Lẹyin ọdun marun-un, kootu ibilẹ yoo bẹrẹ pada l’Ọṣun

Spread the love

Nigba ti ijọba ipinlẹ Ọṣun kede pe kootu ibilẹ yoo bẹrẹ pada, pẹlu ayọ ati idunnu lawọn araalu fi gba iroyin naa, tori wọn nigbagbọ pe ireti tuntun ti wa fun ọpọlọpọ mọlẹbi ti wọn n tuka lai ni atunṣe.

 

Lati ọdun marun-un ṣeyin ni gbogbo awọn kootu naa ko ti ṣiṣẹ mọ, eleyii ko si ṣẹyin aisi owo to fun ijọba Gomina Arẹgbẹṣọla ni wahala nigba naa, to fi di pe owo-oṣu awọn oṣiṣẹ bẹrẹ si i ṣe ṣegeṣege.

 

Bi awọn baba ati iya ti wọn ṣiṣẹ gbẹyin lawọn kootu ibilẹ naa ṣe pari saa wọn ni Arẹgbẹṣọle ko ti fọwọ si yiyan awọn mi-in latigba yẹn.

 

Akoba nla si ni igbesẹ naa ti ṣe laarin ọpọlọpọ idile, gẹgẹ bi iwadii Alaroye ṣe fi ẹsẹ rẹ mulẹ. Ọpọ idile lo ti tuka latari ọrọ ti ko to nnkan, ti wọn kan niloo imọran agbalagba lati fi ṣatunṣe.

 

Lasiko ti awọn kootu ibilẹ naa maa n ṣiṣẹ, o rọrun fun awọn mọlẹbi lọkọ-laya ti wọn ba fẹẹ tu igbeyawo wọn ka lati tete bẹ awọn adajọ kootu naa pe ki wọn ma ṣe gba wọn laaye.

 

Nitori iriri ati oye-agba ti ọpọlọpọ awọn adajọ igba naa ni, ọpọ igbeyawo ni wọn mu pada bọ sipo, bẹẹ lawọn ọmọ ti wọn iba ti didakuda sigboro naa di ẹni to n gbe pẹlu iya ati baba wọn.

 

Ṣugbọn ijọba gomina Arẹgbẹṣọla ko ṣe atunto igbimọ awọn adajọ naa titi to fi gbe eeku ida le Alhaji Gboyega Oyetọla lọwọ gẹgẹ bii gomina loṣu kọkanla, ọdun to kọja.

 

Amọ ṣa, akọwe fun ajọ to n ri si eto idajọ nipinlẹ Ọṣun, Barista Micheal Obidiys ti kede pe gbogbo awọn ti wọn ti forukọ silẹ lati jẹ alaga atawọn ọmọ igbimọ idajọ lawọn kootu ibilẹ naa yoo bẹrẹ ifọrọwanilẹnuwo wọn lọsẹ yii.

 

Gẹgẹ bo ṣe wi, lonii yii gan-an, iyẹn ọjọ kẹtalelogun, osu kẹrin, lawọn igbimọ idajọ lati ẹkun Aarin-Gbungbun ati Iwọ-Oorun Ọṣun yoo ṣe ifọrọwanilẹnuwo tiwọn, nigba ti awọn ti wọn wa lẹkun Ila-Oorun Ọṣun yoo ṣe tiwọn lọla.

 

Aago mẹwa aarọ ni eto naa yoo maa bẹrẹ lojoojumọ ninu ọgba ile-ẹjọ giga ti ilu Oṣogbo.

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.