Lẹyin ọsẹ mẹta, kootu tun fagile ẹjọ tawọn alaga pe Fayẹmi Ijọba ko ti i le alaga kankan—Fayẹmi

Spread the love

Lẹyin ọsẹ mẹta tile-ẹjọ giga ilu Ado-Ekiti fagile ẹjọ tawọn alaga kansu Ekiti pe Gomina Kayọde Fayẹmi lori pe ko ma le wọn kuro nipo, ile-ẹjọ kan naa ti fagile gbogbo ẹjọ naa lodiidi lẹyin igbẹjọ ranpẹ. Lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja ni Onidaajọ Abiọdun Adesọdun gbe igbesẹ naa latari awọn iwe tawọn tọrọ kan kọ si kootu.

Ẹjọ naa lawọn alaga kansu ti gbogbo wọn jẹ mọ ẹgbẹ People’s Democratic Party (PDP), ti wọn tun wa labẹ ẹgbẹ Association of Local Governments of Nigeria (ALGON), gbe lọ si kootu nigba to ku ọjọ diẹ ki Fayẹmi gbajọba, iyẹn ni bii ọsẹ mẹta sẹyin.

Awọn olujẹjọ ni: Gomina Kayọde Fayẹmi, adajọ-agba Ekiti (Onidaajọ Ayọdeji Daramọla), abẹnugan ile igbimọ aṣofin (Ọnarebu Adeniran Alagbada), ati ile igbimọ aṣofin lapapọ.

Ọgbẹni Ibrahim Ọlanrewaju ati Ọgbẹni Tajudeen Akingbolu lo ṣoju Fayẹmi, Ọgbẹni Kabir Akingbolu ṣoju Daramọla, nigba ti Ọgbẹni Adeoye Aribasoye ṣoju Alagbada ati ile igbimọ aṣofin.

Ọgbẹni Ezekiel Agunbiade to jẹ lọọya awọn olupẹjọ lo kọwe si kootu naa pe awọn ko ṣe ẹjọ mọ, eyi si waye lẹyin ti ikọ awọn lọọya to duro fun awọn olujẹjọ kọwe tako ẹjọ naa.

Nnkan tawọn lọọya awọn olujẹjọ sọ ni pe kootu naa ko lẹtọọ lati gbọ ẹjọ ọhun nitori ahesọ lasan ni ẹri tawọn olupẹjọ ni, igbesẹ ti wọn si gbe ko nitumọ labẹ ofin nitori ko sẹni to ti i gbe igbesẹ kankan ti wọn ti sare wa kootu.

Idajọ ọjọ Ẹti yii tun tọka si idajọ to ti kọkọ waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ilu Ado-Ekiti, nibi ti kootu naa ti fagile ẹjọ ti ijọba Ayọdele Fayoṣe to kuro lori oye pe.

Ṣe loṣu kẹwaa, ọdun to kọja, ni kootu to n mojuto ẹjọ awọn ileeṣẹ, National Industrial Court of Nigeria (NINC), niluu Akurẹ dajọ pe Fayoṣe ko lẹtọọ lati fagile ajo eleto idibo Ekiti (SIEC), atawọn ajọ mi-in ti Fayẹmi da silẹ nigba to wa lori aleefa ni saa akọkọ, ati pe ko sanwo gbogbo awọn to le danu.

Abilekọ Cecilia Bọsẹde Adelusi to jẹ alaga (SIEC), atawọn alaga ajọ to ku lo gbe ijọba Fayoṣe lọ sile-ẹjọ nigba naa.

Idajọ yii ni ijọba Fayoṣe lọọ tako ni kootu ko-tẹ-mi-lọrun, ti ẹjọ naa si n lọ, ṣugbọn Ọgbẹni Wale Fapohunda to jẹ agbẹjọro-agba Ekiti tuntun ti lọọ gbe ẹjọ naa kuro nile-ẹjọ, eyi to jẹ ki adajọ fagile e.

Onidaajọ Kayọde Bamiṣilẹ ni Fayoṣe yan lati jẹ alaga SIEC lọdun 2015, oun lo si ṣeto idibo to gbe awọn alaga to mu ẹjọ Fayẹmi lọ si kootu yii wọle.

Nibi tọrọ de duro, ajọ ti Adelusi jẹ alaga fun nigba naa lofin mọ bayii, eyi si tumọ si pe ipo awọn alaga to wa lori aleefa lọwọlọwọ ko bofin mu, ibi tọrọ yoo si ja si fun wọn lawọn araalu n duro de.

Ẹwẹ, lopin ọsẹ to kọja ni Fayẹmi kede nipasẹ Yinka Oyebọde to jẹ olori akọwe iroyin rẹ pe ko si ootọ ninu iroyin to ti gba igboro kan pe awọn ti le awọn alaga kansu ọhun nitori ijọba awọn ko ṣe iru ẹ.

‘’Ijọba wa fẹẹ sọ fun gbogbo eeyan pe awọn kan lo n gbe ahesọ naa kiri, irọ patapata si ni. A fi asiko yii ṣeleri fun yin pe ipinnu ta a ba ṣe lori ọrọ naa yoo de etiigbọ yin, bakan naa ni gbogbo ilu yoo maa mọ awọn eto mi-in ta a ba fẹẹ ṣe.

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.