Lẹyin ti iyawo jawe ikọsilẹ fun ọkọ ẹ niyẹn ṣa a ladaa yannayanna l’Ọrẹ

Spread the love

Isẹ takuntakun lawọn ọlọpaa ilu Ọrẹ n ṣe lọwọ lati ri afurasi kan ti wọn porukọ rẹ ni Ismaila Babalọla mu lori ẹsun ṣiṣa iyawo ẹ, Rukayat Ọdẹpeju, ladaa lẹyin tiyẹn jawee ikọsilẹ fun un ni kootu.

Gẹgẹ bi ohun ti akọroyin wa gbọ, ọdun keje niyi ti Rukayat ati ọkọ ẹ ti n gbe pọ gẹgẹ bii ọkọ ati aya, Ọlọrun si fọmọ meji ta wọn lọrẹ.

Laipẹ yii ni iyaale ile yii ati ọkọ ẹ lọ si kootu to n ri sọrọ awọn ọmọde, eyi to wa niluu Ọrẹ, to si n bẹbẹ ki adajọ tu igbeyawo  wọn ka. Wọn mu ọgbọjọ, oṣu karun-un, ọdun ta a wa yii, gẹgẹ bii ọjọ igbẹjọ.

Ninu alaye ti obinrin ọhun ṣe, o loun pinnu lati jawe ikọsilẹ fun Ismaila latari bo ṣe maa n fi irin na oun ni gbogbo igba, atawọn nnkan mi-in tọwọ ẹ ba ba.

Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ ti igbẹjọ naa ku ọla, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu to kọja yii,  ni afurasi ọhun atawọn ọrẹ rẹ kan waa ka oun mọ ile toun n gbe, wọn si fipa wọ oun ati ọkan ninu awọn ọmọ toun bi fun un sinu ọkọ.

O ni inu igbo kan ni wọn gbe awọn lọ, nibi ti wọn ti fiya jẹ oun daadaa, ti wọn si tun ṣa oun ladaa.

Lẹyin ti wọn tẹfẹẹ inu wọn tan ni wọn de oun mọ igi nla kan,  ti wọn si ba tiwọn lọ.

Rukayat  ni ọrẹ ọkọ oun kan to ba oun bẹ ẹ lo fi pada waa tu oun silẹ nigba to di nnkan bii aago mẹta oru ọjọ yii, o si tun gbe oun pada wale pẹlu ikilọ pe ko si ẹda alaaye kan to gbọdọ gbọ ohun to ṣẹlẹ lẹnu oun.

Lati igba tiṣẹlẹ ọhun ti waye lawọn ọlọpaa ti n wa baale ile yii atawọn ọrẹ ẹ, ṣugbọn wọn ko ti i ri wọn mu titi di ba a ṣe n sọrọ yii.

Ẹnikan to jẹ ẹgbọn Ismaila lobinrin, Rukayat Babalọla, ẹni ti wọn fẹsun kan pe oun lo ṣokunfa bi aburo rẹ ṣe sa mọ ọlọpaa lọwọ nigba ni wọn fẹẹ mu un ni wọn wọ wa sile-ẹjọ Majisreeti to wa niluu Ọrẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.

Agbefọba Muyideen Yẹkinni ni ohun to lodi sofin ipinlẹ Ondo ni bi olujẹjọ naa ṣe di ọlọpaa lọwọ lati ri awọn afurasi ti wọn fẹẹ gbẹmi Abilekọ Rukayat Ọdẹpeju mu.

 

O ni ki adajọ pasẹ fifi olujẹjọ naa pamọ sọgba ẹwọn titi ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Ọgbẹni T.J. Ajani ni ile-ẹjọ Majisreeti ko lẹtọọ labẹ ofin lati gbọ ẹsun igbiyanju lati gbẹmi eeyan ti wọn fi kan olujẹjọ, lẹyin eyi lo ni ki ****Rukayat ṣi lọ maa ṣere lọgba ẹwọn gẹgẹ bii aba ti agbefọba fi siwaju ile-ẹjọ,

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.