Lẹyin ti Kenneth tẹwọn de lo tun lọọ ji owo pasitọ to gba a sile

Spread the love

Kootu majisreeti to wa l’Ọgba ni wọn wọ afurasi ọdaran kan, Kenneth Ejiofor, lọ, wọn ni ṣe lo ja wọ ile Pasitọ Samuel Orji, to si ji owo ọrẹ lọ. Kenneth ni wọn ni ile pasitọ naa lo n gbe, ṣugbọn ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ti pasitọ naa n ṣesin lọwọ lo ja wọ yara rẹ, to si ko owo ọrẹ ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun mọkanla Naira pẹlu owo ọrẹ pataki kan ti wọn ko ti i ka rara ati kaadi ATM rẹ meji.
Ninu alaye ti Pasitọ Orji ṣe fun awọn ọlọpaa, o ni oun faaye gba Kenneth lati maa gbe pẹlu oun nitori ẹgbọn rẹ kan lo mu un wa pe ki oun gbadura fun un, ṣugbọn lati igba to ti de ile ọdọ oun ni awọn nnkan ti bẹrẹ si poora. O ni koda, ọmọkunrin naa maa n ji ẹran jẹ ninu ikoko ọbẹ iyawo oun lẹyin to ba ti fi ẹran jẹun tan.
Ejiofor jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe loootọ, ko pẹ ti oun tẹwọn de, ṣugbọn oun kọ loun ko owo ọrẹ ti pasitọ n wa. Ẹsun mẹrin ni wọn fi kan an ni kootu, eyi to ni i ṣe pẹlu ole jija ati dida omi alaafia agbegbe ru. Ọmọkunrin naa loun ko jẹbi pẹlu alaye.
Adajọ W.A Salami faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira, ati oniduuro meji niye kan naa. Ọjọ kọkanlelogun, oṣu to n bọ, lo sun igbẹjọ rẹ si.

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.