mi o fẹ ki ẹ jaya nipa temi, mo maa pada wa, mo maa wọ ipinlẹ yii wa tilu tẹyẹ lagbara Ọlọrun. Oore-ọfẹ ti ko lẹgbẹ ni mo ri gba, mi o si ni i ṣe alaimoore ohun ti Ọlọrun ṣe fun mi”
Iyawo gomina to pari saa rẹ yii naa dupẹ lọwọ awọn ara ipinlẹ Ekiti fun atilẹyin ti wọn ṣe fun oun ati ọkọ rẹ lasiko ti wọn fi wa lori aleefa. Abilekọ Feyi Fayoṣe sọ pe, “A n pada bọ sipinlẹ Ekiti pẹlu iyi ati ẹyẹ, ati gẹgẹ bii aṣẹgun. Mi o mọ ọna ti Ọlọrun maa gba ṣe e o, ṣugbọn ohun to da mi loju tadaa ni pe a ṣi n pada bọ wa sipinlẹ Ekiti ninu ọla nla ati ẹyẹ.
Bakan naa lo rọ olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa ti wọn yọ nipo lọsẹ to kọja pe ko ṣe ọkan akin, o ni ki o gba iṣẹlẹ naa bii ipenija si ibi giga ti Ọlọrun n gbe e lọ. Bẹẹ lo rọ ọ ki o ma ṣe fa wahala tabi lọ sile-ẹjọ pẹlu bi wọn ṣe yọ ọ nipo. O ni bo tilẹ jẹ pe ọna ti ko ba ofin mu ni wọn fi yọ ọ nipo, ko gba iṣẹlẹ naa mọra, ki o si fi ipo naa silẹ nitori alaafia awọn ọmọ ipinlẹ Ekiti gbogbo.
Ninu ọrọ tiẹ, Alufaa ijọ to wa ninu ile ijọba yii, Oluṣọagutan Ṣeyi Oluṣọla, sọ lasiko iwaasu rẹ pe eeyan gbọdọ koju ipọnju tabi wahala to ba de ba a lasiko iṣoro to ba jẹ pe loootọ ni iru ẹni bẹẹ fẹẹ ga. O gboriyin fun gomina to n lọ naa fun iṣẹ takuntakun to ṣe nigba to wa lori iṣakoso ipinlẹ Ekiti, bẹẹ lo rọ ọ lati ma ṣe jẹ ki ohunkohun da ọkan rẹ laamu. O ni ni gbogbo igba ti ọkan rẹ ba poruuru tabi to ba n la iṣoro tabi wahala kan kọja, ki o kọ lati sa tọ Ọlọrun lọ, ko si sun mọ ọn ninu adura.
Niṣe ni awọn eeyan to lọwọọọwọ lati yẹ ẹ si nigba to fẹẹ wọ baaluu to n gbe e lọ si Abuja, nibi to ti ni oun fẹẹ lọọ jẹ ipe ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku ti wọn n pe ni (EFCC). Ọkunrin yii sọ pe ẹru ajọ naa ko ba oun, o ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii, ni ijọba oun pari, ọjọ yii naa loun yoo si yọju si awọn ajọ naa lati dahun irufẹ ibeere ti wọn ba fẹẹ bi oun lori iṣakoso oun atawọn nnkan mi-in ti wọn ba tun ni lọkan.
Fayoṣe ni igbesẹ yii waye ki awọn ajọ naa ma baa ro pe oun maa sa lọ lẹyin ti oun ba pari iṣakoso ijọba oun. O ni o san ki oun maa lọ si Abuja lọọ duro ti yoo fi di ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, ti oun yoo lọ sọdọ wọn ju ki wọn maa waa pariwo pe awọn ko ri oun. “Onigboya eeyan ni mi, mo ti sọ fun wọn pe ti mo ba ti pari ijọba mi ni mo n bọ waa ri wọn, ọdọ wọn naa ni mo si n gba lọ bayii.
Oni, ọjọ Iṣẹgun, ni ireti wa pe Ayọdele Fayoṣe yoo yọju si ajọ EFCC.

(40)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.