Lẹyin ijamba ọjọ Jimọ, ọmọ-ọwọ ati agbalagba mọkanla tun ku lọjọ Aiku ni marosẹ Abẹokuta- Ṣagamu

Spread the love

Ijamba eleyii pọ ju, ọmọ-ọwọ paapaa ṣalaisi, ninu ijamba ọkọ mi-in to tun ṣẹlẹ ni Ṣiun, loju ọna marosẹ Abẹokuta si Ṣagamu, lọjọ Aiku, Sannde, ijẹrin yii, lẹyin ọjọ kan ṣoṣo teeyan mẹta padanu ẹmi wọn loju ọna yii kan naa.

Niṣe loju awọn eeyan n ṣomi gbere, ko sẹni to ri ijamba to pa ọkunrin marun-un, obinrin mẹfa ati ọmọ-ọwọ kan to wa laarin wọn ti aanu ikunlẹ abiyamọ ko ṣe.

Asidẹnti yii ni i ṣe ẹlẹkẹẹta ẹ nipinlẹ Ogun laarin ọsẹ to kọja yii. Aago kan aabọ ọsan ọjọ Aiku, ọjọ kẹta, oṣu keji yii, lo waye gẹgẹ bi Ọgbẹni Ọladele Clement to jẹ adari ẹka FRSC nipinlẹ Ogun ṣe wi.

Ọladele to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lọjọ yii kan naa ṣalaye pe ọkọ ayọkẹlẹ Cerato kan to ni nọmba KJA 806 BT lo n sare bọ ni marosẹ naa. Ojiji ni taya rẹ fọ, ti nnkan daru mọ dẹrẹba naa lọwọ.

Adari FRSC nipinlẹ Ogun fi kun un pe awọn fura pe niṣe lawakọ naa tẹ bireeki lojiji bi taya ṣe fọ, bẹẹ ko yẹ ko ṣe bẹẹ.

Ijanu to gbiyanju lati tẹ lara mọto ti taya kan ti fọ lẹsẹ ẹ lo di wahala, ti ọkọ ayọkẹlẹ naa fi ya kuro loju popo, to gun ori pepele ti wọn fi pin oju ọna naa si meji, to si ṣe bẹẹ dojukọ ọkọ bọọsi to n lọ si Ṣagamu jẹẹjẹ tiẹ.

Abẹokuta ni ọkọ bọọsi ti nọmba ẹ jẹ LSR 334 FF naa ti gbera, awọn ero wa ninu ẹ. Ṣugbọn ọkọ ayọkẹlẹ to n yi kiri titi naa rọ lu u lojiji, gbogbo ero inu ọkọ naa si ku. Bẹẹ naa si lawọn to wa ninu kaa to kọlu wọn paapaa ko ṣẹku ẹnikan, gbogbo wọn ni wọn ku loju-ẹsẹ ti ikọlu naa waye.

Nigba tawọn ẹṣọ FRSC debẹ, wọn ṣewọn ti wọn le ṣe nipa pipalẹ awọn oku naa mọ.

Ṣugbọn kinni kan ti Ọgbẹni Ọladele Clement sọ ni pe kawọn eeyan ti ẹni wọn ba tirafu lasiko yii, ti wọn ko de mọ, waa yọju sawọn ni kọmandi awọn, tabi ki wọn lọ si Ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ to wa ni Ṣagamu, mọṣuari wọn lawọn ko awọn oku agbalagba mọkanla, ati ọmọ ọwọ to ṣikejila wọn si.

Ko ṣai tun ba awọn awakọ sọrọ pe ki wọn jọwọ, dẹkun ere asapajude ni marosẹ, ki wọn yee lo taya to ti gbo sẹsẹ mọto wọn.

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.