Lẹyin ọsẹ kan ti adajọ dariji Akeem lo tun lọọ jale l’Oṣogbo

Spread the love

Pẹlu ibinu ni adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo fi ju Akeem Ọdẹyale, ẹni ọdun mọkanlelogun si ẹwọn ọdun kan ataabọ, nigba to tun farahan nile-ẹjọ fun ẹsun ole-jija.

 

Ọsẹ to kọja lọ lọhun-un ni awọn ọlọpaa gbe Akeem wa sile-ẹjọ naa lori ẹsun pe o jale, ṣugbọn nitori pe awọn olupẹjọ kuna lati farahan ki wọn le jẹrii si ọrọ ọhun lo mu ki Onidajọ Taofeeq Badmus yọnda rẹ pe ko maa lọ pẹlu ikilọ pe ko tun gbọdọ ṣan aṣọ iru ẹ ṣoro mọ.

 

Bo tun ṣe di ọjọ kejila, oṣu kejila, ọdun yii, la gbọ pe Akeem fori le agbegbe Kunle Thompson, Dada Estate, niluu Oṣogbo, ni nnkan bii aago mẹta idaji, o ja windo ile Ọgbẹni Noah Kazeem, o si ji foonu Infinix ati Tecno kan.

 

Bo ṣe kuro nibẹ lo fori le yara Ọgbẹni Adegboye Ojo, nibi to ti ji foonu Samsung Prime kan, to si sa kuro nibẹ.

 

Nigba to di nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ kan naa, gẹgẹ bi agbefọba lori ẹsun ọhun, Inspẹkitọ Abiọdun Fagboyinbo ṣe sọ, ni Akeem tun lọ si ile baba kan ti wọn n pe ni Muibi Adeleke, o si ji foonu Huawei kan atawọn nnkan mi-in to jẹ ti Ọgbẹni Ali Ọlatunbọsun.

 

Fagboyinbo fi kun ọrọ rẹ pe bo ṣe jale tan nile yii laṣiri tu, ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa Dugbẹ ti wọn n lọ kaakiri lo jẹ ki ọwọ tẹ ẹ nigba to n sa lọ nidaaji ọjọ yii.

 

Nigba ti wọn ka ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi kan Akeem si i leti, o ni oun jẹbi wọn. O ni ki i ṣe pe oun jalẹkun wọnu awọn ile toun ti jale yii, ṣe loun kan nawọ lati oju windo, toun si ji gbogbo nnkan naa.

 

Paripari ẹ, Akeem ni ki ile-ẹjọ ṣiju aanu wo oun, nitori “aanu n ṣogo lori idajọ”, o ni oun ko ti i ta awọn nnkan toun ji naa, ati pe gbogbo rẹ ni awọn ọlọpaa ti gba lọwọ oun, to si ṣee ṣe ki wọn ti da wọn pada fun awọn to ni wọn.

 

Ninu idajọ rẹ, Adajọ Taofeeq Badmus ni o han gbangba pe Akeem ko ṣetan lati yipada rara, bẹẹ ni ko si ṣetan lati gbọ imọran ti oun gba a nigba to kọkọ farahan niwaju oun pe ko gbọdọ pada sinu ẹsẹ rẹ mọ.

 

Eyi lo mu ki adajọ ju Badmus si ẹwọn oṣu mejila fun ẹsun akọkọ, oṣu mẹrinla fun ẹsun keji ati oṣu mejidinlogun fun ẹsun kẹta, ṣugbọn yoo lo awọn akoko naa tẹle ara wọn.

 

Eleyii tumọ si pe ọdun kan ataabọ ni Akeem yoo lo lọgba ẹwọn lai faaye faini kankan silẹ fun un.

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.