Lẹyin ijamba ọta ibọn: Bamidele kede erongba lati di sẹnetọ l’Ekiti

Spread the love

Lẹyin bii oṣu mẹta ti ori ko o yọ lọwọ aṣita ibọn, Ọnarebu Ọpẹyemi Bamidele ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ti kede erongba rẹ lati dupo sẹnẹtọ ni ẹkun Arin-Gbungbun Ekiti.

Oloṣelu to ti ṣe kọmiṣanna nipinlẹ Eko ati aṣoju-ṣofin l’Abuja naa ni yoo koju Sẹnetọ Fatima Raji-Rasaki to ṣẹṣẹ darapọ mọ APC ninu idibo abẹle.

Bamidele lori ko yọ nigba ti ọlọpaa adigbojula kan ṣeeṣi yinbọn lu u nikun lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa, ọdun yii, lasiko ti Ọmọwe Kayọde Fayẹmi bẹrẹ ipolongo lati di gomina Ekiti. Ilẹ yii ati oke-okun ni wọn ti tọju rẹ ko too gbadun.

Nibi eto ikede naa to waye nile rẹ niluu Iyin-Ekiti lọsẹ to kọja, Bamidele ni gbogbo ọna ti APC ba fẹẹ gba lati yan oludije wọn loun faramọ, ṣugbọn inu oun yoo dun lati ri anfaani ṣiṣẹ takuntakun faraalu lẹyin nnkan toun la kọja.

‘’ Nigba ti mo ṣoju awọn eeyan Ado/Irẹpọdun/Ifẹlodun nile igbimọ aṣoju-ṣofin, mo ṣiṣẹ fun awọn to wa ni ẹkun idibo mi atawọn mi-in. Iṣẹlẹ to ṣẹlẹ si mi laipẹ yii jẹ ki n ni ero tuntun, ati pe Ọlọrun fẹẹ lo mi fawọn eeyan mi ni.’’

 

 

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.