Lẹyin oṣu mẹfa, ileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan Ekiti bẹrẹ iṣẹ *Bẹẹ latunṣe ba ibudo Ero Dam lẹyin ọdun mẹtalelọgbọn

Spread the love

Oni, ọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2019, nileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan ipinlẹ Ekiti labẹ Broadcasting Service of Ekiti State (BSES), bẹrẹ iṣẹ pada lẹyin oṣu mẹfa ataabọ geerege tileeṣẹ to n ṣakoso igbohunsafẹfẹ, National Broadcasting Commission (NBC), ti i pa.

Ṣe lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keje, ọdun to kọja, ni NBC ti ileeṣẹ yii pa lori awọn ẹsun kan, eyi ti lara rẹ jẹ ikede ibo gomina ti ajọ eleto idibo ko ti i fọwọ si.

Igbesẹ lati ṣi BSES ko ṣẹyin adehun ti Gomina Kayọde Fayẹmi ni pẹlu NBC lori bi ijọba yoo ṣe maa san owo itanran ti wọn bu fun ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ naa diẹdiẹ.

Ọgbẹni Idowu Oguntuaṣe ni yoo maa ṣe alakooso titi digba ti gomina yoo ṣiṣẹ lori abọ ti igbimọ iwadii ileeṣẹ ọhun gbe fun un.

Ẹwẹ, ọsẹ to kọja ni Fayẹmi lọọ ṣefilọlẹ atunṣe si ibudo to n pese omi fun ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, iyẹn Ẹrọ Dam to wa niluu Ikun Ekiti, nijọba ibilẹ Mọba, eyi tiru rẹ waye ni bii ọdun mẹtalelọgbọn sẹyin.

Nibẹ ni Gomina Fayẹmi ti fi da awọn araalu loju pe iṣẹ akanṣe naa to jẹ pẹlu ajọṣepọ banki agbaye yoo pari loṣu kẹfa, ọdun 2020.

Iwadii fi han pe miliọnu marundinlọgọta (55,000,000), Dọla ni wọn yoo na si iṣẹ akanṣe yii, eyi si jẹ akọjọpọ atunṣẹ sawọn ọpa omi to wa kaakiri Ekiti ati rirọpo awọn ẹrọ ti yoo maa pese omi.

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.