Lẹyin Ọlayanju, awọn aṣofin Ekiti mi-in tun n gbero lati lọ si APC

Spread the love

O ti han gbangba bayii pe o ṣee ṣe kawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti mi-in darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), pẹlu iroyin to n jade lati ile naa lẹyin igbesẹ ti Ọnarebu Ọlanrewaju Ọlayanju gbe lọsẹ to kọja.

Lopin ọsẹ naa ni aṣofin to n ṣoju ẹkun Emure yii kede pe oun ti fi People’s Democratic Party (PDP), silẹ lẹyin toun atawọn eeyan oun ṣajọro lori iṣipopada ọhun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘’ Ẹgbẹ oṣelu PDP lanfaani lati ṣejọba laarin 2014 si 2018 pẹlu atilẹyin awọn eeyan, ṣugbọn ẹgbẹ naa da gbogbo wa. Iṣẹ ati iya la jẹ lasiko wọn, ṣe lawa aṣofin si lọ n gbawin lọdọ awọn to n ta ọkada.

‘’Ẹgbẹ PDP ti fọ si wẹwẹ l’Ekiti nitori aṣilo agbara awọn adari, awọn kan ninu wọn si n sọ pe kawọn eeyan dibo fun ẹgbẹ mi-in nibi ti ọmọ PDP ti n dije.

‘’Latigba ti Gomina Kayọde Fayẹmi ti de ni inu araalu ti n dun, o si n ṣe awa aṣofin daadaa. Nitori naa ni emi, Ọnarebu Ọlanrewaju Ọlayanju, ṣe fi gbogbo ọkan jẹjẹẹ fun APC, mo si rọ awọn ololufẹ mi gbogbo lati ṣe bẹẹ.’’

Bakan naa ni abẹnugan ile igbimọ aṣofin ọhun, Ọnarebu Adeniran Alagbada, sọ pe awọn mi-in yoo tun kede iṣipopada wọn laipẹ nitori PDP ko rọrun fun ẹnikẹni mọ. O ni awọn mẹrin lawọn jẹ ọmọ ẹgbẹ APC lọwọlọwọ, ṣugbọn awọn yoo di mẹwaa laarin ọjọ diẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to lọ lọhun-un nigbimọ to n tukọ ẹgbẹ naa l’Ekiti juwe ile fun Ọlayanju, Ọnarebu Pọsi Ọmọdara, Ọnarebu Badejọ Anifowoṣe, Ọnarebu Cecilia Dada, Ọnarebu Fajana Ojo Ade, Ọnarebu Ọlayọde Ọmọtọṣọ ati Ọnarebu Ṣẹgun Adewumi.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn lẹdi apo pọ pẹlu ẹgbẹ alatako, ṣugbọn awọn eeyan naa ni ere ọmọde nigbimọ naa n ṣe nitori awọn adari ẹgbẹ lapapọ nikan ni wọn niru aṣẹ bẹẹ.

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.