Lẹyin ti Micheal tẹwọn de ni wọn tun mu un fun ẹsun idigunjale

Spread the love

Ẹsun gbigbe oogun oloro lawọn ọlọpaa tun mu ọkunrin to ṣẹṣẹ tẹwọn de, Emmanuel Akinlabi, fun, wọn si ti da a pada si kootu Majisreeti to wa ni Ikẹja, niluu Eko, fun ẹsun idigunjale. Oun pẹlu awọn mẹta mi-in; Nurudeen Gbadamọsi, Emmanuel Akinlabi ati Samuel Elem, lo ja ọkunrin oniṣowo kan, Kẹhinde Adegboyega, lole loṣu kẹwaa, ọdun yii.

Agbefọba to n rojọ tako o nile-ẹjọ, Inspẹkitọ Micheal Unah, sọ pe ẹsun igbimọ-pọ huwa ọdaran ati ole jija ni wọn fi kan wọn. O ṣalaye pe ṣe ni wọn ja  oniṣowo yii lole  lasiko to n wa ọkọ rẹ kọja laduugbo Agege, ti wọn si ja ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry rẹ, ti nọmba rẹ jẹ SZ 759 AAA, ẹrọ agbeletan HP, ati ẹgba ọrun rẹ gba, eyi ti apapọ owo rẹ jẹ miliọnu kan o le diẹ Naira (N1,436.000).

Lasiko ti ọkan lara awọn ole yii fẹẹ ta ọkọ ọhun ni ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ẹ.

Unah ni lẹyin iwadii ni ọwọ awọn tẹ awọn afurasi to ku, ati pe awọn fidi rẹ mulẹ pe ole paraku ni awọn olujẹjọ naa.

Adajọ A.A Faṣhọla sun ẹjọ naa si ọla, Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

 

 

 

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.