Lẹyin ọdun mọkanla, Bọsẹ fẹẹ kọ ọkọ rẹ silẹ l’Abẹokuta

Spread the love

Kayọde Ọmọtọṣọ, Abẹokuta

Abilekọ Bọsẹ Ọladapọ lo ti wọ ọkọ rẹ, Ọladepo Ọladapọ, lọ si kootu kọkọ-kọkọ to wa ni Agbẹlọba, niluu Abẹokuta, o ni oun fẹẹ kọ ọ silẹ latari pe o ti n halẹ pe oun yoo jogun ile ti oun kọ, bẹẹ Ọladepo ko tun san owo-ori oun. Obinrin naa ni fun odidi ọdun mọkanla ni ọkọ oun fi n foni-donii, fọla-dọla lori ọrọ sisan owo-ori oun, idi niyẹn ti oun si ṣe fẹẹ kọ ọ.

Ẹsun mẹta to ka si ọkọ rẹ lẹsẹ ni pe oun ko nifẹẹ rẹ mọ nitori ko nifẹẹ oun pẹlu awọn ọmọ oun mejeeji, idunkooko mọ ẹmi oun pẹlu awọn ọmọ oun ati ifiya-jẹni.

Bọsẹ ni ọpọ igba loun ti mu ẹjọ ọkọ oun lọ si ọdọ awọn ẹbi rẹ, ṣugbọn ko tori rẹ yiwa pada rara.

Nigba to n fesi, Ọladapọ ni irọ niyawo oun n pa mọ oun. O ni oniwahala ni obinrin naa, idi niyẹn ti awọn fi maa n ja.

Adajọ ile-ẹjọ naa, J.A.O Shofolahan, sun ẹjọ siwaju, o ni ki awọn mejeeji pada wa loṣu to n bọ.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.