Lẹyin ọjọ mọkanla ti wọn gba Ben siṣẹ ọmọ-ọdọ lo ja ọga rẹ lole

Spread the love

Kọmisanna Imohimi Edgal ti waa ṣekilọ fawọn to n gba ọmọ-ọdọ lati maa ṣewadii daadaa ki wọn too gba wọn, nitori ọpọ wọn lo maa n jẹ ẹlẹmi eṣu. Ikilọ yii waye nitori bi Ben Peters ti Alagba Alexander Okoye, ẹni ọdun mẹtalelaaadọrin, ati iyawo rẹ, Njideka Okoye, gba sile ṣe ja wọn lole lẹyin ọjọ mọkanla ti wọn gba a.

Ninu atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Chike Oti, fi ṣọwọ si akọroyin wa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, lo ti ni bi ko ba jẹ pe aṣiri ọmọkunrin naa tete tu, niṣe ni ko ba ti ṣe awọn tọkọ-tiyawo naa leṣe.

O ṣalaye pe ọjọ kejila, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni awọn tọkọ-tiyawo naa gba Ben siṣẹ, ṣugbọn nigba to di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, ni awọn baba ati mama naa kọ lẹta si Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, pe  Ben, iyẹn ọmọọdọ tawọn gba ti ko ti i lo ju ọjọ mọkanla lọ lọdọ awọn ti ji dukia awọn, to fi mọ ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry Saloon, 2008 model. Bakan naa ni wọn lo tun ji ẹgbẹrun marun-un Dọla, ṣaati mẹfa ati foonu Motorola Android kan.

Iwe ẹhonu yii ni ọga ọlọpaa fi paṣẹ fun CSP Kẹmi Adedeji ati awọn ikọ to wa ni ẹka to n ja fun ẹtọ awọn ọmọniyan lati wa Ben jade nibi yoowu to ba farapamọ si.

Lẹyin oṣu meji, iyẹn lọjọ kejidinlogun, oṣu yii, wọn wọ ọmọkunrin naa jade nibi to farapamọ si lagbegbe Agege, niluu Eko, wọn si ri awọn dukia to ji gbe naa gba pada lọwọ rẹ.

Iwadii awọn agbofinro fi han pe ki i ṣe Ben Peters gan-an lorukọ ọmọkunrin yii, Usang Bassey Effiong, lorukọ ti awọn obi rẹ sọ ọ.

Ninu alaye ọna to gba ṣiṣẹ ibi naa to sọ fawọn ọlọpaa lo ti ni oun tọpasẹ ibi ti Alagba Okoye maa n tọju kọkọrọ yara rẹ pamọ si to ba n jade, kọkọrọ naa loun si lo lati fi ṣilẹkun. O ni lẹyin eyi loun ṣẹda kọkọrọ yara igbalejo wọn.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹwaa, lo ni oun pinnu lati fọ yara awọn ọga oun yii. Ben ni ki iṣẹ ibi toun fẹẹ ṣe yii fi le rọrun foun, niṣe loun yọ ẹrọ kamẹra aṣofofo (CCTV), to wa ninu yara yii, toun si ko awọn dukia wọn, ki oun too waa gbe ọkọ ayọkẹlẹ wọn lọ.

O ni eleyii rọrun foun nitori ọmọọdọ to n ba wọn ṣiṣẹ tẹlẹ ki wọn too gba oun, Matthew Johnson Abam, jẹ ọkan lara awọn ti awọn jọ maa n jale, oun lo si fun oun ni ẹkunrẹrẹ alaye nipa ọna ti oun le gba ji wọn lẹru ati ibi ti wọn n ko awọn dukia wọn si.

Kọmisanna Imohimi Edgal ti waa ṣekilọ fawọn to n gba ọmọ-ọdọ lati maa ṣewadii daadaa ki wọn too gba wọn, nitori ọpọ wọn lo maa n jẹ ẹlẹmi eṣu.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.