Lẹyin ti mo gba owo LAPO nitori ọkọ mi ni ko ya si mi mọ-Kabiratu

Spread the love

Kayọde Ọmọtọṣọ, Abẹokuta

Iyawo ile kan, Kabiratu Wahabi, ti pe ọkọ rẹ, Saidi Wahabi, lẹjọ si kootu kọkọ-kọkọ to wa l’Agbẹlọba, niluu Abẹokuta bayii, o ni oun ko fẹ ẹ mọ. Ohun to lo fa a ni pe iya ọkọ oun ti pinnu lati fẹ iyawo mi-in fun un. Yatọ si eyi, obinrin naa ni latigba toun ti ba a ya owo gbọmu-le-lanta, ti wọn tun n pe ni LAPO ni ko ti ya si oun mọ. Awọn ẹsun mi-in ti obinrin tun yii ka si ọkọ rẹ lẹsẹ ni pe gbogbo igba lawọn maa n ja, bẹẹ lo si maa n dunkooko mọ ẹmi oun.

Kabira ni gbogbo igba ni iya ọkọ oun maa n sọ pe oun yoo fẹ iyawo mi-in fun ọmọ oun, gbogbo igba loun pẹlu Iya Saidi si tun maa n ja. O ni lati ọdun meji sẹyin toun pẹlu ọkọ oun ti fẹra, ko si ifọkanbalẹ foun rara ninu ile naa, ọrọ yii si ti mu igbeyawo naa su oun, idi niyẹn toun fi fẹ ki kootu pin awọn niya.

Iyawo ile naa ni ki i ṣe nitori iya ọkọ oun nikan loun ṣe fẹẹ kọ ọkọ oun silẹ, o ni gbogbo igba ni Saidi maa n lu oun bii baara lori  ọrọ ti ko too nnkan, bẹẹ ni ki i bikita fun itọju ọmọ kan toun bi fun un, nitori laipẹ yii lo da ẹru oun sita tọmọ-tọmọ.

“Nibi ti ọrọ ọkọ mi yii buru de, ẹgbẹrun lọna ọgọfa Naira (N120,000.00) ni mo ya nitori rẹ ni LAPO, mo si ba a fi owo naa ra ọkada ko le maa ri nnkan fi ṣiṣẹ, ṣugbọn ọkọ mi ko fi owo to pa nibi ọkada yii tọju emi pẹlu ọmọ rẹ, bẹẹ ni ko si da owo ti mo ba a ya pada.”

Obinrin naa waa rọ kootu lati paṣẹ fun un ko gba oun laaye lati lọọ ko ẹru oun to ku nile rẹ. Obinrin naa ni O waa rọ kootu naa lati fopin si igbeyawo ọdun meji naa.

Nigba to n fesi, Saidi ni ko si ootọ ninu ọrọ ti iyawo oun sọ pe iya oun fẹẹ fẹ ẹlomi-in foun, ati pe oun ko pa iyawo oun ti ninu oyun gẹgẹ bo ṣe sọ.

Saidi ni oun ti pinnu lati da owo LAPO ti iyawo oun ba oun gba pada, nitori oun ti ta ọkada naa nigba ti iyawo oun fẹẹ bimọ lọsibitu.

Ṣa, Aarẹ kootu naa, Oloye O.O Akande, ti waa sun ẹjọ naa siwaju, o ni ki awọn mejeeji ṣi pada lọ sile na, ki wọn yọju si kootu loṣu to n bọ.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.